Àwọn ará ń tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe ní Switzerland

ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI May 2017

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a lè lò láti fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ lọni àti láti kọ́ni ní òtítọ́ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Lo àbá yìí láti fi kọ ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ rẹ.

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Àmì Tó Fi Hàn Pé Jèhófà Máa Mú Ísírẹ́lì Padà Bọ̀ Sípò

Ìlérí wo ni Jèhófà Ọlọ́run ṣe fún wòlí ì Jeremáyà nígbà tó sọ pé kó ra ilẹ̀? Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun jẹ́ ẹni rere?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ebedi-mélékì Jẹ́ Onígboyà àti Onínúure

Ebedi-mélékì lo ìgboyà, ó sì gbé ìgbésẹ̀ lójú ẹsẹ̀ láti lọ bá Ọba Sedekáyà, àmọ́ bó ṣe ran wòlí ì Ọlọ́run tó ń jẹ́ Jeremáyà lọ́wọ́ tún fi hàn pé ó jẹ́ onínúure.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Bá A Ṣe Lè Máa Bójú Tó Àwọn Ibi Ìjọsìn Wa

Àwọn ilé ìjọsìn wa jẹ́ ibi tá a yà sí mímọ́ fún Jèhófà, torí náà ó ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ kó máa wà ní mímọ́ tónítóní ká sì máa tún àwọn ohun tó bà jẹ́ ṣe. Báwo ni gbogbo wa ṣe lè máa bójú tó Gbọ̀ngàn Ìjọba wa?

TREASURES FROM GOD’S WORD

Jèhófà Máa San Olúkúlùkù Lẹ́san Níbàámu Pẹ̀lú Iṣẹ́ Rẹ̀

Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wòlí ì Jeremáyà àti Ọba Sedekáyà nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìparun Jerúsálẹ́mù, àmọ́ ọ̀rọ̀ wọn ò jọra rárá.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Jèhófà Kì Í Gbàgbé Ìfẹ́ Tá A Fi Hàn

Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn ìrànṣẹ́ rẹ̀ tó ti dàgbà, àmọ́ tí wọn ò lè ṣe tó ti tẹ́lẹ̀ mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Má Ṣe “Wá Àwọn Ohun Ńláńlá fún Ara Rẹ”

Olùjọ́sìn Jèhófà ni Bárúkù, ó sì fi tọkàntọkàn ti Jeremáyà lẹ́yìn, àmọ́ ìgbà kan wà tí kò fọkàn sí àwọn nǹkan tẹ̀mí mọ́. Kí ni Bárúkù gbọ́dọ̀ ṣe tó bá fẹ́ la ìparun Jerúsálẹ́mù já?

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Jèhófà Ń Bù Kún Àwọn Onírẹ̀lẹ̀ Ó sì Ń Fìyà Jẹ Àwọn Agbéraga

Àwọn ará Bábílónì jẹ́ agbéraga, wọ́n sì hùwà ìkà sí àwọn èèyàn Jèhófà. Jèhófà dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ronú pìwà dà sílẹ̀ nígbèkùn, àmọ́ kí ló ṣẹlẹ̀ sí Bábílónì?