Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 36-37

Àwọn Ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù Hùwà Ìkà Sí I Torí Wọ́n Ń Jowú Rẹ̀

Àwọn Ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù Hùwà Ìkà Sí I Torí Wọ́n Ń Jowú Rẹ̀

37:3-9, 11, 23, 24, 28

Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù jẹ́ ká rí àkóbá tí owú máa ń fà. A to àwọn ìdí tí kò fi yẹ ká máa jowú sí ìsàlẹ̀ yìí, fàlà sí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn mu.

ÌDÍ TÍ KÒ FI YẸ KÁ MÁA JOWÚ

  • Àwọn tó bá ń jowú ò ní jogún ìjọba Ọlọ́run

  • Owú máa ń fa ìyapa nínú ìjọ, kì í sì í jẹ́ kí àlàáfíà wà

  • Owú máa ń ṣàkóbá fún ìlera wa

  • Owú kì í jẹ́ ká rí ibi táwọn míì dáa sí

Kí làwọn nǹkan tó lè mú ká máa jowú àwọn míì?