August 30–September 5
DIUTARÓNÓMÌ 31-32
Orin 78 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ohun Tí Àpèjúwe Tó Wà Nínú Orin Onímìísí Kan Kọ́ Wa”: (10 min.)
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí: (10 min.)
Di 31:12—Báwo làwọn òbí ṣe lè fi ìlànà yìí sílò? (w04 9/15 27 ¶11)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min.) Di 32:36-52 (th ẹ̀kọ́ 2)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min.) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ tí wọn ò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 3)
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min.) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Sọ ohun tó máa bá ipò onílé mu, kó o sì ka ẹsẹ Bíbélì tó máa wọ̀ ọ́ lọ́kàn. (th ẹ̀kọ́ 12)
Àsọyé: (5 min.) w07 5/15 15-16—Àkòrí: Àwọn Ọmọ Rẹ Ń Wò Ẹ́! (th ẹ̀kọ́ 16)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Àpẹẹrẹ Àwọn Tó Ń Múpò Iwájú: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò ‘Ẹ Máa Rántí Àwọn Tó Ń Mú Ipò Iwájú’ (Heb 13:7). Lẹ́yìn náà, bi àwọn ará pé: Kí la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ T. J. Sullivan? George Gangas? Karl Klein? Daniel Sydlik?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) rr orí 13 ¶1-6 àti fídíò ohun tó wà ní orí 13
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.)
Orin 128 àti Àdúrà