Jeremáyà 4:1-31
4 “Bí o bá máa pa dà, ìwọ Ísírẹ́lì,” ni Jèhófà wí,“Bí o bá máa pa dà sọ́dọ̀ mi
Kí o mú òrìṣà ẹ̀gbin rẹ kúrò níwájú mi,Nígbà náà, ìwọ kò ní jẹ́ ìsáǹsá.+
2 Bí o bá ń ṣe òtítọ́ àti òdodo pẹ̀lú ẹ̀tọ́, bí o ti ń búra pé,‘Bí Jèhófà ti wà láàyè!’
Nígbà náà, àwọn orílẹ̀-èdè á gba ìbùkún látọ̀dọ̀ rẹ̀,Wọ́n á sì máa ṣògo nínú rẹ̀.”+
3 Ohun tí Jèhófà sọ fún àwọn ọkùnrin Júdà àti fún Jerúsálẹ́mù nìyí:
“Ẹ tú ilẹ̀ tó dáa fún ọ̀gbìn,Ẹ má sì máa fúnrúgbìn sáàárín ẹ̀gún.+
4 Ẹ kọ ara yín nílà* fún Jèhófà,Ẹ sì kọlà fún* ọkàn yín,+Ẹ̀yin èèyàn Júdà àti ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerúsálẹ́mù,Kí ìbínú mi má bàa ru jáde bí ináKí ó sì máa jó, tí kò fi ní sí ẹni tó lè pa á,Nítorí ìwà ibi yín.”+
5 Ẹ kéde rẹ̀ ní Júdà, ẹ sì polongo rẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù.
Ẹ kígbe, kí ẹ sì fun ìwo jákèjádò ilẹ̀ náà.+
Ẹ gbóhùn sókè, kí ẹ sì sọ pé: “Ẹ kóra jọ,Ẹ sì jẹ́ kí a sá wọ àwọn ìlú olódi.+
6 Ẹ gbé àmì kan dúró* tó ń tọ́ka sí Síónì.
Ẹ wá ibi ààbò, ẹ má sì dúró tẹtẹrẹ,”Nítorí mò ń mú àjálù bọ̀ láti àríwá,+ yóò sì jẹ́ ìparun tó bùáyà.
7 Ó yọ jáde láti inú igbó bíi kìnnìún;+Ẹni tó ń pa àwọn orílẹ̀-èdè run ti jáde.+
Ó ti jáde kúrò ní àyè rẹ̀ kí ó lè sọ ilẹ̀ rẹ di ohun àríbẹ̀rù.
Àwọn ìlú rẹ yóò di àwókù tí kò ní sí ẹni tó ń gbé ibẹ̀ mọ́.+
8 Torí náà, ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀,*+Ẹ ṣọ̀fọ̀,* kí ẹ sì pohùn réré ẹkún,Nítorí ìbínú Jèhófà tó ń jó bí iná kò tíì kúrò lórí wa.
9 “Ní ọjọ́ náà, ọkàn ọba á domi,”*+ ni Jèhófà wí“Àti ọkàn àwọn ìjòyè;*Ẹ̀rù á ba àwọn àlùfáà, kàyéfì á sì ṣe àwọn wòlíì.”+
10 Ni mo bá sọ pé: “Áà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! O ti tan àwọn èèyàn yìí+ àti Jerúsálẹ́mù jẹ pátápátá, o sọ pé, ‘Ẹ máa ní àlàáfíà,’+ nígbà tó jẹ́ pé idà ló wà lọ́rùn wa.”*
11 Nígbà yẹn, a ó sọ fún àwọn èèyàn yìí àti Jerúsálẹ́mù pé:
“Ẹ̀fúùfù gbígbóná láti orí àwọn òkè tó wà ní aṣálẹ̀ tí kò sí ohunkóhun tó hù lórí wọnLó máa gbá ọmọbìnrin* àwọn èèyàn mi lọ;Kì í ṣe pé ó máa wá fẹ́ ọkà tàbí pàǹtírí.
12 Èmi ni mo sọ pé kí ẹ̀fúùfù líle fẹ́ wá láti orí àwọn òkè.
Ní báyìí, màá kéde ìdájọ́ lé wọn lórí.
13 Wò ó! Ọ̀tá yóò wá bí òjò tó ṣú,Àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ á sì wá bí ìjì.+
Àwọn ẹṣin rẹ̀ yára ju ẹyẹ idì lọ.+
A gbé, torí pé a ti di ahoro!
14 Wẹ ìwà burúkú kúrò lọ́kàn rẹ, kí o lè rí ìgbàlà, ìwọ Jerúsálẹ́mù.+
Ìgbà wo lo máa tó mú èrò burúkú kúrò lọ́kàn rẹ?
15 Nítorí ohùn kan ròyìn láti Dánì,+Ó sì kéde àjálù láti àwọn òkè Éfúrémù.
16 Ẹ ròyìn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni, ẹ ròyìn rẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè;Ẹ kéde rẹ̀ sórí Jerúsálẹ́mù.”
“Àwọn ẹ̀ṣọ́* ń bọ̀ láti ilẹ̀ tó jìnnà,Wọ́n á sì gbé ohùn wọn sókè sí àwọn ìlú Júdà.
17 Wọ́n yí Jerúsálẹ́mù ká bí ìgbà tí àwọn ẹ̀ṣọ́ bá ń ṣọ́ pápá gbalasa,+Nítorí pé ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi,”+ ni Jèhófà wí.
