Sáàmù 58:1-11
-
Ọlọ́run kan wà tó ń ṣèdájọ́ ayé
-
Àdúrà pé kí ìyà jẹ àwọn ẹni burúkú (6-8)
-
Sí olùdarí; kí a yí i sí “Má Ṣe Pa Á Run.” Ti Dáfídì. Míkítámù.*
58 Ṣé ẹ lè sọ nípa òdodo nígbà tó jẹ́ pé ńṣe lẹ dákẹ́?+
Ṣé ẹ lè fi òdodo ṣe ìdájọ́, ẹ̀yin ọmọ èèyàn?+
2 Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀ ń hùmọ̀ àìṣòdodo nínú ọkàn yín,+Ọwọ́ yín sì ń gbé ìwà ipá jáde ní ilẹ̀ náà.+
3 Àwọn ẹni burúkú ti ṣìnà* látìgbà tí wọ́n ti bí wọn;*Oníwàkiwà ni wọ́n, òpùrọ́ sì ni wọ́n látìgbà tí wọ́n ti bí wọn.
4 Oró wọ́n dà bí oró ejò;+Wọ́n jẹ́ adití bí ejò ṣèbé tó di etí rẹ̀.
5 Kì í fetí sí ohùn àwọn atujú,Kò sí bí wọ́n ṣe mọ ọfọ̀ pè tó.
6 Ọlọ́run, gbá eyín wọn yọ kúrò lẹ́nu wọn!
Fọ́ páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ àwọn kìnnìún yìí,* Jèhófà!
7 Kí wọ́n pòórá bí ìgbà tí omi bá gbẹ.
Kí Ó tẹ ọrun rẹ̀, kí ọfà rẹ̀ sì mú kí wọ́n ṣubú.
8 Kí wọ́n dà bí ìgbín tó ń yọ́ dà nù bó ṣe ń lọ;Bí ọmọ tí obìnrin kan bí ní òkú, tí kò rí oòrùn.
9 Kí àwọn ìkòkò oúnjẹ yín tó mọ iná igi ẹlẹ́gùn-ún lára,Ọlọ́run yóò gbá ẹ̀ka tútù àti èyí tó ń jó, bí ìgbà tí ìjì bá gbá nǹkan dà nù.+
10 Olódodo yóò máa yọ̀ nítorí pé ó ti rí ẹ̀san;+Ẹ̀jẹ̀ ẹni burúkú yóò rin ẹsẹ̀ rẹ̀ gbingbin.+
11 Nígbà náà, aráyé á sọ pé: “Dájúdájú, èrè wà fún olódodo.+
Ní tòótọ́, Ọlọ́run kan wà tó ń ṣe ìdájọ́ ayé.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “ya oníwà ìbàjẹ́.”
^ Ní Héb., “látinú ilé ọmọ wá.”
^ Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”