ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI June 2017
Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a lè lò láti fi ìwé ìròyìn Jí! lọni àti láti kọ́ni nípa ẹ̀mí tí Ọlọ́run fún wa. Lo àbá yìí láti fi kọ ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ rẹ.
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Gbogbo Ọ̀rọ̀ Jèhófà Máa Ń Ṣẹ Láìkù Síbì Kan
Gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ tó wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ Jeremáyà nípa bí wọ́n ṣe máa ṣẹ́gun Bábílónì tó sì máa dahoro ló ṣẹ láìkù síbì kan.
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Báwo Ni Ìgbàgbọ́ Rẹ Nínú Àwọn Ìlérí Jèhófà Ṣe Lágbára Tó?
Jóṣúà jẹ́rìí sí i pé kò sí ọ̀kan nínú àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tí kò ṣẹ. Báwo ni àwa náà ṣe lè mú kí ìgbàgbọ́ wa nínú àwọn ìlérí Jèhófà túbọ̀ lágbára?
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Ẹ̀mí Ìdúródeni Ń Jẹ́ Ká Ní Ìfaradà
Kí ló ran Jeremáyà lọ́wọ́ tó fi fara da ìṣòro tó lágbára gan-an, tí kò sì ṣìwà hù? Báwo ni mo ṣe lè múra sílẹ̀ de àwọn ìṣòro tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú?
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Inú Ìsíkíẹ́lì Dùn Láti Kéde Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Nínú ìran kan tí Ìsíkíẹ́lì rí, Jèhófà fún un ní àkájọ ìwé kan, ó sì sọ pé kó jẹ ẹ́. Kí ni ohun tí Ìsíkíẹ́lì ṣe yẹn túmọ̀ sí?
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Jẹ́ Kí Iṣẹ́ Ìwàásù Ìhìn Rere Máa Fún Ẹ Láyọ̀
Iṣẹ́ ìwàásù máa ń ṣòro nígbà mí ì, àmọ́ Ọlọ́run fẹ́ ká máa láyọ̀ bá a ṣe ń sin òun. Báwo la ṣe lè máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Ṣé O Máa Wà Lára Àwọn Tá A Máa Sàmì Sí Láti Là Á Já?
Ìran ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jerúsálẹ́mù àtijọ́ pa run. Báwo ni ìran yẹn ṣe máa ṣẹ lóde òní?
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Máa Tẹ̀ Lé Àwọn Ìlànà Jèhófà Nínú Ìwà àti Ìṣe Rẹ
A kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà Ọlọ́run nínú ìwà àti ìṣe wa. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?