February 8 sí 14
NEHEMÁYÀ 5-8
Orin 123 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Alábòójútó Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀ Ni Nehemáyà”: (10 min.)
Ne 5:1-7
—Nehemáyà tẹ́tí sí àwọn èèyàn náà, ó sì gbé ìgbésẹ̀ (w06 2/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 2) Ne 5:14-19
—Nehemáyà jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, aláìmọ̀-tara-ẹni-nìkan àti olóye (w06 2/1 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 4) Ne 8:8-12
—Nehemáyà kópa nínú kíkọ́ àwọn èèyàn náà ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run (w06 2/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 4)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Ne 6:5
—Kí nìdí tí Sáńbálátì ṣe fi “lẹ́tà tí a kò lẹ̀” ránṣẹ́ sí Nehemáyà? (w06 2/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 3) Ne 6:10-13
—Kí nìdí tí Nehemáyà kò fi gba ìmọ̀ràn Ṣemáyà? (w07 7/1 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 15) Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?
Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?
Bíbélì Kíkà: Ne 6:14–7:7a (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Fi àpilẹ̀kọ tó dá lórí kókó iwájú ìwé ìròyìn Jí! ti lọ́ọ́lọ́ọ́ lọni. Sọ ohun tí wàá bá ẹni náà jíròrò nígbà tó o bá pa dà wá..
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè ṣe ìpadàbẹ̀wò ẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí àpilẹ̀kọ tó dá lórí kókó iwájú ìwé ìròyìn Jí! ti lọ́ọ́lọ́ọ́ tí wọ́n fi lọ̀ ọ́. Sọ ohun tí wàá bá ẹni náà jíròrò nígbà tó o bá tún pa dà wá.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ṣe àṣefihàn bí a ṣe máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (bh ojú ìwé 28 sí 29 ìpínrọ̀ 4 àti 5)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Orin 62
Ǹjẹ́ Ò Ń ‘Nàgà fún Iṣẹ́ Àtàtà’?: (15 min.) Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí, a gbé e ka Ilé Ìṣọ́ September 15, 2014, ojú ìwé 3 sí 6. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò tá a pe àkọlé rẹ̀ ní, Ẹ̀yin Arákùnrin—Ẹ Wá Bẹ́ Ẹ Ṣe Máa Ṣe Púpọ̀ Sí I Nínú Iṣẹ́ Ọlọ́run, ó wà nínú Ètò Tẹlifíṣọ̀n JW ti oṣù December 2015. Tẹnu mọ́ ìdí tó fi yẹ kí àwọn arákùnrin máa nàgà fún iṣẹ́ àtàtà, kó o sì ṣàlàyé bí wọ́n ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀. Gba àwọn arákùnrin níyànjú pé kí wọ́n sapá kí wọ́n lè tóótun láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti alàgbà.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: ia orí 8 ìpínrọ̀ 17 sí 27 àti àtúnyẹ̀wò tó wà lójú ìwé 75 (30 min.)
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 125 àti Àdúrà