January 10-16
ÀWỌN ONÍDÀÁJỌ́ 17-19
Orin 88 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Téèyàn Bá Rú Òfin Ọlọ́run, Àbájáde Ẹ̀ Kì Í Dáa”: (10 min.)
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì: (10 min.)
Ond 19:18—Kí nìdí tá a ṣe fi orúkọ Jèhófà sínú ẹsẹ Bíbélì yìí nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe lọ́dún 2013 (w15 12/15 10 ¶6)
Àwọn ìṣúra wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min.) Ond 17:1-13 (th ẹ̀kọ́ 2)
TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Fídíò Ìpadàbẹ̀wò: (5 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò Ìpadàbẹ̀wò: Ọlọ́run Ń Bójú Tó Wa—Jer 29:11. Ẹ dá fídíò náà dúró láwọn ibi tẹ́ ẹ bá ti rí ìbéèrè, kẹ́ ẹ sì jíròrò ìbéèrè náà kẹ́ ẹ tó máa wò ó lọ.
Ìpadàbẹ̀wò: (3 min.) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. (th ẹ̀kọ́ 6)
Ìpadàbẹ̀wò: (5 min.) Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ. Lẹ́yìn náà fún ẹni náà ní ìwé pẹlẹbẹ Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! kó o sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ẹ̀kọ́ 01. (th ẹ̀kọ́ 13)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà—Máa Ṣègbọràn sí Àwọn Òbí Rẹ: (10 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà, tó bá ṣeé ṣe, pe àwọn ọmọdé bíi mélòó kan, kó o sì béèrè àwọn ìbéèrè yìí lọ́wọ́ wọn: Kí ni mọ́mì Kọ́lá ní kó ṣe àmọ́ tí kò ṣe? Kí ni Kọ́lá ṣe tó fi hàn pé ó ṣàtúnṣe? Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa gbọ́ràn sáwọn òbí ẹ lẹ́nu?
Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ: (5 min.)
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) rr orí 18 ¶16-25
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.)
Orin 150 àti Àdúrà