Sáàmù 111:1-10

  • Ẹ yin Jèhófà nítorí àwọn iṣẹ́ rẹ̀ tóbi

    • Orúkọ Ọlọ́run jẹ́ mímọ́, ó sì yẹ fún ọ̀wọ̀ (9)

    • Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ọgbọ́n (10)

111  Ẹ yin Jáà!*+א [Áléfì] Màá fi gbogbo ọkàn mi yin Jèhófà+ב [Bétì] Nínú àwùjọ àwọn adúróṣinṣin àti nínú ìjọ. ג [Gímélì]   Àwọn iṣẹ́ Jèhófà tóbi;+ד [Dálétì] Gbogbo àwọn tó fẹ́ràn wọn máa ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn.+ ה [Híì]   Àwọn iṣẹ́ rẹ̀ ní ògo àti ọlá ńlá,ו [Wọ́ọ̀] Òdodo rẹ̀ sì wà títí láé.+ ז [Sáyìn]   Ó ń mú ká rántí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀.+ ח [Hétì] Jèhófà jẹ́ agbatẹnirò* àti aláàánú.+ ט [Tétì]   Ó ń fún àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ ní oúnjẹ.+ י [Yódì] Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ títí láé.+ כ [Káfì]   Ó ti fi àwọn iṣẹ́ agbára rẹ̀ han àwọn èèyàn rẹ̀ל [Lámédì] Bó ṣe fún wọn ní ogún àwọn orílẹ̀-èdè.+ מ [Mémì]   Àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́ òdodo;+נ [Núnì] Gbogbo àṣẹ rẹ̀ ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé.+ ס [Sámékì]   Wọ́n ṣeé gbára lé ní gbogbo ìgbà, ní báyìí àti títí láé;ע [Áyìn] Inú òtítọ́ àti òdodo ni wọ́n ti wá.+ פ [Péè]   Ó ti ra àwọn èèyàn rẹ̀ pa dà,+צ [Sádì] Ó pàṣẹ pé kí májẹ̀mú rẹ̀ wà títí láé. ק [Kófì] Orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́, ó sì yẹ fún ọ̀wọ̀.+ ר [Réṣì] 10  Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n.+ ש [Sínì] Gbogbo àwọn tó ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀* mọ́ ní òye tó jinlẹ̀ gan-an.+ ת [Tọ́ọ̀] Ìyìn rẹ̀ wà títí láé.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.
Tàbí “olóore ọ̀fẹ́.”
Ní Héb., “pa wọ́n.”