Léfítíkù 16:1-34

  • Ọjọ́ Ètùtù (1-34)

16  Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Áárónì méjì kú torí wọ́n lọ síwájú Jèhófà.+  Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Sọ fún Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ pé kó má kàn wá sínú ibi mímọ́+ tó wà lẹ́yìn aṣọ ìdábùú+ nígbàkigbà, níwájú ìbòrí Àpótí, kó má bàa kú,+ torí màá fara hàn nínú ìkùukùu*+ lórí ìbòrí+ náà.  “Ohun tí Áárónì máa mú wá tó bá ń bọ̀ wá sínú ibi mímọ́ nìyí: ọmọ akọ màlúù láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ àti àgbò láti fi rú ẹbọ sísun.+  Kó wọ ẹ̀wù mímọ́ tí wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀*+ ṣe, kó sì wọ ṣòkòtò péńpé*+ tí wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe láti bo ara* rẹ̀, kó de ọ̀já+ tí wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe mọ́ra, kó sì wé láwàní+ tí wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe sórí. Aṣọ mímọ́+ ni wọ́n. Kó fi omi wẹ̀,+ kó sì wọ àwọn aṣọ náà.  “Kó mú òbúkọ méjì tó ṣì kéré látinú àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kó sì fi àgbò kan rú ẹbọ sísun.  “Kí Áárónì mú akọ màlúù ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá, èyí tó jẹ́ tirẹ̀, kó sì ṣe ètùtù torí ara rẹ̀+ àti ilé rẹ̀.  “Kó mú ewúrẹ́ méjèèjì, kó sì mú kí wọ́n dúró síwájú Jèhófà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.  Kí Áárónì ṣẹ́ kèké lórí ewúrẹ́ méjèèjì, kèké kan fún Jèhófà, kèké kejì fún Ásásélì.*  Ewúrẹ́ tí kèké+ mú fún Jèhófà ni kí Áárónì mú wá, kó sì fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. 10  Àmọ́ kó mú ewúrẹ́ tí kèké mú fún Ásásélì wá láàyè láti dúró níwájú Jèhófà kó lè ṣe ètùtù lórí rẹ̀, kó sì rán an lọ sínú aginjù+ fún Ásásélì. 11  “Kí Áárónì mú akọ màlúù ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá, èyí tó jẹ́ tirẹ̀, kó sì ṣe ètùtù torí ara rẹ̀ àti ilé rẹ̀; lẹ́yìn náà, kó pa akọ màlúù ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, tó jẹ́ tirẹ̀.+ 12  “Kó wá mú ìkóná+ tí ẹyin iná tó ń jó látorí pẹpẹ+ níwájú Jèhófà kún inú rẹ̀, pẹ̀lú ẹ̀kúnwọ́ tùràrí onílọ́fínńdà+ méjì tó dáa, kó sì kó wọn wá sẹ́yìn aṣọ ìdábùú.+ 13  Kó tún fi tùràrí sínú iná níwájú Jèhófà,+ èéfín tùràrí yóò sì bo ìbòrí Àpótí+ náà, èyí tó wà lórí Ẹ̀rí,+ kó má bàa kú. 14  “Kó mú lára ẹ̀jẹ̀+ akọ màlúù náà, kó fi ìka rẹ̀ wọ́n ọn síwájú ìbòrí náà ní apá ìlà oòrùn, kó sì fi ìka rẹ̀ wọ́n lára ẹ̀jẹ̀ náà lẹ́ẹ̀méje síwájú ìbòrí+ náà. 15  “Kó wá pa ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, tó jẹ́ ti àwọn èèyàn,+ kó mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sẹ́yìn aṣọ ìdábùú,+ kó sì fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe ohun kan náà tó fi ẹ̀jẹ̀+ akọ màlúù náà ṣe; kó wọ́n ọn sí apá ibi tí ìbòrí náà wà, níwájú ìbòrí náà. 16  “Kó ṣe ètùtù fún ibi mímọ́ torí ìwà àìmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àṣìṣe wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn,+ bẹ́ẹ̀ náà ni kó ṣe fún àgọ́ ìpàdé, èyí tó wà láàárín wọn, láàárín àwọn tó ń hùwà àìmọ́. 17  “Ẹnì kankan ò gbọ́dọ̀ sí nínú àgọ́ ìpàdé látìgbà tó bá ti wọlé lọ ṣe ètùtù ní ibi mímọ́ títí yóò fi jáde. Kó ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti ilé rẹ̀+ àti gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì.