Jeremáyà 14:1-22
14 Ohun tí Jèhófà bá Jeremáyà sọ nípa ọ̀dá* nìyí:+
2 Júdà ń ṣọ̀fọ̀,+ àwọn ẹnubodè rẹ̀ ti dá páropáro.
Wọ́n ti wọlẹ̀ torí pé wọ́n ti pa á tì,Igbe ẹkún Jerúsálẹ́mù ti dé ọ̀run.
3 Àwọn ọ̀gá wọn ń rán àwọn ìránṣẹ́* wọn lọ pọn omi.
Wọ́n dé ìdí àwọn kòtò omi,* àmọ́ wọn ò rí omi kankan.
Òfìfo ìkòkò ni wọ́n gbé pa dà.
Ojú tì wọ́n, ìjákulẹ̀ bá wọn,Wọ́n sì bo orí wọn.
4 Ilẹ̀ náà ti sán,Torí òjò kò rọ̀ sórí rẹ̀,+Ìrẹ̀wẹ̀sì ti bá àwọn àgbẹ̀, wọ́n sì bo orí wọn.
5 Kódà, abo àgbọ̀nrín inú pápá ń pa àwọn ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí tì
Nítorí kò sí koríko.
6 Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó dúró lórí àwọn òkè.
Wọ́n ń mí hẹlẹhẹlẹ bí ajáko;*Ojú wọn ò ríran dáadáa torí pé kò sí ewéko.+
7 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà wa jẹ́rìí sí i pé a ti ṣe àṣìṣe,Jèhófà, ràn wá lọ́wọ́ nítorí orúkọ rẹ.+
Nítorí ìwà àìṣòótọ́ wa pọ̀,+Ìwọ sì ni a dẹ́ṣẹ̀ sí.
8 Ìwọ, ìrètí Ísírẹ́lì, Olùgbàlà rẹ̀+ ní àkókò wàhálà,Kí nìdí tí o fi dà bí àjèjì ní ilẹ̀ náà
Àti bí arìnrìn-àjò tó kàn dúró láti sùn mọ́jú?
9 Kí nìdí tí o fi dà bí ọkùnrin tí nǹkan tojú sú,Bí alágbára ọkùnrin tí kò lè gbani là?
Nítorí o wà láàárín wa, Jèhófà,+Wọ́n sì ń fi orúkọ rẹ pè wá.+
Má fi wá sílẹ̀.
10 Ohun tí Jèhófà sọ nípa àwọn èèyàn yìí rèé: “Wọ́n fẹ́ láti máa rìn kiri,+ wọn ò ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ wọn.+ Nítorí náà, inú Jèhófà ò dùn sí wọn.+ Ní báyìí, á rántí àṣìṣe wọn, á sì pè wọ́n wá jíhìn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”+
11 Jèhófà sì sọ fún mi pé: “Má ṣe gbàdúrà pé kí ire bá àwọn èèyàn yìí.+
12 Tí wọ́n bá gbààwẹ̀, mi ò ní fetí sí ẹ̀bẹ̀ wọn,+ tí wọ́n bá sì fi odindi ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà rúbọ, inú mi ò ní dùn sí wọn,+ nítorí pé idà àti ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn* ni màá fi pa wọ́n.”+
13 Ni mo bá sọ pé: “Áà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Wò ó, àwọn wòlíì ń sọ fún wọn pé, ‘Ẹ kò ní rí idà, ìyàn kò sì ní dé bá yín, ṣùgbọ́n Ọlọ́run á fún yín ní àlàáfíà gidi ní ibí yìí.’”+
14 Jèhófà wá sọ fún mi pé: “Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni àwọn wòlíì náà ń sọ ní orúkọ mi.+ Mi ò rán wọn, bẹ́ẹ̀ ni mi ò pàṣẹ fún wọn, mi ò sì bá wọn sọ̀rọ̀.+ Ìran èké àti ìwoṣẹ́ asán àti ẹ̀tàn ọkàn wọn ni wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀ fún yín.+
15 Nítorí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Ní ti àwọn wòlíì tó ń sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ mi, bó tilẹ̀ jẹ pé mi ò rán wọn, tí wọ́n ń sọ pé idà tàbí ìyàn kò ní wáyé ní ilẹ̀ yìí, idà àti ìyàn ni yóò pa àwọn wòlíì náà.+
16 Àwọn èèyàn tí wọ́n sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún yóò di òkú tí wọ́n á gbé jù sí àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù nítorí ìyàn àti idà. Ẹnì kankan kò sì ní sin wọ́n,+ látorí àwọn fúnra wọn dórí àwọn ìyàwó wọn àti àwọn ọmọkùnrin wọn pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin wọn, torí màá mú àjálù tí ó tọ́ sí wọn bá wọn.’+
17 “Sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn pé,‘Kí omijé ṣàn ní ojú mi tọ̀sántòru, kí ó má sì dá,+Nítorí wọ́n ti lu wúńdíá àwọn èèyàn mi ní àlùbolẹ̀,+Wọ́n sì dá ọgbẹ́ sí i lára yánnayànna.
18 Bí mo bá jáde lọ sínú pápá, tí mo sì wò,Àwọn tí idà pa ni mò ń rí!+
Bí mo bá sì wá sínú ìlú,Àwọn àrùn tí ìyàn fà ni mò ń rí!+
Nítorí wòlíì àti àlùfáà ti lọ káàkiri ní ilẹ̀ tí wọn ò mọ̀.’”+
19 Ṣé o kọ Júdà sílẹ̀ pátápátá ni, àbí o* ti kórìíra Síónì dé góńgó ni?+
Kí nìdí tí o fi lù wá débi tí a ò fi lè rí ìwòsàn?+
À ń retí àlàáfíà, àmọ́ ohun rere kan ò dé,À ń retí àkókò ìwòsàn, àmọ́ ìpayà là ń rí!+
20 Jèhófà, a mọ̀ pé a ti hùwà burúkú,A sì mọ̀ pé àwọn baba ńlá wa ti ṣàṣìṣe,Nítorí a ti ṣẹ̀ ọ́.+
21 Nítorí orúkọ rẹ, má kọ̀ wá sílẹ̀;+Má ṣe fojú àbùkù wo ìtẹ́ ògo rẹ.
Rántí, má sì da májẹ̀mú tí o bá wa dá.+
22 Ǹjẹ́ ìkankan lára àwọn òrìṣà lásánlàsàn tí àwọn orílẹ̀-èdè ń bọ lè rọ òjò,Àbí ṣé ọ̀run fúnra rẹ̀ pàápàá lè dá rọ ọ̀wààrà òjò?
Ìwọ nìkan lo lè ṣe é, Jèhófà Ọlọ́run wa.+
A sì ní ìrètí nínú rẹ,Nítorí ìwọ nìkan ló ń ṣe gbogbo nǹkan yìí.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Tàbí “ọ̀gbẹlẹ̀.”
^ Tàbí “ẹni kékeré.”
^ Tàbí “àwọn àmù; àwọn ìkùdu.”
^ Tàbí “akátá.”
^ Tàbí “àìsàn.”
^ Tàbí “ọkàn rẹ.”