Nọ́ńbà 32:1-42

  • Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ní ìlà oòrùn Jọ́dánì (1-42)

32  Ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọmọ Rúbẹ́nì+ àti àwọn ọmọ Gádì+ ní ẹran ọ̀sìn tó pọ̀ gan-an, wọ́n sì rí i pé ilẹ̀ Jásérì+ àti ilẹ̀ Gílíádì dáa fún àwọn ẹran ọ̀sìn.  Torí náà, àwọn ọmọ Gádì àti àwọn ọmọ Rúbẹ́nì lọ bá Mósè àti àlùfáà Élíásárì pẹ̀lú àwọn ìjòyè àpéjọ náà pé:  “Átárótì, Díbónì, Jásérì, Nímírà, Hẹ́ṣíbónì,+ Éléálè, Sébámù, Nébò+ àti Béónì,+  àwọn ilẹ̀ tí Jèhófà bá àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ ṣẹ́gun, dáa fún àwọn ẹran ọ̀sìn,+ ẹran ọ̀sìn àwa ìránṣẹ́ rẹ sì pọ̀ gan-an.”  Wọ́n ń bá ọ̀rọ̀ wọn lọ pé: “Tí a bá rí ojúure rẹ, jẹ́ kí ilẹ̀ yìí di ohun ìní àwa ìránṣẹ́ rẹ. Má ṣe jẹ́ ká sọdá Jọ́dánì.”  Mósè wá dá àwọn ọmọ Gádì àti àwọn ọmọ Rúbẹ́nì lóhùn pé: “Ṣé ẹ̀yin wá fẹ́ máa gbé níbí nígbà tí àwọn arákùnrin yín bá lọ jagun ni?  Kí ló dé tí ẹ fẹ́ kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí wọ́n má bàa sọdá lọ sí ilẹ̀ tó dájú pé Jèhófà máa fún wọn?  Ohun tí àwọn bàbá yín ṣe nìyẹn nígbà tí mo rán wọn láti Kadeṣi-báníà pé kí wọ́n lọ wo ilẹ̀+ náà.  Nígbà tí wọ́n gòkè lọ sí Àfonífojì Éṣíkólì,+ tí wọ́n sì rí ilẹ̀ náà, wọ́n kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí wọ́n má bàa lọ sí ilẹ̀ tí Jèhófà fẹ́ fún wọn.+ 10  Inú bí Jèhófà gidigidi ní ọjọ́ yẹn débi tó fi búra+ pé: 11  ‘Àwọn ọkùnrin tó kúrò ní Íjíbítì, láti ẹni ogún (20) ọdún sókè kò ní rí ilẹ̀  + tí mo búra pé màá fún Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù,+ torí pé wọn ò fi gbogbo ọkàn wọn tọ̀ mí lẹ́yìn, 12  àfi Kélẹ́bù+ ọmọ Jéfúnè ọmọ Kénásì àti Jóṣúà+ ọmọ Núnì, torí pé wọ́n fi gbogbo ọkàn wọn tọ Jèhófà lẹ́yìn.’+ 13  Jèhófà bínú gidigidi sí Ísírẹ́lì, ó sì mú kí wọ́n fi ogójì (40) ọdún+ rìn kiri nínú aginjù, títí gbogbo ìran tó ń hùwà ibi lójú Jèhófà fi pa run.+ 14  Ẹ̀yin ìran ẹlẹ́ṣẹ̀ ti wá rọ́pò àwọn bàbá yín, ẹ̀ ń mú kí ìbínú Jèhófà tó ń jó fòfò túbọ̀ gbóná mọ́ Ísírẹ́lì. 15  Tí ẹ ò bá tẹ̀ lé e mọ́, ó dájú pé ó tún máa fi wọ́n sílẹ̀ nínú aginjù, ẹ sì máa mú kí gbogbo àwọn èèyàn yìí pa run.” 16  Lẹ́yìn náà, wọ́n wá bá a, wọ́n sì sọ fún un pé: “Jẹ́ ká fi òkúta kọ́ ilé síbí fún àwọn ẹran ọ̀sìn wa, ká sì kọ́ ìlú fún àwọn ọmọ wa. 17  Àwa máa dira ogun,+ a ó sì máa lọ níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí a fi máa mú wọn dé àyè wọn, àmọ́ àwọn ọmọ wa á máa gbé inú àwọn ìlú olódi, kí àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà má bàa yọ wọ́n lẹ́nu. 18  A ò ní pa dà sí ilé wa títí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á fi gba ilẹ̀ wọn, tí yóò sì di tiwọn.+ 19  A ò ní bá wọn pín ogún ní òdìkejì Jọ́dánì àti ìkọjá rẹ̀, torí pé a ti gba ogún tiwa ní apá ìlà oòrùn Jọ́dánì.”