Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

July 22-28

SÁÀMÙ 66-68

July 22-28

Orin 7 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Jèhófà Ń Bá Wa Gbé Ẹrù Wa Lójoojúmọ́

(10 min.)

Jèhófà máa ń tẹ́tí sí àdúrà wa, ó sì máa ń dáhùn rẹ̀ (Sm 66:19; w23.05 12 ¶15)

Jèhófà ò fọ̀rọ̀ àwọn tí nǹkan ò rọrùn fún ṣeré, ó sì ṣe tán láti pèsè ohun tí wọ́n nílò (Sm 68:5; w10 12/1 23 ¶6; w09 4/1 31 ¶1)

Ojoojúmọ́ ni Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ (Sm 68:19; w23.01 19 ¶17)

RONÚ LÓRÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Báwo ni Jèhófà ṣe ń bá wa gbé ẹrù wa?

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 68:18—Ní Ísírẹ́lì àtijọ́, àwọn wo ni “ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn”? (w06 6/1 10 ¶5)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Àṣà ìbílẹ̀ ẹni náà yàtọ̀ sí tìẹ. (lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 3)

5. Pa Dà Lọ

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Máa bá ìjíròrò rẹ lọ nínú ìwé ìléwọ́ tó o fún ẹni náà nígbà tó o kọ́kọ́ wàásù fún un. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 3)

6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 102

7. Ṣé O Lè Mú Kí Ẹrù Ẹnì Kan Fúyẹ́?

(15 min.) Ìjíròrò.

Kò yẹ kí ìránṣẹ́ Jèhófà èyíkéyìí dá fàyà rán ìṣòro ẹ̀. (2Kr 20:15; Sm 127:1) Ìdí ni pé Jèhófà ni Olùrànlọ́wọ́ wa. (Ais 41:10) Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà máa ń gbà ràn wá lọ́wọ́? Ó máa ń fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò rẹ̀ tọ́ wa sọ́nà. (Ais 48:17) Ó máa ń fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Lk 11:13) Ó tún máa ń lo àwọn ará wa láti ràn wá lọ́wọ́ kí wọ́n sì fún wa níṣìírí. (2Kọ 7:6) Èyí fi hàn pé Jèhófà lè lo ẹnikẹ́ni nínú wa láti mú kí ẹrù àwọn ará wa fúyẹ́.

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Máa Fi Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Hàn Sáwọn—Àgbàlagbà. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí lo lè ṣe kí ẹrù àwọn Kristẹni tó jẹ́ àgbàlagbà lè fúyẹ́?

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Máa Fi Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Hàn Sáwọn—Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí lo lè ṣe kí ẹrù àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún lè fúyẹ́?

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Máa Fi Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Hàn Sáwọn—Àjèjì. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí lo lè ṣe kí ẹrù àwọn tó ń kojú ìṣòro tó lágbára lè fúyẹ́?

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 88 àti Àdúrà