Ohun Tó Wà Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká mọ̀, ìyẹn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló wà nínú Bíbélì. Ó jẹ́ ká mọ bí a ṣe lè ṣàṣeyọrí nígbèésí ayé àti bí a ṣe lè rí ojú rere Ọlọ́run. Ó tún dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
BÍ O ṢE LÈ WÁ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ
Ìwé kéékèèké mẹ́rìndínláàádọ́rin (66) ló para pọ̀ di Bíbélì. Apá méjì ló pín sí, ìyẹn Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti Árámáíkì tí wọ́n ń pè ní (“Májẹ̀mú Láéláé”) àti Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì tí wọ́n ń pè ní (“Májẹ̀mú Tuntun.”) Ìwé kọ̀ọ̀kan tó wà nínú Bíbélì ní àwọn orí àti ẹsẹ. Tí a bá tọ́ka sí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, nọ́ńbà tó tẹ̀ lé orúkọ ìwé yẹn dúró fún orí, nígbà tí nọ́ńbà tó tẹ̀ lé e dúró fún ẹsẹ. Bí àpẹẹrẹ, Jẹ́nẹ́sísì 1:1 túmọ̀ sí Jẹ́nẹ́sísì orí 1, ẹsẹ 1.