Léfítíkù 6:1-30

  • Àwọn ohun míì nípa ẹbọ ẹ̀bi (1-7)

  • Ìtọ́ni nípa àwọn ọrẹ (8-30)

    • Ẹbọ sísun (8-13)

    • Ọrẹ ọkà (14-23)

    • Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ (24-30)

6  Jèhófà wá sọ fún Mósè pé:  “Tí ẹnì* kan bá ṣẹ̀, tó hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà+ torí pé ó tan ọmọnìkejì rẹ̀ jẹ nípa ohun kan tó fi sí ìkáwọ́ rẹ̀ tàbí ohun kan tó fi pa mọ́ sọ́wọ́ rẹ̀+ tàbí tó ja ọmọnìkejì rẹ̀ lólè tàbí tó lù ú ní jìbìtì,  tàbí tó rí ohun tó sọ nù, tó sì sẹ́ pé òun ò rí i, tó wá búra èké lórí èyíkéyìí nínú ẹ̀ṣẹ̀ tó dá,+ ohun tó máa ṣe nìyí:  Tó bá ti ṣẹ̀, tó sì jẹ̀bi, kó dá ohun tó jí pa dà àti ohun tó fipá gbà, ohun tó fi jìbìtì gbà, ohun tí wọ́n fi sí ìkáwọ́ rẹ̀ tàbí ohun tó sọ nù tí ó rí,  tàbí ohunkóhun tó búra èké lé lórí, kó sì san gbogbo rẹ̀ pa dà,+ kó tún fi ìdá márùn-ún rẹ̀ kún un. Kó fún ẹni tó ni ín lọ́jọ́ tí wọ́n bá fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó jẹ̀bi.  Kó sì mú àgbò tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá wá fún àlùfáà láti fi rú ẹbọ ẹ̀bi fún Jèhófà, kí àgbò náà tó iye tí wọ́n dá lé e, láti fi rú ẹbọ ẹ̀bi.+  Kí àlùfáà ṣe ètùtù fún un níwájú Jèhófà, yóò sì rí ìdáríjì fún ohunkóhun tó ṣe tó mú kó jẹ̀bi.”+  Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé:  “Pàṣẹ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, ‘Òfin ẹbọ sísun+ nìyí: Kí ẹbọ sísun wà nínú ààrò lórí pẹpẹ ní gbogbo òru mọ́jú, kí iná sì máa jó lórí pẹpẹ náà. 10  Kí àlùfáà wọ ẹ̀wù oyè rẹ̀ tí wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀*+ ṣe, kó sì wọ ṣòkòtò péńpé*+ láti bo ara rẹ̀. Kó wá kó eérú*+ ẹbọ sísun tí wọ́n ti fi iná jó lórí pẹpẹ kúrò, kó sì kó o sẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ. 11  Lẹ́yìn náà, kó bọ́ aṣọ rẹ̀,+ kó wọ aṣọ míì, kó sì kó eérú náà lọ síbì kan tó mọ́ lẹ́yìn ibùdó.+ 12  Kí iná máa jó lórí pẹpẹ. Kò gbọ́dọ̀ kú. Kí àlùfáà máa dáná igi  + lórí rẹ̀ láràárọ̀, kó to ẹbọ sísun sórí rẹ̀, kó sì mú kí ọ̀rá ẹbọ ìrẹ́pọ̀ rú èéfín lórí rẹ̀.+ 13  Iná gbọ́dọ̀ máa jó lórí pẹpẹ náà nígbà gbogbo. Kò gbọ́dọ̀ kú. 14  “‘Òfin ọrẹ ọkà+ nìyí: Kí ẹ̀yin ọmọ Áárónì mú un wá síwájú Jèhófà, ní iwájú pẹpẹ. 15  Kí ọ̀kan lára wọn bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun tó kúnná nínú ọrẹ ọkà àti díẹ̀ lára òróró rẹ̀ àti gbogbo oje igi tùràrí tó wà lórí ọrẹ ọkà, kó sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ láti mú òórùn dídùn* jáde sí Jèhófà, kó fi ṣe ọrẹ ìṣàpẹẹrẹ.*+ 16  Kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ ohun tó bá ṣẹ́ kù lára rẹ̀.+ Kí wọ́n fi ṣe búrẹ́dì aláìwú, kí wọ́n jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́. Kí wọ́n jẹ ẹ́ ní àgbàlá àgọ́ ìpàdé.