MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I —Bí O Ṣe Lè Kọ Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tó O Fẹ́ Lò Láti Fi Ìwé Ìròyìn Lọni
ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Òótọ́ ni pé àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a lè lò tó wà lójú ìwé àkọ́kọ́ ìwé ìpàdé yìí máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọ bá a ṣe lè gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lóde ẹ̀rí, àmọ́ àpẹẹrẹ ni wọ́n kàn jẹ́. Ó yẹ kó o máa gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lọ́rọ̀ ara rẹ. O lè gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà míì tàbí kó o sọ̀rọ̀ lórí àpilẹ̀kọ míì tó o mọ̀ pé àwọn tó wà ní ìpílẹ̀ ìwàásù yín máa nífẹ̀ẹ́ sí. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, tó o bá ti ka ìwé ìròyìn kan tán, tó o ti wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà nínú ìwé ìpàdé, tó o sì ti wo àwọn fídíò ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, o lè wá tẹ̀ lé àwọn àbá yìí láti kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.
BÓ O ṢE LÈ ṢE É:
Bi ara rẹ pé, ‘Ṣé ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ inú ìwé ìpàdé ni mo fẹ́ lò?’
BẸ́Ẹ̀ NI
-
Múra bó o ṣe máa bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ. Lẹ́yìn tó o bá ti kí onílé, ní ṣókí, sọ ìdí tó o fi wá fún un. (Àpẹẹrẹ: “Ìdí tí mo fi wá ni pé . . .”)
-
Ronú nípa ìbéèrè tí wàá bi onílé, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wàá kà fún un àti bí wàá ṣe fi ìwé lọ̀ ọ́. (Àpẹẹrẹ: Tó o bá fẹ́ nasẹ̀ Ìwé Mímọ́ tó o fẹ́ kà, o lè sọ pé: “Ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn nìyí.”)
BẸ́Ẹ̀ KỌ́
-
Yan àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn tó o nífẹ̀ẹ́ sí, tó o sì mọ̀ pé àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín náà á nífẹ̀ẹ́ sí
-
Pinnu ìbéèrè tí wàá bi onílé láti mọ èrò rẹ̀ lórí kókó ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ bá a sọ, èyí táá jẹ́ kẹ́ ẹ lè jọ fọ̀rọ̀ wérọ̀. Àmọ́, má ṣe béèrè ìbéèrè tó le lọ́wọ́ onílé. (Àpẹẹrẹ: Àwọn ìbéèrè tó wà lójú ìwé 2 nínú àwọn ìwé ìròyìn.)
-
Yan ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o máa kà fún onílé. (Tó o bá fẹ́ fi Jí! lọni, o lè yàn láti má ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ torí pé àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní ìmọ̀ Bíbélì tàbí tí wọn ò fọkàn tán ẹ̀sìn la ṣe é fún.)
-
Ronú ọ̀rọ̀ ṣókí tí wàá sọ láti fi ṣàlàyé bí onílé á ṣe jàǹfààní tó bá ka àpilẹ̀kọ tó o fẹ́ fi lọ̀ ọ́
ÈYÍ TÓ WÙ KÓ JẸ́
-
Múra ìbéèrè kan tí wàá bi onílé tí ẹ jọ máa jíròrò nígbà tó o bá pa dà wá
-
Ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìsọfúnni tó o nílò táá jẹ́ kó o rántí ohun tó o fẹ́ sọ nígbà míì tó o bá pa dà lọ sọ́dọ̀ onílé