Sáàmù 137:1-9

  • Létí àwọn odò Bábílónì

    • Wọn ò kọ orin Síónì (3, 4)

    • Bábílónì máa di ahoro (8)

137  Létí àwọn odò Bábílónì,+ ibẹ̀ la jókòó sí. A sunkún nígbà tí a rántí Síónì.+  Orí àwọn igi pọ́pílà tó wà láàárín rẹ̀*Ni a gbé àwọn háàpù wa kọ́.+  Ibẹ̀ ni àwọn tó mú wa lẹ́rú ti ní ká kọrin,+Àwọn tó ń fi wá ṣẹ̀sín fẹ́ ká dá àwọn lára yá, wọ́n ní: “Ẹ kọ ọ̀kan lára àwọn orin Síónì fún wa.”  Báwo la ó ṣe kọ orin JèhófàNí ilẹ̀ àjèjì?  Tí mo bá gbàgbé rẹ, ìwọ Jerúsálẹ́mù,Kí ọwọ́ ọ̀tún mi gbàgbé ohun tó mọ̀ ọ́n ṣe.*+  Kí ahọ́n mi lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu miTí mi ò bá rántí rẹ,Tí mi ò bá gbé Jerúsálẹ́mù ga kọjáOlórí ohun tó ń fún mi láyọ̀.+  Jèhófà, jọ̀wọ́ rántíOhun tí àwọn ọmọ Édómù sọ lọ́jọ́ tí Jerúsálẹ́mù ṣubú, wọ́n ní: “Ẹ wó o palẹ̀! Ẹ wó o palẹ̀ dé ìpìlẹ̀ rẹ̀!”+  Ìwọ ọmọbìnrin Bábílónì, tí kò ní pẹ́ di ahoro,+Aláyọ̀ ni ẹni tó máa san ọ́ lẹ́sanLórí ohun tí o ṣe sí wa.+  Aláyọ̀ ni ẹni tó máa gba àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ rẹ,Tí á sì là wọ́n mọ́ àpáta.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ó ń tọ́ka sí Bábílónì.
Tàbí kó jẹ́, “Kí ọwọ́ ọ̀tún mi rọ.”