+ 17  Wọn ò gbọ́dọ̀ fi ohunkóhun tó ní ìwúkàrà+ sí i. Mo ti fi ṣe ìpín tiwọn látinú àwọn ọrẹ àfinásun+ mi. Ohun mímọ́ jù lọ+ ni, bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ ẹ̀bi. 18  Gbogbo ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Áárónì ni yóò jẹ+ ẹ́. Yóò jẹ́ ìpín wọn títí lọ látinú àwọn ọrẹ àfinásun+ sí Jèhófà, jálẹ̀ àwọn ìran wọn. Gbogbo ohun tó bá fara kàn wọ́n* yóò di mímọ́.’” 19  Jèhófà tún sọ fún Mósè pé: 20  “Èyí ni ọrẹ tí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò mú wá fún Jèhófà ní ọjọ́ tí ẹ bá fòróró yàn wọ́n:+ ìyẹ̀fun tó kúnná tó jẹ́ ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà,*+ kí wọ́n máa fi ṣe ọrẹ ọkà+ nígbà gbogbo, ààbọ̀ rẹ̀ ní àárọ̀, ààbọ̀ rẹ̀ ní alẹ́. 21  Kí o fi òróró yan án lórí agbada.+ Kí o pò ó mọ́ òróró dáadáa, yan ọrẹ ọkà náà, kí o sì mú un wá ní kéékèèké fún Jèhófà bí ọrẹ tó ní òórùn dídùn.* 22  Àlùfáà tí ẹ fòróró yàn dípò rẹ̀ látinú àwọn ọmọ rẹ̀+ ni kó ṣe é. Ìlànà tó máa wà títí lọ ni: Kó jẹ́ odindi ọrẹ tó máa mú kó rú èéfín sí Jèhófà. 23  Kí gbogbo ọrẹ ọkà àlùfáà jẹ́ odindi ọrẹ. Wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́.” 24  Jèhófà tún sọ fún Mósè pé: 25  “Sọ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, ‘Òfin ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ nìyí: Ibi tí wọ́n ti ń pa ẹran ẹbọ sísun+ ni kí wọ́n ti pa ẹran ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ níwájú Jèhófà. Ohun mímọ́ jù lọ ni. 26  Àlùfáà tó fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ló máa jẹ ẹ́.+ Ibi mímọ́ ni kó ti jẹ ẹ́, nínú àgbàlá àgọ́ ìpàdé.+ 27  “‘Gbogbo ohun tó bá fara kan ẹran rẹ̀ yóò di mímọ́, tí ẹnikẹ́ni bá sì wọ́n lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí aṣọ rẹ̀, kí o fọ aṣọ tí ẹni náà wọ́n ẹ̀jẹ̀ sí ní ibi mímọ́. 28  Kí wọ́n fọ́ ìkòkò amọ̀ tí wọ́n fi sè é túútúú. Àmọ́ tó bá jẹ́ ìkòkò bàbà ni wọ́n fi sè é, kí wọ́n ha á, kí wọ́n sì fi omi fọ̀ ọ́. 29  “‘Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ àlùfáà ni kó jẹ ẹ́.+ Ohun mímọ́ jù lọ+ ni. 30  Àmọ́, ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sínú àgọ́ ìpàdé láti ṣe ètùtù ní ibi mímọ́.+ Ṣe ni kí ẹ fi iná sun ún.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “eérú ọlọ́ràá,” ìyẹn, eérú tí ọ̀rá tí wọ́n fi rúbọ ti rin.
Tàbí “àwọ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí “ohun ìrántí (ìṣàpẹẹrẹ) látinú rẹ̀.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Tàbí “àwọn ọrẹ náà.”
Ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà kan jẹ́ Lítà 2.2. Wo Àfikún B14.
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”