MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Máa Kẹ́gbẹ́ Pẹ̀lú Àwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà? Torí pé àwọn tá à ń bá kẹ́gbẹ́ lè jẹ́ ká hùwà tó tọ́, wọ́n sì lè jẹ́ ká hùwà tí kò tọ́. (Owe 13:20) Bí àpẹẹrẹ, Ọba Jèhóáṣì ṣe “ohun tí ó tọ́ lójú Jèhófà” nígbà tó ń kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Àlùfáà Àgbà Jèhóádà. (2Kr 24:2) Àmọ́ lẹ́yìn tí Jèhóádà kú, Jèhóáṣì fi Jèhófà sílẹ̀ torí ẹgbẹ́ búburú tó kó.—2Kr 24:17-19.
Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìjọ Kristẹni wé “ilé ńlá,” ó sì fi àwọn ará ìjọ wé “àwọn ohun èlò” tàbí ohun èlò ilé. “Ohun tó ní ọlá” la máa jẹ́ tá ò bá ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣe nǹkan tínú Ọlọ́run kò dùn sí, kódà kẹ́ni náà tiẹ̀ jẹ́ mọ̀lẹ́bí wa tàbí ará ìjọ wa. (2Ti 2:20, 21) Torí náà, ó yẹ ká máa báa lọ láti máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, torí pé àwọn ló máa fún wa níṣìírí láti máa sin Jèhófà nìṣó.
WO FÍDÍÒ NÁÀ PINNU LÁTI KỌ ẸGBẸ́ BÚBURÚ SÍLẸ̀ LÁKỌ̀TÁN, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Báwo la ṣe lè bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́gbẹ́ búburú láìmọ̀?
-
Nínú fídíò yẹn, kí ló ran àwọn Kristẹni mẹ́ta yẹn lọ́wọ́ láti kọ ẹgbẹ́ búburú sílẹ̀?
-
Ìlànà Bíbélì wo ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti yan àwọn tí wàá máa bá ṣe wọléwọ̀de?