Sáàmù 48:1-14
Orin. Orin àwọn ọmọ Kórà.+
48 Jèhófà tóbi, òun sì ni ìyìn yẹ jù lọNí ìlú Ọlọ́run wa, ní òkè mímọ́ rẹ̀.
2 Gíga rẹ̀ rẹwà, ayọ̀ gbogbo ayé,+Òkè Síónì tó jìnnà réré ní àríwá,Ìlú Ọba Títóbi Lọ́lá.+
3 Nínú àwọn ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò,Ọlọ́run ti jẹ́ kí a mọ̀ pé òun ni ibi ààbò.*+
4 Wò ó! àwọn ọba ti kóra jọ;*Wọ́n jọ tẹ̀ síwájú.
5 Nígbà tí wọ́n rí i, ẹnu yà wọ́n.
Jìnnìjìnnì bá wọn, wọ́n sì sá kìjokìjo.
6 Ìbẹ̀rù mú wọn níbẹ̀,Ìrora bíi ti obìnrin tó ń rọbí.
7 O fi ẹ̀fúùfù ìlà oòrùn fọ́ àwọn ọkọ̀ òkun Táṣíṣì.
8 A ti wá fi ojú wa rí ohun tí a ti gbọ́Ní ìlú Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, ní ìlú Ọlọ́run wa.
Ọlọ́run yóò fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin títí láé.+ (Sélà)
9 A ronú lórí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, Ọlọ́run,+Nínú tẹ́ńpìlì rẹ.
10 Bí orúkọ rẹ ṣe lọ, Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìyìn rẹṢe lọ títí dé ìkángun ayé.+
Òdodo kún ọwọ́ ọ̀tún rẹ.+
11 Kí inú Òkè Síónì+ máa dùn,Kí àwọn ìlú* Júdà sì máa yọ̀, nítorí àwọn ìdájọ́ rẹ.+
12 Ẹ rìn yí ká Síónì; ẹ lọ káàkiri inú rẹ̀;Ẹ ka àwọn ilé gogoro rẹ̀.+
13 Ẹ kíyè sí àwọn òkìtì tó wà lẹ́yìn ògiri rẹ̀.*+
Ẹ ṣàyẹ̀wò àwọn ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò,Kí ẹ lè ròyìn rẹ̀ fún ìran ọjọ́ iwájú.
14 Nítorí Ọlọ́run yìí ni Ọlọ́run wa+ títí láé àti láéláé.
Yóò máa ṣamọ̀nà wa títí láé.*+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ibi gíga tó láàbò.”
^ Tàbí “pàdé bí wọ́n ṣe ṣàdéhùn.”
^ Ní Héb., “ọmọbìnrin.”
^ Tàbí “odi ààbò.”
^ Tàbí kó jẹ́, “títí a ó fi kú.”