Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

August 24-30

Ẹ́KÍSÓDÙ 19-20

August 24-30
  • Orin 88 àti Àdúrà

  • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

  • Ẹ̀kọ́ Tí Òfin Mẹ́wàá Náà Kọ́ Wa Lónìí”: (10 min.)

    • Ẹk 20:​3-7​—Bọlá fún Jèhófà, kó o sì máa jọ́sìn òun nìkan (w89 11/15 6 ¶1)

    • Ẹk 20:​8-11​—Ìjọsìn Jèhófà ni kó ṣe pàtàkì jù lọ láyé rẹ

    • Ẹk 20:​12-17​—Máa bọlá fáwọn míì (w89 11/15 6 ¶2-3)

  • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.)

    • Ẹk 19:​5, 6​—Kí nìdí tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ fi pàdánù àǹfààní tí wọ́n ní láti di “ìjọba àwọn àlùfáà”? (it-2 687 ¶1-2)

    • Ẹk 20:​4, 5​—Báwo ni Jèhófà ṣe ń “fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá” jẹ àwọn àtọmọdọ́mọ wọn? (w04 3/15 27 ¶1)

    • Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?

  • Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ẹk 19:​1-19 (th ẹ̀kọ́ 10)

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

  • Orin 91

  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Kí N Lè Túbọ̀ Lómìnira?: (6 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò eré ojú pátákó náà. Lẹ́yìn náà, bi àwọn ọ̀dọ́ pé: Kí lo lè ṣe káwọn òbí ẹ lè fọkàn tán ẹ? Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá ṣàṣìṣe? Tó o bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn òbí ẹ, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ fún ẹ lómìnira?

  • Máa Tọ́jú Àwọn Òbí Ẹ Àgbà: (9 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà, béèrè pé: Àwọn ìṣòro wo ló lè yọjú báwọn òbí ṣe túbọ̀ ń dàgbà? Kí nìdí tó fi yẹ káwọn tó wà nínú ìdílé jọ sọ̀rọ̀ dáadáa tí wọ́n bá fẹ́ pinnu bí wọ́n á ṣe tọ́jú àwọn òbí wọn? Báwo làwọn ọmọ ṣe lè bọlá fáwọn òbí wọn tí wọ́n ń tọ́jú?

  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) jy orí 129 àti àpótí “Bí Wọ́n Ṣe Máa Ń Na Ọ̀daràn

  • Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

  • Orin 13 àti Àdúrà