Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
JÍ!
Béèrè Ìbéèrè: Ṣé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì lóòótọ́? Àbí èrò àwọn èèyàn ni wọ́n kàn kọ síbẹ̀?
Ka Bíbélì: 2Ti 3:16
Fi ìwé lọni: Ìwé ìròyìn Jí! yìí sọ̀rọ̀ nípa kókó mẹ́ta tó fi hàn pé Ọlọ́run ló mí sí Bíbélì lóòótọ́.
MÁA FI ÒTÍTỌ́ KỌ́NI
Béèrè Ìbéèrè: Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo ẹ̀mí?
Ka Bíbélì: Iṣi 4:11
Òtítọ́: A ka ẹ̀mí sí pàtàkì, torí pé Ọlọ́run ló fún wa. A kì í fi ọ̀rọ̀ ààbò ṣeré, a ò sì ní mọ̀ọ́mọ̀ pa ẹlòmíì. A mọyì ẹ̀mí gan-an.
KÍ LÓ LÈ MÚ KÍ ÌDÍLÉ LÁYỌ̀?
Béèrè Ìbéèrè: Ẹ wo ìbéèrè tó wà ní iwájú ìwé yìí. Èwo lẹ fara mọ́ nínú àwọn ìdáhùn tó wà níbẹ̀?
Ka Bíbélì: Lk 11:28
Fi ìwé lọni: Ìwé yìí sọ àǹfààní tí ohun tá a kà nínú Bíbélì yẹn lè ṣe fún ìdílé yín.
KỌ Ọ̀NÀ ÌGBỌ́RỌ̀KALẸ̀ RẸ
Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