Privacy Settings

To provide you with the best possible experience, we use cookies and similar technologies. Some cookies are necessary to make our website work and cannot be refused. You can accept or decline the use of additional cookies, which we use only to improve your experience. None of this data will ever be sold or used for marketing. To learn more, read the Global Policy on Use of Cookies and Similar Technologies. You can customize your settings at any time by going to Privacy Settings.

Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ẹ “Jẹ́ Kí Àwọn Nǹkan Tó Wà Báyìí Tẹ́ Yín Lọ́rùn”

Ẹ “Jẹ́ Kí Àwọn Nǹkan Tó Wà Báyìí Tẹ́ Yín Lọ́rùn”

Tí owó tó ń wọlé fún wa ò bá tó nǹkan, ó lè máa ṣe wá bíi pé ká lọ́wọ́ sí àwọn ohun kan. Àwọn nǹkan náà sì lè mú ká jìnnà sí Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, a lè rí iṣẹ́ tó máa mówó gọbọi wọlé àmọ́ tí kò ní jẹ́ ká ráyè fáwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. Tá a bá ronú lórí Hébérù 13:​5, ó máa jẹ́ ká lè ṣèpinnu tó tọ́.

“Ẹ yẹra fún ìfẹ́ owó nínú ìgbésí ayé yín”

  • Gbàdúrà, kó o wá ronú nípa bó o ṣe máa ń ṣe tó bá ti kan ọ̀rọ̀ owó. Lẹ́yìn náà, ronú nípa àpẹẹrẹ tó ò ń fi lélẹ̀ fáwọn ọmọ rẹ.—g 11/15 6.

“Bí ẹ ṣe ń jẹ́ kí àwọn nǹkan tó wà báyìí tẹ́ yín lọ́rùn”

  • Fara balẹ̀ ronú lórí ohun tó o nílò gan-an.—w16.07 7 ¶1-2.

“Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé, mi ò sì ní pa ọ́ tì láé”

  • Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa pèsè àwọn ohun kòṣeémánìí fún ẹ tó o bá ń fi ire Ìjọba rẹ̀ sípò àkọ́kọ́.—w14 4/15 21 ¶17.

Àwòrán: Àwọn apá kan nínú fídíò náà “Ọkàn Àwọn Ará Wa Balẹ̀ Bí Wọ́n Tiẹ̀ Ń Dojú Kọ Ìṣòro Àìlówó Lọ́wọ́.” 1. Miguel ń po ìyẹ̀fun nítòsí àdògán ńlá kan. 2. Ó ń lọ aṣọ. 3. Ó wo ara ẹ̀ nínú dígí, ó sì rẹ́rìn-ín bó ṣe ń múra láti lọ síbiṣẹ́.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ, ỌKÀN ÀWỌN ARÁ WA BALẸ̀ BÍ WỌ́N TIẸ̀ Ń DOJÚ KỌ ÌṢÒRO ÀÌLÓWÓ LỌ́WỌ́, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

Kí lo rí kọ́ nínú ìrírí Miguel Novoa?