Sáàmù 38:1-22
Orin Dáfídì, kí ó jẹ́ ìránnilétí.*
38 Jèhófà, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ,Má sì tọ́ mi sọ́nà nínú ìrunú rẹ.+
2 Nítorí àwọn ọfà rẹ ti gún mi wọnú,Ọwọ́ rẹ sì rìn mí mọ́lẹ̀.+
3 Gbogbo ara mi ń ṣàìsàn* nítorí ìbínú rẹ.
Kò sí àlàáfíà nínú egungun mi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi.+
4 Àwọn àṣìṣe mi rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lórí mi;+Bí ẹrù tó wúwo, wọ́n ti wúwo ju ohun tí mo lè gbé.
5 Àwọn egbò mi ti kẹ̀, wọ́n sì ń rùnNítorí ìwà òmùgọ̀ mi.
6 Ìdààmú àti ìrẹ̀wẹ̀sì tó lé kenkà bá mi;Mò ń rìn kiri nínú ìbànújẹ́ láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.
7 Iná ń jó nínú mi lọ́hùn-ún;*Gbogbo ara mi ń ṣàìsàn.+
8 Ara mi ti kú tipiri, àárẹ̀ sì ti bá mi gidigidi;Mò ń kérora* nítorí ìdààmú tó bá ọkàn mi.
9 Jèhófà, gbogbo ìfẹ́ ọkàn mi wà níwájú rẹ,Ẹ̀dùn ọkàn mi kò sì pa mọ́ fún ọ.
10 Ọkàn mi ń lù kì-kì, agbára mi ti tán,Ojú mi sì ti ṣú.*+
11 Àwọn ọ̀rẹ́ mi àti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi yẹra fún mi nítorí ìyọnu tó dé bá mi,Àwọn ojúlùmọ̀ tó sún mọ́ mi sì ta kété sí mi.
12 Àwọn tó ń wá ẹ̀mí* mi dẹ pańpẹ́ sílẹ̀;Àwọn tó fẹ́ ṣe mí léṣe ń sọ nípa ìparun;+Ẹ̀tàn ni wọ́n ń sọ lẹ́nu wúyẹ́wúyẹ́ láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.
13 Àmọ́, màá ṣe bí adití, mi ò ní fetí sí wọn;+Màá ṣe bí ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀, mi ò ní la ẹnu mi.+
14 Mo dà bí ẹni tí kò gbọ́ràn,Tí kò ní nǹkan kan tó máa sọ láti gbèjà ara rẹ̀.
15 Nítorí ìwọ Jèhófà ni mo dúró dè,+O sì dá mi lóhùn, Jèhófà Ọlọ́run mi.+
16 Torí mo sọ pé: “Kí wọ́n má yọ̀ mí,Kí wọ́n má sì gbé ara wọn ga sí mi tí ẹsẹ̀ mi bá yẹ̀.”
17 Nítorí mo ti fẹ́ ṣubú lulẹ̀,Ara sì ń ro mí nígbà gbogbo.+
18 Mo jẹ́wọ́ àṣìṣe mi;+Ẹ̀ṣẹ̀ mi dààmú mi.+
19 Àmọ́ àwọn ọ̀tá mi lókun,* wọ́n sì lágbára,*Àwọn tó kórìíra mi láìnídìí ti pọ̀ gan-an.
20 Wọ́n ń fi ibi san ire fún mi;Wọ́n ń ta kò mí nítorí mò ń lépa ohun rere.
21 Má fi mí sílẹ̀, Jèhófà.
Má jìnnà sí mi,+ Ọlọ́run mi.
22 Tètè wá ràn mí lọ́wọ́,Jèhófà, ìgbàlà mi.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “láti ránni létí.”
^ Ní Héb., “Kò sí ibì kankan tó dá ṣáṣá lára mi.”
^ Ní Héb., “Iná gba abẹ́ mi kan.”
^ Tàbí “ké ramúramù.”
^ Ní Héb., “Ìmọ́lẹ̀ ojú mi sì ti lọ.”
^ Tàbí “ọkàn.”
^ Ní Héb., “wà láàyè.”
^ Tàbí kó jẹ́, “Àwọn tó sọ ara wọn di ọ̀tá mi láìnídìí pọ̀.”