May 19-25
ÒWE 14
Orin 89 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Ronú Jinlẹ̀ Kó O Tó Gbé Ìgbésẹ̀ Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀
(10 min.)
Má ṣe gba “gbogbo ọ̀rọ̀” gbọ́ (Owe 14:15; w23.02 22-23 ¶10-12)
Má ṣe gbára lé òye ara ẹ tàbí ìrírí tó o ní (Owe 14:12)
Má ṣe máa tẹ́tí sí àwọn tí kì í tẹ̀ lé ohun tí ètò Jèhófà bá sọ (Owe 14:7)
RONÚ LÓRÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Ẹ̀yin alàgbà, ṣẹ́ ẹ múra tán láti ṣé ohun tí ètò Ọlọ́run bá sọ, kẹ́ ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀?—w24.07 5 ¶11.
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
-
Owe 14:17—Kí ló ṣeé ṣe kó fà á táwọn èèyàn fi máa ń kórìíra “ẹni tó bá ń ro ọ̀rọ̀ wò”? (it-2 1094)
-
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Owe 14:1-21 (th ẹ̀kọ́ 11)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Ẹnì kan sọ fún ẹ nípa bí ọ̀rọ̀ àtijẹ-àtimu ṣe ṣòro tó, fi Bíbélì tù ú nínú. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 3)
5. Pa Dà Lọ
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fún ẹnì kan ní ìwé ìròyìn tó dá lórí ohun tó o kíyè sí pé ó nífẹ̀ẹ́ sí nígbà tẹ́ ẹ jọ sọ̀rọ̀ kẹ́yìn. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 4)
6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
(5 min.) Gba ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ níyànjú pé kó máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, kó o sì jẹ́ kó mọ bó ṣe lè ṣe é. (th ẹ̀kọ́ 19)
Orin 126
7. Múra Sílẹ̀ fún Àjálù
(15 min.) Ìjíròrò.
Alàgbà ni kó ṣe iṣẹ́ yìí. Mẹ́nu kan àwọn ìtọ́ni tí ẹ̀ka ọ́fíìsì ti fún yín àtèyí tí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà fohùn ṣọ̀kan lé lórí, ìyẹn tó bá wà.
A mọ̀ pé ìṣòro á máa pọ̀ sí i ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí. (2Ti 3:1; àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 24:8, nwtsty) Kí àjálù tó ṣẹlẹ̀ àti nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, àwa èèyàn Jèhófà máa ń gba ìtọ́ni tó lè gba ẹ̀mí wa là. Torí náà, tá a bá fẹ́ là á já, ó yẹ ká máa ṣe àwọn nǹkan táá mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára, ká sì ṣètò àwọn nǹkan tá a máa nílò tí àjálù bá ṣẹlẹ̀.—Owe 14:6, 8.
-
Mú kí ìgbàgbọ́ ẹ túbọ̀ lágbára: Jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa ka Bíbélì, kó o sì máa dá kẹ́kọ̀ọ́. Túbọ̀ já fáfá nínú oríṣiríṣi ọ̀nà tá à ń gbà wàásù. Má bẹ̀rù tó bá ṣẹlẹ̀ pé o ò mọ ibi táwọn ará tó kù nínú ìjọ wà. (Owe 14:30) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé o ò dá wà, Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi wà pẹ̀lú ẹ.—od 176 ¶15-17
-
Ṣètò àwọn nǹkan tó o máa nílò: Yàtọ̀ sí báàgì pàjáwìrì, ó yẹ kí ìdílé kọ̀ọ̀kan ní oúnjẹ, omi, oògùn àtàwọn nǹkan míì tẹ́ ẹ máa nílò tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ ò ní lè kúrò nílé fáwọn àkókò kan.—Owe 22:3; g17.5 4
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ De Àjálù? Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
-
Ọ̀nà wo ni Jèhófà ń gbà ràn wá lọ́wọ́ nígbà àjálù?
-
Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká ṣe ká lè múra sílẹ̀ fún àjálù?
-
Báwo la ṣe lè ran àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí lọ́wọ́?
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 26 ¶18-22, àpótí tó wà lójú ìwé 209