Nọ́ńbà 23:1-30
23 Báláámù wá sọ fún Bálákì pé: “Mọ pẹpẹ+ méje sí ibí yìí, kí o sì ṣètò akọ màlúù méje àti àgbò méje sílẹ̀ fún mi.”
2 Ojú ẹsẹ̀ ni Bálákì ṣe ohun tí Báláámù sọ gẹ́lẹ́. Bálákì àti Báláámù sì fi akọ màlúù kan àti àgbò kan rúbọ lórí pẹpẹ+ kọ̀ọ̀kan.
3 Báláámù wá sọ fún Bálákì pé: “Dúró síbí, nídìí ẹbọ sísun rẹ, èmi á sì lọ. Bóyá Jèhófà máa kàn sí mi. Màá jẹ́ kí o mọ ohunkóhun tó bá fi hàn mí.” Ó wá lọ sórí òkè kan tí ohunkóhun kò hù níbẹ̀.
4 Ọlọ́run kàn sí Báláámù,+ ó sì sọ fún Ọlọ́run pé: “Mo ti to pẹpẹ méje, mo sì ti fi akọ màlúù kan àti àgbò kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.”
5 Jèhófà fi ọ̀rọ̀ yìí sí Báláámù+ lẹ́nu pé: “Pa dà sọ́dọ̀ Bálákì, ohun tí wàá sì sọ fún un nìyí.”
6 Ó wá pa dà, ó sì rí i pé Bálákì àti gbogbo ìjòyè Móábù dúró sí ẹ̀gbẹ́ ẹbọ sísun rẹ̀.
7 Ó wá sọ̀rọ̀ lówelówe pé:+
“Bálákì ọba Móábù mú mi wá láti Árámù,+Láti àwọn òkè ìlà oòrùn:
‘Wá bá mi gégùn-ún fún Jékọ́bù.
Àní, wá dá Ísírẹ́lì lẹ́bi.’+
8 Ṣé kí n wá lọ gégùn-ún fún àwọn tí Ọlọ́run ò fi gégùn-ún ni?
Àbí kí n lọ dẹ́bi fún àwọn tí Jèhófà kò dá lẹ́bi?+
9 Mo rí wọn látorí àwọn àpáta,Mo sì rí wọn látorí àwọn òkè.
Ibẹ̀ ni wọ́n pàgọ́ sí láwọn nìkan+ bí àwùjọ;Wọn ò ka ara wọn mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè.+
10 Ta ló lè ka àwọn ọmọ Jékọ́bù+ tí wọ́n pọ̀ bí iyanrìn,Ta ló tiẹ̀ lè ka ìdá mẹ́rin Ísírẹ́lì?
Jẹ́ kí n* kú ikú olódodo,Sì jẹ́ kí ìgbẹ̀yìn mi rí bíi tiwọn.”
11 Bálákì wá sọ fún Báláámù pé: “Kí lo ṣe sí mi yìí? Mo mú ọ wá kí o lè gégùn-ún fún àwọn ọ̀tá mi, àmọ́ ṣe lo kàn wá ń súre fún wọn.”+
12 Ó dá a lóhùn pé: “Ṣé kí n má sọ ohun tí Jèhófà bá fi sí mi lẹ́nu+ ni?”
13 Bálákì sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, jẹ́ ká lọ sí ibòmíì tí o ti lè rí wọn. Díẹ̀ nínú wọn ni wàá rí; o ò ní rí gbogbo wọn. Bá mi gégùn-ún fún wọn láti ibẹ̀.”+
14 Torí náà, ó mú un lọ sí pápá Sófímù, ní orí Písígà,+ ó mọ pẹpẹ méje, ó sì fi akọ màlúù kan àti àgbò kan rúbọ lórí pẹpẹ+ kọ̀ọ̀kan.
15 Báláámù wá sọ fún Bálákì pé: “Dúró síbí, nídìí ẹbọ sísun rẹ, sì jẹ́ kí n kàn sí I níbẹ̀ yẹn.”
16 Jèhófà wá kàn sí Báláámù, ó sì fi ọ̀rọ̀ yìí sí i lẹ́nu+ pé: “Pa dà sọ́dọ̀ Bálákì, ohun tí wàá sì sọ nìyí.”
17 Torí náà, ó wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì rí i pé ó dúró ní ẹ̀gbẹ́ ẹbọ sísun rẹ̀, àwọn ìjòyè Móábù sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Bálákì bi í pé: “Kí ni Jèhófà sọ?”
18 Ó wá sọ̀rọ̀ lówelówe pé:+
“Dìde Bálákì, kí o sì fetí sílẹ̀.
Tẹ́tí sí mi, ìwọ ọmọ Sípórì.
19 Ọlọ́run kì í ṣe èèyàn lásánlàsàn tó máa ń parọ́,+Tàbí ọmọ èèyàn tó máa ń yí èrò pa dà.*+
Tó bá sọ ohun kan, ṣé kò ní ṣe é?
Tó bá sì sọ̀rọ̀, ǹjẹ́ kò ní mú un ṣẹ?+
20 Wò ó! A ti mú mi wá súre;Ní báyìí, Ó ti súre,+ mi ò sì lè yí i pa dà.+
21 Kò fàyè gba agbára òkùnkùn èyíkéyìí láti bá Jékọ́bù jà,Kò sì gbà kí wàhálà kankan dé bá Ísírẹ́lì.
Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú wọn,+Wọ́n sì ń pòkìkí rẹ̀ bí ọba láàárín wọn.
22 Ọlọ́run ń mú wọn kúrò ní Íjíbítì.+
Ó dà bí ìwo akọ màlúù igbó fún wọn.+
23 Torí kò sí ẹni tó lè ríran ìparun sí Jékọ́bù,+Bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò lè woṣẹ́ ibi sí Ísírẹ́lì.+
Ní àkókò yìí, wọ́n á máa sọ nípa Jékọ́bù àti Ísírẹ́lì pé:
‘Ẹ wo ohun tí Ọlọ́run ṣe!’
24 Àwọn èèyàn yìí yóò dìde bíi kìnnìún,Bíi kìnnìún ni yóò gbé ara rẹ̀ sókè.+
Kò ní dùbúlẹ̀ títí yóò fi jẹ ẹran tó bá múTó sì máa mu ẹ̀jẹ̀ àwọn tó bá pa.”
25 Bálákì wá sọ fún Báláámù pé: “Tó ò bá ti lè gégùn-ún kankan fún un, kò tún yẹ kí o máa súre fún un.”
26 Báláámù fèsì pé: “Ṣebí mo ti sọ fún ọ pé, ‘Gbogbo ohun tí Jèhófà bá sọ ni màá ṣe’?”+
27 Bálákì sọ fún Báláámù pé: “Jọ̀ọ́ tẹ̀ lé mi, jẹ́ kí n tún mú ọ lọ sí ibòmíì. Bóyá Ọlọ́run tòótọ́ máa gbà pé kí o bá mi gégùn-ún fún un láti ibẹ̀.”+
28 Bálákì wá mú Báláámù lọ sí orí òkè Péórì, tó dojú kọ Jéṣímónì.*+
29 Báláámù wá sọ fún Bálákì pé: “Mọ pẹpẹ méje sí ibí yìí, kí o sì pèsè akọ màlúù méje àti àgbò méje sílẹ̀ fún mi.”+
30 Bálákì wá ṣe ohun tí Báláámù sọ gẹ́lẹ́, ó sì fi akọ màlúù kan àti àgbò kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.