+ 18  “Kó wá jáde wá síbi pẹpẹ+ tó wà níwájú Jèhófà, kó ṣe ètùtù fún un, kó sì mú lára ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà àti lára ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ náà, kó wá fi sára àwọn ìwo tó wà ní gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. 19  Kó tún fi ìka rẹ̀ wọ́n lára ẹ̀jẹ̀ náà sára pẹpẹ lẹ́ẹ̀méje, kó lè wẹ̀ ẹ́ mọ́, kó sì sọ ọ́ di mímọ́ kúrò nínú ìwà àìmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 20  “Tó bá ti ṣe ètùtù+ fún ibi mímọ́ náà tán, pẹ̀lú àgọ́ ìpàdé àti pẹpẹ,+ kó tún mú ààyè ewúrẹ́+ náà wá. 21  Kí Áárónì gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé orí ààyè ewúrẹ́ náà, kó jẹ́wọ́ gbogbo àṣìṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti gbogbo ìṣìnà wọn àti gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn sórí rẹ̀, kí ó kó o lé orí ewúrẹ́+ náà, kó wá yan ẹnì kan* tó máa rán ewúrẹ́ náà lọ sínú aginjù. 22  Kí ewúrẹ́ náà fi orí rẹ̀ ru gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn+ lọ sí aṣálẹ̀,+ kó sì rán ewúrẹ́ náà lọ sínú aginjù.+ 23  “Kí Áárónì wá wọnú àgọ́ ìpàdé, kó bọ́ ẹ̀wù tí wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe, èyí tó wọ̀ nígbà tó lọ sínú ibi mímọ́, kó sì kó wọn sílẹ̀ níbẹ̀. 24  Kó fi omi wẹ+ ara rẹ̀* ní ibi mímọ́, kó sì wọ aṣọ rẹ̀;+ kó wá jáde, kó sì rú ẹbọ sísun+ rẹ̀ àti ẹbọ sísun+ àwọn èèyàn náà, kó ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti fún àwọn èèyàn náà.+ 25  Kó mú kí ọ̀rá ẹran tó fi rúbọ ẹ̀ṣẹ̀ rú èéfín lórí pẹpẹ. 26  “Kí ẹni tó rán ewúrẹ́ náà lọ fún Ásásélì+ fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, lẹ́yìn náà ó lè wá sínú ibùdó. 27  “Ní ti akọ màlúù ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, tó mú ẹ̀jẹ̀ wọn wá sínú ibi mímọ́ láti fi ṣe ètùtù, kí ó kó wọn lọ sí ẹ̀yìn ibùdó, kó fi iná sun+ awọ wọn, ẹran wọn àti ìgbẹ́ wọn. 28  Kí ẹni tó fi iná sun ún fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, lẹ́yìn náà ó lè wá sínú ibùdó. 29  “Àṣẹ tó máa wà fún yín títí lọ ni: Ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù keje, kí ẹ pọ́n ara yín* lójú, ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan,+ ì báà jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ tàbí àjèjì tó ń gbé láàárín yín. 30  Ọjọ́ yìí ni wọ́n á ṣe ètùtù+ fún yín láti kéde pé ẹ jẹ́ mímọ́. Ẹ máa di mímọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín níwájú Jèhófà.+ 31  Yóò jẹ́ sábáàtì fún yín, ọjọ́ ìsinmi tí ẹ ò ní ṣiṣẹ́ rárá, kí ẹ sì pọ́n ara yín* lójú.+ Àṣẹ tó máa wà títí lọ ni. 32  “Kí àlùfáà tí ẹ fòróró yàn,+ tí ẹ fiṣẹ́ lé lọ́wọ́* láti ṣe àlùfáà+ dípò bàbá rẹ̀+ ṣe ètùtù, kó sì wọ aṣọ ọ̀gbọ̀,+ aṣọ mímọ́.+ 33  Kó ṣe ètùtù fún ibi mímọ́,+ àgọ́ ìpàdé+ àti pẹpẹ;+ kó sì ṣe ètùtù fún àwọn àlùfáà àti gbogbo ìjọ+ náà. 34  Èyí máa jẹ́ àṣẹ tí ẹ ó máa pa mọ́ títí lọ,+ láti ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́ẹ̀kan lọ́dún+ torí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” Torí náà, ó ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè gẹ́lẹ́.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “àwọsánmà.”
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “àwọ̀tẹ́lẹ̀.”
Tàbí “ìhòòhò.”
Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Ewúrẹ́ Tó Lọ.”
Tàbí “kó mú kí ẹnì kan wà ní sẹpẹ́.”
Ní Héb., “ẹran ara rẹ̀.”
Tàbí “ọkàn yín.” Kí èèyàn “pọ́n ara rẹ̀ lójú” sábà máa ń túmọ̀ sí kí èèyàn fi oríṣiríṣi nǹkan du ara rẹ̀, irú bíi kó gbààwẹ̀.
Tàbí “ọkàn yín.”
Ní Héb., “tí ẹ ó fi kún ọwọ́ rẹ̀.”