Ṣé O Máa Wà Lára Àwọn Tá A Máa Sàmì Sí Láti Là Á Já?
Ìran ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jerúsálẹ́mù àtijọ́ pa run. Báwo ni ìran yẹn ṣe máa ṣẹ lóde òní?
-
Ọkùnrin tó ní ìwo yíǹkì akọ̀wé ṣàpẹẹrẹ Jésù Kristi
-
Àwọn ọkùnrin mẹ́fà tó ní àwọn ohun ìjà tó lè fọ́ nǹkan túútúú ṣàpẹẹrẹ àwọn ọmọ ogun ọ̀run, Kristi tó jẹ́ olórí wọn sì wà pẹ̀lú wọn
-
Lákòókò tí ìpọ́njú ńlá bá ń lọ lọ́wọ́, Jésù máa ṣe ìdájọ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá náà, ó sì máa sàmì sí wọn pé wọ́n jẹ́ àgùntàn