July 15-21
SÁÀMÙ 63-65
Orin 108 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. “Ìfẹ́ Rẹ Tí Kì Í Yẹ̀ Sàn Ju Ìyè”
(10 min.)
Kéèyàn ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe pàtàkì ju ìyè lọ (Sm 63:3; w01 10/15 15-16 ¶17-18)
A máa túbọ̀ mọyì Jèhófà tá a bá ń ronú lórí bó ṣe ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí wa (Sm 63:6; w19.12 28 ¶4; w15 10/15 24 ¶7)
Tá a bá mọyì ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Jèhófà ní sí wa, ìyẹn á jẹ́ kínú wa máa dùn bá a ṣe ń yìn ín (Sm 63:4, 5; w09 7/15 16 ¶6)
OHUN TẸ́ Ẹ LÈ ṢE NÍGBÀ ÌJỌSÌN ÌDÍLÉ: Ẹ sọ àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ti gbà fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí yín.
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
-
Sm 64:3—Báwo ni ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa sọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró? (w07 11/15 15 ¶6)
-
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Sm 63:1–64:10 (th ẹ̀kọ́ 12)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(2 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Ẹni tó o fẹ́ wàásù fún ò gbọ́ èdè rẹ. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 4)
5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(2 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. O ò ráyè wàásù títí ìjíròrò náà fi parí. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 4)
6. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Fọgbọ́n wádìí ohun tó ń jẹ ẹni náà lọ́kàn, kó o sì béèrè bó o ṣe lè kàn sí i nígbà míì. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 5)
7. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́
(4 min.) Àṣefihàn. ijwfq 51—Àkòrí: Kí Nìdí Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Máa Ń Pa Dà Lọ Sọ́dọ̀ Àwọn Tó Ti Sọ Pé “Mi Ò Fẹ́ Gbọ́”? (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 3)
Orin 154
8. Bá A Ṣe Lè Fi Hàn Pé A Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run
(15 min.) Ìjíròrò.
‘Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀’ tí Jèhófà ní pọ̀ gidigidi. (Sm 86:15) Ọ̀rọ̀ náà ‘ìfẹ́ tí kì í yẹ̀’ túmọ̀ sí ìfẹ́ tí ẹni tó ṣeé fọkàn tán, tó jẹ́ olóòótọ́, adúróṣinṣin àti adúrótini máa ń ní sáwọn èèyàn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́, àwọn tó jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀ nìkan ló máa ń fi ‘ìfẹ́ tí kì í yẹ̀’ hàn sí. (Sm 33:18; 63:3; Jo 3:16; Iṣe 14:17) A lè fi hàn pé a mọyì ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Jèhófà ní sí wa táwa náà bá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ títí kan èyí tó sọ pé ká máa ‘sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.’—Mt 28:19; 1Jo 5:3.
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Máa Fi Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Hàn Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Báwo ni ìfẹ́ ṣe ń mú ká wàásù
-
tó bá rẹ̀ wá?
-
táwọn èèyàn bá ta kò wá?
-
lẹ́nu ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́?
9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 12 ¶14-20