Sáàmù 122:1-9

  • Àdúrà fún àlàáfíà Jerúsálẹ́mù

    • Ayọ̀ tó wà nínú lílọ sí ilé Jèhófà (1)

    • Ìlú tó so pọ̀ mọ́ra (3)

Orin Ìgòkè. Ti Dáfídì. 122  Mo yọ̀ nígbà tí wọ́n sọ fún mi pé: “Jẹ́ ká lọ sí ilé Jèhófà.”+  Ní báyìí, ẹsẹ̀ wa dúróNí àwọn ẹnubodè rẹ, ìwọ Jerúsálẹ́mù.+  A kọ́ Jerúsálẹ́mù bí ìlú,Ó so pọ̀ mọ́ra.+  Àwọn ẹ̀yà ti lọ síbẹ̀,Àwọn ẹ̀yà Jáà,*Kí wọ́n lè fi ọpẹ́ fún orúkọ Jèhófà,Gẹ́gẹ́ bí ìrántí fún Ísírẹ́lì.+  Nítorí ibẹ̀ la gbé àwọn ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀ sí,+Àwọn ìtẹ́ ilé Dáfídì.+  Ẹ gbàdúrà pé kí Jerúsálẹ́mù ní àlàáfíà.+ Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ yóò wà láìséwu, ìwọ ìlú.  Kí àlàáfíà máa wà nínú àwọn odi rẹ,*Kí ààbò sì wà nínú àwọn ilé gogoro rẹ tó láàbò.  Nítorí àwọn arákùnrin mi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi, màá sọ pé: “Kí àlàáfíà wà nínú rẹ.”  Nítorí ilé Jèhófà Ọlọ́run wa,+Màá wá ire fún ọ.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

“Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.
Tàbí “àwọn odi ààbò rẹ.”