Sáàmù 14:1-7
Sí olùdarí. Ti Dáfídì.
14 Òmùgọ̀* sọ lọ́kàn rẹ̀ pé:
“Kò sí Jèhófà.”+
Ìwà ìbàjẹ́ ni wọ́n ń hù, ìṣesí wọn sì jẹ́ ohun ìríra;Kò sí ẹni tó ń ṣe rere.+
2 Àmọ́ Jèhófà ń bojú wo àwọn ọmọ èèyàn láti ọ̀runLáti rí i bóyá ẹnì kan wà tó ní ìjìnlẹ̀ òye, bóyá ẹnì kan wà tó ń wá Jèhófà.+
3 Gbogbo wọn ti kúrò lójú ọ̀nà;+Gbogbo wọn jẹ́ oníwà ìbàjẹ́.
Kò sí ẹni tó ń ṣe rere,Kò tiẹ̀ sí ẹyọ kan.
4 Ṣé kò yé ìkankan lára àwọn oníwà burúkú ni?
Wọ́n ń ya àwọn èèyàn mi jẹ bí ẹni ń jẹ búrẹ́dì.
Wọn ò ké pe Jèhófà.
5 Àmọ́, jìnnìjìnnì á bò wọ́n,+Nítorí Jèhófà wà pẹ̀lú ìran àwọn olódodo.
6 Ẹ̀yin oníwà burúkú fẹ́ da èrò aláìní rú,Àmọ́ Jèhófà ni ibi ààbò rẹ̀.+
7 Ká ní ìgbàlà Ísírẹ́lì lè wá láti Síónì+ ni!
Nígbà tí Jèhófà bá kó àwọn èèyàn rẹ̀ tó wà lóko ẹrú pa dà,Kí inú Jékọ́bù dùn, kí Ísírẹ́lì sì yọ̀.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “Òpònú.”