Oníwàásù 6:1-12

  • Ọ̀pọ̀ ohun ìní láìsí ìgbádùn (1-6)

  • Gbádùn ohun tí o ní nísinsìnyí (7-12)

6  Àdánù* míì wà tí mo ti rí lábẹ́ ọ̀run,* ó sì máa ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn èèyàn:  Ọlọ́run tòótọ́ fún ọkùnrin kan ní ọrọ̀ àti ohun ìní àti ògo, tí kò fi ṣaláìní ohunkóhun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́; síbẹ̀ Ọlọ́run tòótọ́ kò jẹ́ kó gbádùn àwọn ohun náà, àmọ́ ó jẹ́ kí àlejò gbádùn wọn. Asán ni èyí àti ìpọ́njú tó lágbára.  Tí ọkùnrin kan bá bímọ ní ọgọ́rùn-ún ìgbà, tó lo ọ̀pọ̀ ọdún láyé, tó sì darúgbó, síbẹ̀ tí* kò gbádùn àwọn ohun rere tó ní kó tó wọnú sàréè,* ohun tí màá sọ ni pé ọmọ tí wọ́n bí ní òkú sàn jù ú lọ.+  Torí pé ẹni yìí wá lásán, ó sì lọ nínú òkùnkùn, òkùnkùn bo orúkọ rẹ̀ mọ́lẹ̀.  Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rí oòrùn, kò sì mọ nǹkan kan, ó ṣì sàn* ju ẹni ìṣáájú lọ.+  Kí làǹfààní kéèyàn gbé ẹgbẹ̀rún ọdún láyé ní ìlọ́po méjì, àmọ́ kó má gbádùn nǹkan kan? Torí pé ibì kan náà ni gbogbo èèyàn ń lọ.+  Gbogbo iṣẹ́ àṣekára téèyàn ń ṣe, torí kó lè rí nǹkan fi sẹ́nu ni;+ síbẹ̀ kì í* yó.  Nítorí àǹfààní wo ni ọlọ́gbọ́n ní lórí òmùgọ̀?+ Tàbí àǹfààní kí ló jẹ́ fún aláìní pé ó mọ bí èèyàn ṣe ń tọ́jú ara rẹ̀?*  Ó sàn kéèyàn máa gbádùn ohun tí ojú rẹ̀ rí ju kó máa dààmú lórí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́.* Asán ni èyí pẹ̀lú, ìmúlẹ̀mófo.* 10  Ohunkóhun tó bá wà, ó ti ní orúkọ tẹ́lẹ̀, a ti mọ ohun tí èèyàn jẹ́; kò sì lè bá ẹni tó lágbára jù ú lọ jiyàn.* 11  Bí ọ̀rọ̀* bá ṣe pọ̀ náà ni asán á ṣe pọ̀, àǹfààní wo sì ni èèyàn máa rí nínú wọn? 12  Ta ló mọ ohun tó dára jù lọ fún èèyàn láti fi ayé rẹ̀ ṣe láàárín ọjọ́ díẹ̀ tó máa fi gbé ìgbé ayé asán, èyí tó máa kọjá lọ bí òjìji?+ Àbí ta ló lè sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ọ̀run* fún èèyàn lẹ́yìn tó bá ti lọ?

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “Àjálù.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”
Tàbí “tí ọkàn rẹ̀.”
Tàbí “kí ibojì tó jẹ́ tirẹ̀.”
Ní Héb., “ní ìsinmi.”
Tàbí “ọkàn rẹ̀ kì í.”
Ní Héb., “máa rìn níwájú àwọn alààyè.”
Tàbí “kí ọkàn rẹ̀ máa rìn káàkiri.”
Tàbí “lílépa ẹ̀fúùfù.”
Tàbí “gbèjà ara rẹ̀ níwájú ẹni tó lágbára jù ú lọ.”
Tàbí kó jẹ́, “nǹkan.”
Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”