MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Máa Fi Ìháragàgà Dúró Dè É Pẹ̀lú Ìfaradà
Báwo ló ti ṣe pẹ́ tó, tí o ti ń retí pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé? Ó ṣeé ṣe kó o ti máa fi sùúrù fara da àwọn ìṣòro tó le koko. (Ro 8:25) Wọ́n ń ṣe inúnibíni sí àwọn kan lára wa, wọ́n ń hùwà ìkà sáwọn míì, àwọn kan lára wa wà lẹ́wọ̀n, wọ́n sì ń fi ikú halẹ̀ mọ́ àwọn míì. Àìsàn burúkú ló ń bá àwọn kan fínra, ọjọ́ ogbó ni tàwọn míì.
Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti máa fi ìháragàgà dúró, tí ìṣòro èyíkéyìí bá tiẹ̀ ń bá wa fínra? A gbọ́dọ̀ máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, ká sì máa ronú lórí ohun tá à ń kà, ìyẹn ló máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i. A tún gbọ́dọ̀ pọkàn pọ̀ sórí ìrètí tá a ní. (2Kọ 4:16-18; Heb 12:2) A gbọ́dọ̀ máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà pé kó fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́. (Lk 11:10, 13; Heb 5:7) Baba wa onífẹ̀ẹ́ máa ràn wá lọ́wọ́ ká ‘lè fara dà á ní kíkún, ká sì máa ní ìpamọ́ra pẹ̀lú ìdùnnú.’—Kol 1:11.
WO FÍDÍÒ NÁÀ A GBỌ́DỌ̀ ‘FI ÌFARADÀ SÁRÉ’—JẸ́ KÓ DÁ Ọ LÓJÚ PÉ WÀÁ GBA ÈRÈ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
“Ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” wo ló lè wáyé? (Onw 9:11)
-
Ìrànlọ́wọ́ wo ni àdúrà máa ń ṣe fún wa tá a bá wà nínú ìṣòro?
-
Tá ò bá lè ṣe tó báa ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀ nínú ìjọsìn Jèhófà, kí nìdí tó fi yẹ ká máa pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tí agbára wa ká?
-
Kí ló mú kó dá ẹ lójú pé wàá rí èrè náà gbà?