Sáàmù 37:1-40
Ti Dáfídì.
א [Áléfì]
37 Má banú jẹ́* nítorí àwọn ẹni burúkúTàbí kí o jowú àwọn aṣebi.+
2 Kíákíá ni wọ́n á gbẹ dà nù bíi koríko+Wọ́n á sì rọ bíi koríko tútù.
ב [Bétì]
3 Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí o sì máa ṣe rere;+Máa gbé ayé,* kí o sì máa hùwà òtítọ́.+
4 Jẹ́ kí inú rẹ máa dùn jọjọ* nínú Jèhófà,Yóò sì fún ọ ní àwọn ohun tí ọkàn rẹ fẹ́.
ג [Gímélì]
5 Fi ọ̀nà rẹ lé Jèhófà lọ́wọ́;*+Gbẹ́kẹ̀ lé e, yóò sì gbé ìgbésẹ̀ nítorí rẹ.+
6 Yóò mú kí òdodo rẹ yọ bí ọjọ́,Àti ìwà títọ́ rẹ bí oòrùn ọ̀sán gangan.
ד [Dálétì]
7 Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Jèhófà+Kí o sì dúró* dè é.
Má banú jẹ́ nítorí ẹniTó gbèrò ibi, tó sì mú un ṣẹ.+
ה [Híì]
8 Fi ìbínú sílẹ̀, kí o sì pa ìrunú tì;+Má ṣe bínú kí o wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ibi.*
9 Nítorí a ó mú àwọn ẹni ibi kúrò,+Àmọ́ àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ni yóò jogún ayé.+
ו [Wọ́ọ̀]
10 Láìpẹ́, àwọn ẹni burúkú ò ní sí mọ́;+
Wàá wo ibi tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀,Wọn ò ní sí níbẹ̀.+
11 Àmọ́ àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóò jogún ayé,+Inú wọn yóò sì máa dùn jọjọ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.+
ז [Sáyìn]
12 Ẹni burúkú ń dìtẹ̀ olódodo;+Ó ń wa eyín pọ̀ sí i.
13 Àmọ́ Jèhófà yóò fi í rẹ́rìn-ín,Nítorí Ó mọ̀ pé ọjọ́ rẹ̀ máa dé.+
ח [Hétì]
14 Àwọn ẹni burúkú fa idà wọn yọ, wọ́n sì tẹ* ọrun wọnLáti mú àwọn tí à ń ni lára àti àwọn aláìní balẹ̀,Láti pa àwọn tí ọ̀nà wọn tọ́.
15 Àmọ́ idà àwọn fúnra wọn yóò gún ọkàn wọn;+A ó sì ṣẹ́ ọrun wọn.
ט [Tétì]
16 Ohun díẹ̀ tí olódodo níSàn ju ọ̀pọ̀ nǹkan tí àwọn ẹni burúkú ní.+
17 A ó ṣẹ́ apá àwọn ẹni burúkú,Àmọ́ Jèhófà yóò ti àwọn olódodo lẹ́yìn.
י [Yódì]
18 Jèhófà mọ ohun tí àwọn aláìlẹ́bi ń bá yí,*Ogún wọn yóò sì wà títí láé.+
19 Ní àkókò àjálù, ojú kò ní tì wọ́n;Ní àkókò ìyàn, wọ́n á ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ.
כ [Káfì]
20 Àmọ́ àwọn ẹni burúkú yóò ṣègbé;+Àwọn ọ̀tá Jèhófà yóò pòórá bí ibi ìjẹko tó léwé dáadáa;Wọ́n á pòórá bí èéfín.
ל [Lámédì]
21 Ẹni burúkú ń yá nǹkan, kì í sì í san án pa dà,Àmọ́ olódodo lawọ́,* ó sì ń fúnni ní nǹkan.+
22 Àwọn tí Ọlọ́run bù kún yóò jogún ayé,Àmọ́ àwọn tí Ọlọ́run gégùn-ún fún yóò pa rẹ́.+
מ [Mémì]
23 Jèhófà máa ń darí ẹsẹ̀ ẹni*+Nígbà tí inú Rẹ̀ bá dùn sí ọ̀nà ẹni náà.+
24 Bí onítọ̀hún bá tiẹ̀ ṣubú, kò ní balẹ̀ pátápátá,+Nítorí pé Jèhófà dì í lọ́wọ́ mú.*+
נ [Núnì]
25 Mo ti jẹ́ ọ̀dọ́ rí, àmọ́ ní báyìí mo ti darúgbó,Síbẹ̀, mi ò tíì rí i kí a pa olódodo tì,+Tàbí kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ* kiri.+
26 Ó máa ń yáni ní nǹkan látọkàn wá,+Ìbùkún sì ń dúró de àwọn ọmọ rẹ̀.
