Sáàmù 52:1-9
Sí olùdarí. Másíkílì.* Ti Dáfídì, nígbà tí Dóẹ́gì ọmọ Édómù wá, tó sì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé Dáfídì wá sí ilé Áhímélékì.+
52 Kí ló dé tí ò ń fi ìwà burúkú rẹ ṣògo, ìwọ alágbára ńlá?+
Ṣé o kò mọ̀ pé ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀ wà láti ọjọ́ dé ọjọ́ ni?+
2 Ahọ́n rẹ mú bí abẹ fẹ́lẹ́,+Ó ń pète ibi, ó sì ń ṣiṣẹ́ ẹ̀tàn.+
3 Ìwọ nífẹ̀ẹ́ ohun búburú ju ohun rere lọ,O sì nífẹ̀ẹ́ pípa irọ́ ju sísọ ohun tí ó tọ́. (Sélà)
4 O nífẹ̀ẹ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tó ń pani run,Ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn!
5 Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run yóò fi mú ọ balẹ̀ láìtún gbérí mọ́;+Yóò gbá ọ mú, yóò sì fà ọ́ kúrò nínú àgọ́ rẹ;+Yóò fà ọ́ tu kúrò ní ilẹ̀ alààyè.+ (Sélà)
6 Àwọn olódodo á rí i, ẹnu á yà wọ́n,+Wọ́n á sì fi í rẹ́rìn-ín.+
7 “Ọkùnrin yìí kò fi Ọlọ́run ṣe ibi ààbò* rẹ̀,+Àmọ́ ó gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀pọ̀ ọrọ̀ tó ní,+Èrò ibi tó wà lọ́kàn rẹ̀* ló sì gbára lé.”*
8 Ṣùgbọ́n màá dà bí igi ólífì tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run;Ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé+ títí láé àti láéláé.
9 Èmi yóò máa yìn ọ́ títí láé torí pé o ti gbé ìgbésẹ̀;+Níwájú àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ,Màá gbẹ́kẹ̀ lé orúkọ rẹ,+ nítorí ó dára.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “odi ààbò.”
^ Ní Héb., “Àgbákò látọwọ́ rẹ̀.”
^ Tàbí “fi ṣe ibi ààbò.”