MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ìfọkànsin Ọlọ́run Tàbí Eré Ìdárayá
Ṣé àǹfààní wà nínú kéèyàn máa ṣeré ìdárayá? Bẹ́ẹ̀ ni, àmọ́ bíńtín ló jẹ́ tá a bá fi wéra pẹ̀lú àǹfààní tá a máa rí tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ ká sún mọ́ Jèhófà. (1Ti 4:8) Torí náà, ó yẹ kí àwa Kristẹni ní èrò tó tọ́ nípa eré ìdárayá.
WO FÍDÍÒ ERÉ OJÚ PÁTÁKÓ NÁÀ OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀ NÍPA ERÉ ÌDÁRAYÁ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
1. Àwọn nǹkan wo la lè rí kọ́ látinú eré ìdárayá?
-
2. Kí ni àwọn nǹkan mẹ́ta tó máa pinnu bóyá ó máa dáa ká ṣeré ìdárayá kan tàbí ká má ṣe é?
-
3. Báwo ni Sáàmù 11:5 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ irú eré ìdárayá tó yẹ ká ṣe?
-
4. Báwo la ṣe lè fi Fílípì 2:3 àti Òwe 16:18 sílò nípa ọ̀nà tá à ń gbà ṣeré ìdárayá?
-
5. Nígbà tá a bá ń ṣe eré ìdárayá tàbí tá à ń wò ó, báwo ni Fílípì 1:10 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí ẹ̀?