April 13-19
JẸ́NẸ́SÍSÌ 31
Orin 112 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Jékọ́bù àti Lábánì Dá Májẹ̀mú Àlàáfíà”: (10 min.)
Jẹ 31:44-46—Jékọ́bù àti Lábánì fi òkúta ṣe òkìtì, wọ́n sì jọ jẹun lórí òkúta náà láti dá májẹ̀mú (it-1 883 ¶1)
Jẹ 31:47-50—Wọ́n pe orúkọ ibẹ̀ ní Gáléédì àti Ilé Ìṣọ́ (it-2 1172)
Jẹ 31:51-53—Wọ́n jọ ṣèlérí pé àwọn ò ní ṣe ara wọn ní jàǹbá
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (10 min.)
Jẹ 31:19—Kí ló ṣeé ṣe kó mú kí Réṣẹ́lì jí àwọn ère tẹ́ráfímù tó jẹ́ ti bàbá rẹ̀? (it-2 1087-1088)
Jẹ 31:41, 42—Kí la rí kọ́ lára Jékọ́bù tó bá jẹ́ pé ẹni “tó ṣòroó tẹ́ lọ́rùn” ló gbà wá síṣẹ́? (1Pe 2:18; w13 3/15 21 ¶8)
Àwọn ìṣúra tẹ̀mí wo lo tún rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí nípa Jèhófà, iṣẹ́ ìwàásù tàbí àwọn nǹkan míì?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Jẹ 31:1-18 (th ẹ̀kọ́ 10)
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́—Fídíò: (4 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà, lẹ́yìn náà béèrè àwọn ìbéèrè yìí: Báwo ni arábìnrin yìí ṣe jẹ́ kí kókó tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì tó kà ṣe kedere? Kí ló sọ tó fi múra ọkàn onílé sílẹ̀ fún ìpadàbẹ̀wò?
Nígbà Àkọ́kọ́: (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. Onílé sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ní ìpínlẹ̀ yín tí wọn kò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Fèsì ní ṣókí, kó o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ. (th ẹ̀kọ́ 4)
Nígbà Àkọ́kọ́: (5 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Lo ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tó wà lójú ìwé 1. Lẹ́yìn náà fún onílé ní ìwé Ìròyìn Ayọ̀, kó o sì fi ẹ̀kọ́ 5 bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (th ẹ̀kọ́ 8)
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ẹ Ran Àwọn Aláìṣiṣẹ́mọ́ Lọ́wọ́: (20 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí. Jẹ́ káwọn ará wo fídíò Jèhófà Ń Bójú Tó Àwọn Àgùntàn Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ṣàkópọ̀ àwọn kókó tó wà ní ojú ìwé 14 nínú ìwé pẹlẹbẹ Jọ̀wọ́ Pa Dà Sọ́dọ̀ Jèhófà. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ tu àwùjọ lára.
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) bh orí 18 ¶1-7
Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
Orin 146 àti Àdúrà