Wọ́n Fẹ̀sùn Kan Pọ́ọ̀lù Pé Alákòóbá Ni àti Pé Ó Ń Ru Ìdìtẹ̀ Sókè
23:12, 16; 24:2, 5, 6, 10-21
Àwọn Júù tó wà ní Jerúsálẹ́mù “fi ègún de ara wọn” pé àwọn gbọ́dọ̀ pa Pọ́ọ̀lù. (Iṣe 23:12) Àmọ́, ìfẹ́ Jèhófà ni pé kí Pọ́ọ̀lù lọ wàásù ní Róòmù. (Iṣe 23:11) Nígbà tí ìbátan Pọ́ọ̀lù kan gbọ́ pé wọ́n fẹ́ pa á, ó lọ sọ fún Pọ́ọ̀lù, ìyẹn ni kò jẹ́ kí wọ́n rí Pọ́ọ̀lù pa. (Iṣe 23:16) Kí ni ìtàn yìí kọ́ ẹ nípa . . .
-
ohunkóhun táwọn èèyàn bá ṣe láti ta ko ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn?
-
ohun tí Ọlọ́run lè ṣe láti ràn wá lọ́wọ́?
-
ìgboyà?