+ 20  Mósè dá wọn lóhùn pé: “Tí ẹ bá lè ṣe èyí: Kí ẹ gbé ohun ìjà yín níwájú Jèhófà láti jagun+ náà; 21  tí gbogbo yín bá sì gbé ohun ìjà, tí ẹ sọdá Jọ́dánì níwájú Jèhófà nígbà tó ń lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ kúrò níwájú rẹ̀,+ 22  títí a fi máa gba ilẹ̀ náà níwájú Jèhófà,+ nígbà náà, ẹ lè pa dà,+ ẹ ò sì ní jẹ̀bi lọ́dọ̀ Jèhófà àti Ísírẹ́lì. Ilẹ̀ yìí á wá di tiyín níwájú Jèhófà.+ 23  Àmọ́ bí ẹ kò bá ṣe èyí, a jẹ́ pé ẹ máa ṣẹ Jèhófà. Tó bá sì wá rí bẹ́ẹ̀, ẹ ò ní lọ láìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín. 24  Torí náà, ẹ lè kọ́ àwọn ìlú fún àwọn ọmọ yín àti ilé fún àwọn ẹran ọ̀sìn+ yín, àmọ́ ẹ gbọ́dọ̀ mú ìlérí yín ṣẹ.” 25  Àwọn ọmọ Gádì àti àwọn ọmọ Rúbẹ́nì wá dá Mósè lóhùn pé: “Ohun tí olúwa mi pa láṣẹ ni àwa ìránṣẹ́ rẹ máa ṣe gẹ́lẹ́. 26  Àwọn ọmọ wa, àwọn ìyàwó wa, àwọn àgbo ẹran wa àti gbogbo ẹran ọ̀sìn wa máa wà ní àwọn ìlú Gílíádì,+ 27  àmọ́ àwa ìránṣẹ́ rẹ máa sọdá, gbogbo ọkùnrin tó dira ogun láti lọ jagun níwájú Jèhófà,+ bí olúwa mi ṣe sọ.” 28  Mósè wá pàṣẹ fún àlùfáà Élíásárì nípa wọn, fún Jóṣúà ọmọ Núnì àti àwọn olórí agbo ilé bàbá wọn nínú ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 29  Mósè sọ fún wọn pé: “Tí àwọn ọmọ Gádì àti àwọn ọmọ Rúbẹ́nì bá bá yín sọdá Jọ́dánì, tí gbogbo ọkùnrin sì dira ogun níwájú Jèhófà, tí ẹ sì ṣẹ́gun ilẹ̀ náà, kí ẹ wá fún wọn ní ilẹ̀ Gílíádì kó lè di tiwọn.+ 30  Àmọ́ tí wọn ò bá gbé ohun ìjà, tí wọn ò sì bá yín sọdá, a jẹ́ pé wọ́n á máa gbé láàárín yín ní ilẹ̀ Kénáánì.” 31  Àwọn ọmọ Gádì àti àwọn ọmọ Rúbẹ́nì fèsì pé: “Ohun tí Jèhófà sọ fún àwa ìránṣẹ́ rẹ la máa ṣe. 32  A máa gbé ohun ìjà, a ó sì sọdá sí ilẹ̀ Kénáánì+ níwájú Jèhófà, àmọ́ apá ibi tá a wà ní Jọ́dánì yìí ni ogún wa máa wà.” 33  Mósè fún àwọn ọmọ Gádì, àwọn ọmọ Rúbẹ́nì+ àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè+ ọmọ Jósẹ́fù ní ilẹ̀ tí Síhónì+ ọba àwọn Ámórì ti ń jọba àti ilẹ̀ ti Ógù+ ọba Báṣánì ti ń jọba, ilẹ̀ tó wà láwọn ìlú rẹ̀ ní àwọn agbègbè yẹn àti àwọn ìlú tó yí ilẹ̀ náà ká. 34  Àwọn ọmọ Gádì kọ́* Díbónì,+ Átárótì,+ Áróérì,+ 35  Atiroti-ṣófánì, Jásérì,+ Jógíbéhà,+ 36  Bẹti-nímírà+ àti Bẹti-háránì,+ àwọn ìlú olódi, wọ́n sì fi òkúta kọ́ ilé fún àwọn agbo ẹran. 37  Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì kọ́ Hẹ́ṣíbónì,+ Éléálè,+ Kíríátáímù,+ 38  Nébò+ àti Baali-méónì,+ wọ́n yí orúkọ àwọn ìlú náà pa dà, wọ́n kọ́ Síbúmà; wọ́n sì sọ àwọn ìlú tí wọ́n tún kọ́ ní orúkọ míì. 39  Àwọn ọmọ Mákírù+ ọmọ Mánásè lọ sí Gílíádì láti gbógun jà á, wọ́n gbà á, wọ́n sì lé àwọn Ámórì tó wà níbẹ̀ kúrò. 40  Torí náà, Mósè fún Mákírù ọmọ Mánásè ní Gílíádì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ibẹ̀.+ 41  Jáírì ọmọ Mánásè lọ síbẹ̀ láti gbógun jà wọ́n, ó sì gba àwọn abúlé tí wọ́n pàgọ́ sí, ó wá pè wọ́n ní Hafotu-jáírì.*+ 42  Nóbà lọ gbógun ja Kénátì, ó sì gbà á, tòun ti àwọn àrọko rẹ̀,* ó wá ń fi Nóbà orúkọ ara rẹ̀ pè é.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ṣàtúnkọ́.”
Ó túmọ̀ sí “Abúlé Jáírì Tí Wọ́n Pàgọ́ Sí.”
Tàbí “ìlú tó yí i ká.”