Sekaráyà 13:1-9
13 “Ní ọjọ́ yẹn, wọn yóò gbẹ́ kànga kan fún ilé Dáfídì àti fún àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù láti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ àti èérí wọn mọ́.+
2 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ pé, “Ní ọjọ́ yẹn, èmi yóò pa orúkọ àwọn òrìṣà rẹ́ ní ilẹ̀ náà,+ wọn ò sì ní rántí wọn mọ́; èmi yóò sì mú àwọn wòlíì+ àti ẹ̀mí àìmọ́ kúrò ní ilẹ̀ náà.
3 Tí ọkùnrin kan bá tún ń sọ tẹ́lẹ̀, bàbá àti ìyá tó bí i yóò sọ fún un pé, ‘O ti fi orúkọ Jèhófà parọ́, o máa kú ni!’ Bàbá àti ìyá tó bí i yóò sì gún un pa torí pé ó sọ àsọtẹ́lẹ̀.+
4 “Ní ọjọ́ yẹn, ojú yóò ti àwọn wòlíì nítorí ìran tí kálukú wọn ń rí nígbà tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀; wọn ò sì ní wọ aṣọ onírun+ mọ́ láti tan àwọn èèyàn jẹ.
5 Yóò sì sọ pé, ‘Èmi kì í ṣe wòlíì. Àgbẹ̀ ni mí, torí ọkùnrin kan rà mí láti kékeré.’
6 Tí ẹnì kan bá sì bi í pé, ‘Ọgbẹ́ wo ló wà lára rẹ yìí?’* yóò dáhùn pé, ‘Ilé àwọn ọ̀rẹ́ mi* ni mo ti fara gba ọgbẹ́.’”
7 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ pé, “Ìwọ idà, dìde sí olùṣọ́ àgùntàn mi,+Sí ọkùnrin tó jẹ́ ọ̀rẹ́ mi.
Kọ lu olùṣọ́ àgùntàn,+ kí agbo* sì tú ká;+Èmi yóò sì yí ọwọ́ mi pa dà sí àwọn tí kò já mọ́ nǹkan kan.”
8 Jèhófà sọ pé, “Ní gbogbo ilẹ̀ náà,Ìdá méjì nínú rẹ̀ yóò pa run, yóò sì ṣègbé;*Ìdá kẹta yóò sì ṣẹ́ kù síbẹ̀.
9 Èmi yóò fi ìdá kẹta sínú iná;Èmi yóò yọ́ wọn mọ́ bí wọ́n ṣe ń yọ́ fàdákà mọ́,Èmi yóò sì yẹ̀ wọ́n wò bí wọ́n ṣe ń yẹ wúrà wò.+
Wọ́n á ké pe orúkọ mi,Èmi yóò sì dá wọn lóhùn.
Màá sọ pé, ‘Èèyàn mi ni wọ́n,’+
Wọ́n á sì sọ pé, ‘Jèhófà ni Ọlọ́run wa.’”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “láàárín ọwọ́ rẹ yìí?” Ìyẹn, ní àyà tàbí ẹ̀yìn.
^ Tàbí “àwọn tó fẹ́ràn mi.”
^ Tàbí “àgùntàn.”
^ Tàbí “kú.”