Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di dandan fún wa.”​—2Kọ 5:14

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ṣé Wàá Fẹ́ Ṣe Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ Lóṣù March Tàbí April?

Ṣé Wàá Fẹ́ Ṣe Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ Lóṣù March Tàbí April?

Ṣé wàá fẹ́ ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ní àkókò Ìrántí Ikú Kristi? (2Kọ 5:14, 15) Lóṣù March àti April, àwọn tó bá fẹ́ ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lè yàn láti ròyìn ọgbọ̀n (30) wákàtí tàbí àádọ́ta (50). Tó bá máa rọrùn fún ẹ láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ pàtàkì yìí, gba fọ́ọ̀mù aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, kọ ọ̀rọ̀ kún inú rẹ̀, kó o sì fún Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ yín. Wọ́n máa ka orúkọ àwọn tó bá fẹ́ ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún ìjọ, ìyẹn á sì jẹ́ kí àwọn ará túbọ̀ jáde láàárín oṣù yẹn láti ràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa lo àǹfààní àsìkò Ìrántí Ikú Kristi yìí láti fún ara wa níṣìírí, ká sì tún já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.​—1Tẹ 5:11.