Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​—⁠Máa Ṣe Ìpadàbẹ̀wò

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​—⁠Máa Ṣe Ìpadàbẹ̀wò

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Ọ̀pọ̀ àwọn tó máa ń fi ìfẹ́ hàn sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ló fẹ́ mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run. (Ais 55:6) A gbọ́dọ̀ máa pa dà lọ bẹ̀ wọ́n wò lóòrèkóòrè láti kọ́ wọn kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lè máa tẹ̀ síwájú. Ìṣòro tí àwọn èèyàn ní yàtọ̀ síra, torí náà ohun tó máa wọ oníkálukú lọ́kàn máa ń yàtọ̀ síra. Ọ̀rọ̀ wa máa wọ àwọn èèyàn lọ́kàn tá a bá múra sílẹ̀ dáadáa, tá a ní ohun kan pàtó tá a fẹ́ sọ fún wọn, tá a sì fi sọ́kàn pé ńṣe la fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Gbìyànjú láti tètè pa dà lọ, tó bá ṣeé ṣe kó má ju ọjọ́ mélòó kan lọ sí ìgbà tẹ́ ẹ kọ́kọ́ pàdé.​—Mt 13:⁠19

  • Jẹ́ ọlọ́yàyà, bọ̀wọ̀ fún un, kó o sì fara balẹ̀

  • Kí i pẹ̀lú ọ̀yàyà. Fi orúkọ rẹ̀ pè é. Jẹ́ kó mọ̀ pé ó ní ìdí tó o fi pa dà wá. Ó lè jẹ́ láti dáhùn ìbéèrè kan, láti fún un ní ìwé ìròyìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde, láti fi ìkànnì wa hàn án, láti fi fídíò kan hàn án tàbí láti fi bá a ṣe ń bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án. Tí ohun tó ń jẹ onílé lọ́kàn bá yàtọ̀ sí ohun tó o fẹ́ bá a sọ, ńṣe ni kó o yí ọ̀rọ̀ rẹ pa dà.​—Flp 2:4

  • Ẹ jọ jíròrò kókó kan látinú Ìwé Mímọ́, kó o sì tún fún un ní ìwé ìròyìn kan, èyí á fi hàn pé ò ń bomi rin irúgbìn òtítọ́ tó o gbìn sínú rẹ̀. (1Kọ 3:6) Gbìyànjú láti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín wọ̀

  • Sọ ohun tẹ́ ẹ máa jíròrò nígbà tó o bá pa dà wá