Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Fọkàn Balẹ̀ Bí Ètò Àwọn Nǹkan Yìí Ṣe Ń Lọ Sópin

Fọkàn Balẹ̀ Bí Ètò Àwọn Nǹkan Yìí Ṣe Ń Lọ Sópin

Láìpẹ́, sùúrù tí Jèhófà ní fún ayé yìí máa dópin. Lára àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ni pé ìsìn èké máa pa run, àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè sì máa gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà, Jèhófà máa pa àwọn èèyàn burúkú run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. Kò sí àní-àní pé àwa Kristẹni ń fojú sọ́nà fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí.

Àmọ́, a ò mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà ìpọ́njú ńlá. Bí àpẹẹrẹ, a ò mọ ìgbà tó máa bẹ̀rẹ̀ ní pàtó. A ò mọ ohun tó máa mú káwọn ìjọba ayé gbéja ko ìsìn. Bákan náà, a ò mọ bí àtakò tí àwọn orílẹ̀-èdè máa ṣe sáwa èèyàn Ọlọ́run ṣe máa pẹ́ tó, a ò sì mọ ọ̀nà tí wọ́n á gbà gbéjà kò wá. Yàtọ̀ síyẹn, a ò mọ ohun pàtó tí Jèhófà máa lò láti pa àwọn èèyàn burúkú nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì.

Síbẹ̀, a ò nídìí láti bẹ̀rù torí pé Bíbélì ti jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan táá fi wá lọ́kàn balẹ̀ bí òpin ṣe ń sún mọ́lé. Bí àpẹẹrẹ, a mọ pé a ti wà ní apá ìparí “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2Ti 3:1) A tún mọ̀ pé Ọlọ́run ò ní jẹ́ kí ìsìn tòótọ́ pa run nígbà tí àwọn ìjọba ayé bá gbéjà ko ìsìn torí pé ó máa “dín àwọn ọjọ́ yẹn kù.” (Mt 24:22) Yàtọ̀ síyẹn, a mọ̀ pé Jèhófà máa gba àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀. (2Pe 2:9) Bákan náà, a mọ̀ pé olóòótọ́ àti alágbára ni Ẹni tí Jèhófà yàn láti pa àwọn èèyàn burúkú run, kó sì dáàbò bo ogunlọ́gọ̀ èèyàn nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì.​—Ifi 19:11, 15, 16.

Ó dájú pé àwọn ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ yìí máa mú káwọn kan “kú sára nítorí ìbẹ̀rù.” Àmọ́, tá a bá ń ronú nípa bí Jèhófà ṣe gba àwọn èèyàn rẹ̀ là nígbà àtijọ́, tá a sì ń ronú lórí àwọn nǹkan tó ti jẹ́ ká mọ̀ nípa ọjọ́ iwájú, àá lè ‘nàró ṣánṣán, ká sì gbé orí wa sókè,’ torí ó dá wa lójú pé ìdáǹdè wa ti sún mọ́lé.​—Lk 21:26, 28.