18 “Ọ̀nà rẹ àti ìṣe rẹ á yí dà lé ọ lórí.+
Wo bí àjálù rẹ á ti korò tó!
Nítorí ó ti dé inú ọkàn rẹ.”
19 Ìrora mi pọ̀,* ìrora mi pọ̀!
Ọkàn mi* gbọgbẹ́.
Àyà mi ń lù kìkì.
Mi ò lè dákẹ́,Nítorí mo* ti gbọ́ ìró ìwo
Àti ìró ogun.*+
20 Àjálù lórí àjálù ni ìròyìn tí à ń gbọ́,Nítorí pé wọ́n ti pa gbogbo ilẹ̀ náà run.
Lójijì, wọ́n pa àgọ́ mi run,Ní ìṣẹ́jú kan, wọ́n pa aṣọ àgọ́ mi run.+
21 Ìgbà wo ni mi ò ní rí àmì* mọ́,Tí mi ò sì ní máa gbọ́ ìró ìwo?+
22 “Nítorí àwọn èèyàn mi gọ̀;+Wọn ò kà mí sí.
Ọmọ tí kò gbọ́n ni wọ́n, wọn ò sì lóye.
Ọ̀jáfáfá* ni wọ́n nínú ìwà ibi,Àmọ́, wọn ò mọ bí a ti ń ṣe rere.”
23 Mo rí ilẹ̀ náà, sì wò ó! ó ṣófo, ó sì dahoro.+
Mo bojú wo ọ̀run, ìmọ́lẹ̀ wọn kò sì sí mọ́.+
24 Mo rí àwọn òkè ńlá, sì wò ó! wọ́n ń mì tìtì,Àwọn òkè kéékèèké sì ń mì.+
25 Mo wò ó, kíyè sí i! kò sí èèyàn kankan níbẹ̀,Gbogbo àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ti fò lọ.+
26 Mo wò ó, kíyè sí i! ọgbà eléso ti di aginjù,Gbogbo àwọn ìlú rẹ̀ ti wó lulẹ̀.+
Nítorí Jèhófà ni,
Torí ìbínú rẹ̀ tó ń jó fòfò ni.
27 Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Gbogbo ilẹ̀ náà á di ahoro,+Àmọ́ mi ò ní pa á run pátápátá.
28 Nítorí èyí, ilẹ̀ náà máa ṣọ̀fọ̀,+Àwọn ọ̀run á sì ṣókùnkùn.+
Torí pé mo ti sọ̀rọ̀, mo sì ti pinnu,Mi ò ní pèrò dà,* bẹ́ẹ̀ sì ni mi ò ní yí pa dà.+
29 Nítorí ìró àwọn agẹṣin àti àwọn tafàtafà,
Gbogbo ìlú sá lọ.+
Wọ́n wọnú igbó,Wọ́n sì gun àwọn àpáta.+
Gbogbo ìlú ni wọ́n ti fi sílẹ̀,Kò sì sí èèyàn kankan tó ń gbé inú wọn.”
30 Ní báyìí tí o ti di ahoro, kí lo máa ṣe?
O ti máa ń wọ aṣọ rírẹ̀dòdò tẹ́lẹ̀,O ti máa ń fi ohun ọ̀ṣọ́ wúrà ṣe ara rẹ lóge,O sì ti máa ń fi tìróò* sọ ojú rẹ di ńlá.
Àmọ́ lásán lo ṣe ara rẹ lóge,+Àwọn tí ìfẹ́ rẹ ti kó sí lórí ti pa ọ́ tì;Ní báyìí wọ́n ń wá bí wọ́n á ṣe gba ẹ̀mí rẹ.*+
31 Nítorí mo gbọ́ ohùn kan tó dà bíi ti obìnrin tó ń ṣàìsàn,Ìdààmú bíi ti obìnrin tó ń rọbí àkọ́bí ọmọ rẹ̀,Ohùn ọmọbìnrin Síónì tó ń mí gúlegúle.
Bó ṣe tẹ́ àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, ó ń sọ pé:+
“Mo gbé, àárẹ̀ ti mú mi* nítorí àwọn apààyàn!”
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “dá ara yín ládọ̀dọ́.”
^ Tàbí “dádọ̀dọ́.”
^ Tàbí “fi òpó ṣe àmì.”
^ Tàbí “Ẹ lu àyà yín.”
^ Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”
^ Tàbí “ọba kì yóò ní ìgboyà.”
^ Tàbí “Àwọn ìjòyè kì yóò ní ìgboyà.”
^ Tàbí “nígbà tí idà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ̀mí wa.”
^ Ọ̀rọ̀ ewì tó ṣeé ṣe kó máa tọ́ka sí àánú tàbí ìgbatẹnirò bíi pé èèyàn ni wọ́n.
^ Ní Héb., “Àwọn olùṣọ́,” ìyẹn, àwọn tó ń ṣọ́ ìlú kan, kí wọ́n lè mọ ìgbà tó yẹ kí wọ́n gbéjà kò ó.
^ Ní Héb., “Ìfun mi.”
^ Ní Héb., “Ògiri ọkàn mi.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”
^ Tàbí kó jẹ́, “ariwo ogun.”
^ Tàbí “òpó tí a fi ṣe àmì.”
^ Tàbí “Ọlọ́gbọ́n.”
^ Tàbí “yí ìpinnu mi pa dà.”
^ Tàbí “lẹ́ẹ̀dì.”
^ Tàbí “wọ́n ń lépa ọkàn rẹ.”
^ Tàbí “ọkàn mi.”