Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁTÍÙ 25

“Ẹ Máa Bá A Nìṣó ní Ṣíṣọ́nà”

“Ẹ Máa Bá A Nìṣó ní Ṣíṣọ́nà”

25:​1-12

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni Jésù fi àkàwé nípa àwọn wúńdíá mẹ́wàá náà bá sọ̀rọ̀, síbẹ̀ gbogbo Kristẹni pátá làwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì inú ẹ̀ kàn. (w15 3/15 12-16) “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà.” (Mt 25:13) Ǹjẹ́ o lè ṣàlàyé àkàwé Jésù yìí?

  • Ọkọ ìyàwó (ẹsẹ 1)​—Jésù

  • Àwọn wúńdíá olóye tó múra sílẹ̀ (ẹsẹ 2)​—Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n múra sílẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé lé wọn lọ́wọ́ títí dé òpin láìkù-síbì-kan, tí wọ́n sì tàn bí ìmọ́lẹ̀ títí dé òpin (Flp 2:15)

  • Igbe ta: “Ọkọ ìyàwó ti dé!” (ẹsẹ 6)​—Àwọn àmì tó fi hàn pé Jésù ti dé

  • Àwọn òmùgọ̀ wúńdíá (ẹsẹ 8)​—Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n lọ pàdé ọkọ ìyàwó àmọ́ tí wọn ò bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, tí wọn ò sì pa ìwà títọ́ wọn mọ́

  • Àwọn wúńdíá olóye kò fún àwọn òmùgọ̀ wúńdíá náà ní òróró (ẹsẹ 9)​—Lẹ́yìn èdìdì ìkẹyìn, àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró kò ní lè ran ẹnikẹ́ni tó di aláìṣòótọ́ lọ́wọ́, ẹ̀pa kò ní bóró mọ́

  • “Ọkọ ìyàwó dé” (ẹsẹ 10)​—Jésù dé ní apá ìparí ìpọ́njú ńlá náà láti ṣe ìdájọ́

  • Àwọn wúńdíá olóye wọlé pẹ̀lú ọkọ ìyàwó síbi àsè ìgbéyàwó náà, a sì ti ilẹ̀kùn (ẹsẹ 10)​—Jésù máa kó àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró rẹ̀ lọ sí ọ̀run, àmọ́ àwọn ẹni àmì òróró aláìṣòótọ́ máa pàdánù èrè wọn ní ọ̀run