Orin Sólómọ́nì 1:1-17

  • Orin tó ju orin lọ (1)

  • Ọ̀dọ́bìnrin (2-7)

  • Àwọn ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù (8)

  • Ọba (9-11)

    • “A máa fi wúrà ṣe ohun ọ̀ṣọ́ fún ọ” (11)

  • Ọ̀dọ́bìnrin (12-14)

    • “Olólùfẹ́ mi dà bí àpò òjíá tó ń ta sánsán” (13)

  • Olùṣọ́ àgùntàn (15)

    • “O rẹwà gan-an, olólùfẹ́ mi”

  • Ọ̀dọ́bìnrin(16, 17)

    • “O rẹwà púpọ̀, olólùfẹ́ mi” (16)

1  Orin tó ju orin lọ,* tí Sólómọ́nì+ kọ:   “Wá fẹnu kò mí lẹ́nu,Torí ìfẹ́ tí ò ń fi hàn sí mi dára ju wáìnì lọ.+   Bí àwọn òróró rẹ ṣe ń ta sánsán ń tuni lára.+ Orúkọ rẹ dà bí òróró tó ń ta sánsán tí wọ́n tú jáde.+ Ìdí nìyẹn tí àwọn ọ̀dọ́bìnrin fi nífẹ̀ẹ́ rẹ.   Mú mi dání;* jẹ́ ká sáré. Ọba ti mú mi wọnú àwọn yàrá rẹ̀ tó wà ní inú! Jẹ́ kí inú wa máa dùn, ká sì jọ máa yọ̀. Jẹ́ ká yin* ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tí ò ń fi hàn sí mi ju ọ̀rọ̀ wáìnì lọ. Abájọ tí wọ́n* fi nífẹ̀ẹ́ rẹ.   Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù, mo dúdú lóòótọ́, àmọ́ òrékelẹ́wà ni mí,Bí àwọn àgọ́ tí wọ́n fi Kídárì ṣe,+ bí àwọn aṣọ àgọ́+ Sólómọ́nì.   Ẹ má tẹjú mọ́ mi torí pé mo dúdú,Oòrùn ló sọ mí dà bẹ́ẹ̀. Àwọn ọmọ ìyá mi bínú sí mi;Wọ́n ní kí n máa bójú tó àwọn ọgbà àjàrà,Àmọ́ mi ò bójú tó ọgbà àjàrà tèmi.   Ìwọ ẹni tí mo nífẹ̀ẹ́* gan-an, sọ fún mi,Ibi ìjẹko tí o ti ń da àwọn ẹran rẹ,+Ibi tí ò ń mú kí wọ́n dùbúlẹ̀ sí ní ọ̀sán. Ṣé ó wá yẹ kí n dà bí obìnrin tó fi aṣọ bojú*Nínú agbo ẹran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ?”   “Tó ò bá mọ̀, ìwọ obìnrin tó rẹwà jù,Gba ibi tí agbo ẹran náà gbà,Kí o sì jẹ́ kí àwọn ọmọ ewúrẹ́ rẹ máa jẹko lẹ́gbẹ̀ẹ́ àgọ́ àwọn olùṣọ́ àgùntàn.”   “Olólùfẹ́ mi, mo fi ọ́ wé abo ẹṣin* láàárín àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin Fáráò.+ 10  Ohun ọ̀ṣọ́* mú kí ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ lẹ́wà,Ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ sì mú kí ọrùn rẹ lẹ́wà. 11  A máa fi wúrà ṣe ohun ọ̀ṣọ́* fún ọ,A ó sì fi fàdákà sí i lára.” 12  “Nígbà tí ọba jókòó sídìí tábìlì rẹ̀,Lọ́fínńdà*+ mi ń ta sánsán. 13  Lójú mi, olólùfẹ́ mi dà bí àpò òjíá+ tó ń ta sánsán, Tó ń sùn mọ́jú láàárín ọmú mi. 14  Lójú mi, olólùfẹ́ mi rí bí ìdì ewé làálì,+Láàárín àwọn ọgbà àjàrà Ẹ́ń-gédì.”+ 15  “Wò ó! O rẹwà gan-an, olólùfẹ́ mi. Wò ó! O rẹwà gan-an. Ojú rẹ rí bíi ti àdàbà.”+ 16  “Wò ó! O rẹwà púpọ̀,* olólùfẹ́ mi, o sì wù mí gan-an.+ Àárín ewéko ni ibùsùn wa. 17  Igi kédárì ni àwọn òpó ilé* wa,Igi júnípà ni a sì fi ró ilé wa.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Orin tó dùn jù lọ.”
Ní Héb., “Fà mí lọ́wọ́.”
Tàbí “sọ.”
Ìyẹn, àwọn ọ̀dọ́bìnrin.
Tàbí “tó lo aṣọ ọ̀fọ̀ tí wọ́n fi ń bojú.”
Tàbí “tí ọkàn mi fẹ́.”
Tàbí “abo ẹṣin mi.”
Tàbí kó jẹ́, “Irun tí o dì.”
Tàbí “ohun ọ̀ṣọ́ tó rí roboto.”
Ní Héb., “Sípíkénádì.”
Tàbí “O dára lọ́mọkùnrin.”
Tàbí “ilé ńlá.”