ס [Sámékì]
27 Yẹra fún ohun búburú, máa ṣe rere,+Wàá sì máa gbé ayé títí láé.
28 Nítorí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo,Kò sì ní kọ àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀.+
ע [Áyìn]
Ìgbà gbogbo ni yóò máa ṣọ́ wọn;+Àmọ́ a ó pa àtọmọdọ́mọ àwọn ẹni burúkú rẹ́.+
29 Àwọn olódodo ni yóò jogún ayé,+Wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.+
פ [Péè]
30 Ẹnu olódodo ń sọ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n,*Ahọ́n rẹ̀ sì ń sọ nípa ìdájọ́ òdodo.+
31 Òfin Ọlọ́run rẹ̀ wà ní ọkàn rẹ̀;+Ẹsẹ̀ rẹ̀ kò ní tàsé.+
צ [Sádì]
32 Ẹni burúkú ń ṣọ́ olódodo,Ó sì ń wá ọ̀nà láti pa á.
33 Àmọ́ Jèhófà kò ní jẹ́ kí ọwọ́ ẹni yẹn tẹ̀ ẹ́,+Kò sì ní dá a lẹ́bi nígbà tí wọ́n bá ṣèdájọ́ rẹ̀.+
ק [Kófì]
34 Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí o sì máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀,Yóò gbé ọ ga láti jogún ayé.
Nígbà tí a bá pa àwọn ẹni burúkú rẹ́,+ wàá rí i.+
ר [Réṣì]
35 Mo ti rí ìkà ẹ̀dá tó jẹ́ olubiTó ń tẹ́ rẹrẹ bí igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ ní ilẹ̀ tó dàgbà sí.+
36 Àmọ́, ó kọjá lọ lójijì, kò sì sí mọ́;+Mo wá a kiri, mi ò sì rí i.+
ש [Ṣínì]
37 Máa fiyè sí aláìlẹ́bi,*Kí o sì máa wo adúróṣinṣin,+Nítorí àlàáfíà ń dúró de ẹni yẹn ní ọjọ́ ọ̀la.+
38 Àmọ́ a ó pa gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ rẹ́,Ìparun ló sì ń dúró de àwọn ẹni burúkú ní ọjọ́ ọ̀la.+
ת [Tọ́ọ̀]
39 Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìgbàlà àwọn olódodo ti wá;+Òun ni odi ààbò wọn ní àkókò wàhálà.+
40 Jèhófà á ràn wọ́n lọ́wọ́, á sì gbà wọ́n sílẹ̀.+
Á gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú, á sì gbà wọ́n là,Nítorí òun ni wọ́n fi ṣe ibi ààbò.+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “gbaná jẹ.”
^ Tàbí “ilẹ̀ náà.”
^ Tàbí “Ní ayọ̀ tó kọyọyọ.”
^ Ní Héb., “Yí ọ̀nà rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà.”
^ Tàbí “fi sùúrù dúró.”
^ Tàbí kó jẹ́, “Má ṣe bínú, torí á mú kí o ṣe ibi.”
^ Tàbí “fi okùn sí.”
^ Ní Héb., “àwọn ọjọ́ àwọn aláìlẹ́bi.”
^ Tàbí “ń ṣàánú.”
^ Tàbí “mú kí ẹsẹ̀ ẹni múlẹ̀.”
^ Tàbí “fi ọwọ́ Rẹ̀ dì í mú.”
^ Ní Héb., “búrẹ́dì.”
^ Tàbí “ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ sọ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n.”
^ Tàbí “ẹni tó ń pa ìwà títọ́ mọ́.”