Míkà 7:1-20

  • Ìwàkiwà Ísírẹ́lì (1-6)

    • “Ará ilé ẹni ni ọ̀tá ẹni” (6)

  • “Màá dúró de Ọlọ́run” (7)

  • Ọlọ́run dá àwọn èèyàn rẹ̀ láre (8-13)

  • Míkà gbàdúrà, ó sì yin Ọlọ́run (14-20)

    • Jèhófà dáhùn (15-17)

    • ‘Ta ló dà bíi Jèhófà?’ (18)

7  Ó mà ṣe fún mi o! Mo dà bí ẹni tí Kò rí àwọn èso àjàrà jẹ,Tí kò sì rí àkọ́so ọ̀pọ̀tọ́ tó wù ú* jẹ,Lẹ́yìn tí wọ́n kó èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn jọ,Tí wọ́n sì ti pèéṣẹ́* lẹ́yìn ìkórè èso àjàrà.   Adúrótini ti tán* ní ayé;Kò sí olódodo kankan láàárín àwọn èèyàn.+ Gbogbo wọn lúgọ kí wọ́n lè ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.+ Kálukú wọn ń fi àwọ̀n dọdẹ arákùnrin rẹ̀.   Wọ́n mọ iṣẹ́ ibi ṣe dáadáa;+Olórí ń béèrè nǹkan lọ́wọ́ àwọn èèyàn,Adájọ́ ń béèrè àbẹ̀tẹ́lẹ̀,+Gbajúmọ̀ ń sọ ohun tó fẹ́,*+Wọ́n sì jọ gbìmọ̀ pọ̀.*   Ẹni tó dáa jù nínú wọn dà bí ẹ̀gún,Ẹni tó jẹ́ olóòótọ́ jù láàárín wọn burú ju ọgbà ẹlẹ́gùn-ún lọ. Ọjọ́ tí àwọn olùṣọ́ rẹ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ àti ọjọ́ ìyà rẹ yóò dé.+ Ẹ̀rù yóò sì bà wọ́n.+   Má ṣe gbára lé ẹnì kejì rẹ,Má sì gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́.+ Máa ṣọ́ ohun tí wàá sọ fún ẹni tó ń sùn sí àyà rẹ.   Torí ọmọkùnrin ń tàbùkù sí bàbá rẹ̀,Ọmọbìnrin ń bá ìyá rẹ̀ jà,+Ìyàwó ń gbógun ti ìyá ọkọ rẹ̀;+Ará ilé ẹni ni ọ̀tá ẹni.+   Àmọ́ ní tèmi, èmi yóò máa retí Jèhófà.+ Màá dúró* de Ọlọ́run ìgbàlà mi.+ Ọlọ́run mi yóò gbọ́ mi.+   Má yọ̀ mí, ìwọ ọ̀tá mi.* Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti ṣubú, màá dìde;Bí mo tiẹ̀ wà nínú òkùnkùn, Jèhófà yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ mi.   Èmi yóò fara da ìbínú Jèhófà,Títí yóò fi gbèjà mi tí yóò sì dá mi láre,Torí mo ti ṣẹ̀ ẹ́.+ Yóò mú mi wá sínú ìmọ́lẹ̀;Èmi yóò rí òdodo rẹ̀. 10  Ọ̀tá mi pẹ̀lú yóò rí i,Ojú yóò sì ti ẹni tó ń sọ fún mi pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ dà?”+ Ojú mi yóò rí i. Wọn yóò tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ lójú ọ̀nà. 11  Ọjọ́ yẹn ni wọ́n máa mọ ògiri olókùúta rẹ;Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n máa sún ààlà síwájú.* 12  Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n máa wá sọ́dọ̀ rẹ Láti Ásíríà lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún àti láti àwọn ìlú Íjíbítì,Láti Íjíbítì títí lọ dé Odò;*Láti òkun dé òkun àti láti òkè dé òkè.+ 13  Ilẹ̀ náà yóò sì di ahoro torí àwọn tó ń gbé ibẹ̀,Nítorí ohun tí wọ́n ṣe.* 14  Fi ọ̀pá rẹ ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn èèyàn rẹ, agbo ẹran tó jẹ́ ogún rẹ,+Tó ń dá gbé inú igbó, láàárín ọgbà eléso. Jẹ́ kí Báṣánì àti Gílíádì+ fún wọn ní oúnjẹ bíi ti àtijọ́. 15  “Màá fi àwọn ohun àgbàyanu hàn án,+Bíi ti ìgbà tí ẹ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì. 16  Àwọn orílẹ̀-èdè yóò rí i, ojú sì máa tì wọ́n bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lágbára.+ Wọ́n á fi ọwọ́ bo ẹnu;Etí wọn á di. 17  Wọ́n á lá erùpẹ̀ bí ejò;+Wọ́n á máa gbọ̀n rìrì bí wọ́n ṣe ń jáde látinú ibi ààbò wọn bí àwọn ẹran tó ń fàyà fà. Wọ́n á wá sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wa pẹ̀lú ìbẹ̀rù,Ẹ̀rù rẹ yóò sì bà wọ́n.”+ 18  Ta ló dà bí rẹ, Ọlọ́run,Tó ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini, tó sì ń gbójú fo ìṣìnà+ àwọn tó ṣẹ́ kù nínú ogún rẹ̀?+ Kò ní máa bínú lọ títí láé,Torí inú rẹ̀ máa ń dùn sí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.+ 19  Ó tún máa ṣàánú wa;+ ó sì máa pa àwọn àṣìṣe wa rẹ́.* O máa ju gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn sí ìsàlẹ̀ òkun.+ 20  O máa jẹ́ olóòótọ́ sí Jékọ́bù,Ìfẹ́ tí o ní sí Ábúráhámù kò ní yẹ̀,Bí o ṣe búra fún àwọn baba ńlá wa láti ìgbà àtijọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “wu ọkàn rẹ̀.”
Ó túmọ̀ sí ṣíṣà lára irè oko tí wọ́n bá fi sílẹ̀.
Tàbí “ṣègbé.”
Tàbí “ohun tó wù ú lọ́kàn.”
Ní Héb., “Wọ́n sì jọ hun ún pọ̀.”
Tàbí “Màá fi sùúrù dúró.”
Lédè Hébérù, abo ni wọ́n ń lo ọ̀rọ̀ tí a tú sí “ọ̀tá” fún.
Tàbí kó jẹ́, “àṣẹ náà yóò jìnnà réré.”
Ìyẹn, odò Yúfírétì.
Ní Héb., “Torí èrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn.”
Tàbí “tẹ àwọn àṣìṣe wa mọ́lẹ̀; tẹ àwọn àṣìṣe wa lórí ba.”