Jẹ́nẹ́sísì 25:1-34

  • Ábúráhámù fẹ́ ìyàwó míì (1-6)

  • Ábúráhámù kú (7-11)

  • Àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì (12-18)

  • Wọ́n bí Jékọ́bù àti Ísọ̀ (19-26)

  • Ísọ̀ ta ogún ìbí rẹ̀ (27-34)

25  Ábúráhámù fẹ́ ìyàwó míì, Kétúrà ni orúkọ rẹ̀.  Nígbà tó yá, ó bí Símíránì, Jókíṣánì, Médánì, Mídíánì,+ Íṣíbákì àti Ṣúáhì.+  Jókíṣánì bí Ṣébà àti Dédánì. Àwọn ọmọ Dédánì ni Áṣúrímù, Létúṣímù àti Léúmímù.  Àwọn ọmọ Mídíánì ni Eéfà, Éférì, Hánókù, Ábíídà àti Élídáà. Ọmọ Kétúrà ni gbogbo wọn.  Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù fún Ísákì  + ní gbogbo ohun tó ní,  àmọ́ Ábúráhámù fún àwọn ọmọ tí àwọn wáhàrì* rẹ̀ bí fún un ní ẹ̀bùn. Nígbà tó ṣì wà láàyè, ó ní kí wọ́n máa lọ sí apá ìlà oòrùn kúrò lọ́dọ̀ Ísákì ọmọ+ rẹ̀, sí ilẹ̀ Ìlà Oòrùn.  Ọjọ́ ayé Ábúráhámù jẹ́ ọdún márùndínlọ́gọ́sàn-án (175).  Ábúráhámù mí èémí ìkẹyìn, ó sì kú, ó darúgbó, ayé rẹ̀ sì dára, wọ́n wá kó o jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀.*  Ísákì àti Íṣímáẹ́lì ọmọ rẹ̀ sin ín sí ihò Mákípẹ́là lórí ilẹ̀ Éfúrónì ọmọ Sóhárì, ọmọ Hétì, tó wà níwájú Mámúrè,+ 10  ilẹ̀ tí Ábúráhámù rà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hétì. Ibẹ̀ ni wọ́n sin Ábúráhámù sí, pẹ̀lú Sérà+ ìyàwó rẹ̀. 11  Lẹ́yìn tí Ábúráhámù kú, Ọlọ́run ṣì ń bù kún Ísákì+ ọmọ rẹ̀, Ísákì sì ń gbé nítòsí Bia-laháí-róì.+ 12  Ìtàn Íṣímáẹ́lì+ ọmọ Ábúráhámù nìyí, ẹni tí Hágárì+ ọmọ ilẹ̀ Íjíbítì tó jẹ́ ìránṣẹ́ Sérà bí fún Ábúráhámù. 13  Orúkọ àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì nìyí, orúkọ wọn gẹ́gẹ́ bí ìdílé tí wọ́n ti wá: Àkọ́bí Íṣímáẹ́lì ni Nébáótì,+ lẹ́yìn náà ó bí Kídárì,+ Ádíbéélì, Míbúsámù,+ 14  Míṣímà, Dúmà, Máásà, 15  Hádádì, Témà, Jétúrì, Náfíṣì àti Kédémà. 16  Àwọn yìí ni ọmọ Íṣímáẹ́lì, orúkọ wọn sì nìyí, gẹ́gẹ́ bí ibi tí wọ́n ń gbé àti ibùdó* wọn, wọ́n jẹ́ ìjòyè méjìlá (12) ní àwọn agbo ilé+ wọn. 17  Ọjọ́ ayé Íṣímáẹ́lì jẹ́ ọdún mẹ́tàdínlógóje (137). Ó mí èémí ìkẹyìn, ó sì kú, wọ́n kó o jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀.* 18  Wọ́n tẹ̀ dó sí Háfílà+ nítòsí Ṣúrì,+ tó sún mọ́ Íjíbítì, títí lọ dé Ásíríà. Wọ́n sì ń gbé nítòsí gbogbo àwọn arákùnrin+ wọn.* 19  Ìtàn Ísákì ọmọ Ábúráhámù+ nìyí. Ábúráhámù bí Ísákì. 20  Ẹni ogójì (40) ọdún ni Ísákì nígbà tó fẹ́ Rèbékà, ọmọ Bẹ́túẹ́lì+ ará Arémíà ní ilẹ̀ Padani-árámù, òun ni arábìnrin Lábánì ará Arémíà. 21  Ísákì sì ń bẹ Jèhófà nítorí ìyàwó rẹ̀, torí pé ó yàgàn; Jèhófà gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, Rèbékà ìyàwó rẹ̀ sì lóyún. 22  Àwọn ọmọ inú rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn+ jà, débi tó fi sọ pé: “Tó bá jẹ́ pé bó ṣe máa ń rí nìyí, ǹjẹ́ kò ní sàn kí n kú?” Torí náà, ó wádìí lọ́wọ́ Jèhófà. 23  Jèhófà sì sọ fún un pé: “Orílẹ̀-èdè méjì ló wà nínú ikùn+ rẹ, èèyàn méjì tó yàtọ̀ síra máa tinú rẹ+ jáde; orílẹ̀-èdè kan máa lágbára ju ìkejì+ lọ, ẹ̀gbọ́n sì máa sin àbúrò.”+ 24  Nígbà tí àsìkò tó máa bímọ tó, wò ó! ìbejì ló wà ní inú rẹ̀. 25  Èyí àkọ́kọ́ sì jáde, ó pupa látòkè délẹ̀, ó dà bí aṣọ onírun,+ torí náà, wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Ísọ̀.*+ 26  Lẹ́yìn náà, àbúrò rẹ̀ jáde, ó sì di gìgísẹ̀ Ísọ̀+ mú, torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Jékọ́bù.*+ Ẹni ọgọ́ta (60) ọdún ni Ísákì nígbà tí Rèbékà bí àwọn ọmọ náà. 27  Bí àwọn ọmọ náà ṣe ń dàgbà, Ísọ̀ di ọdẹ+ tó já fáfá, inú igbó ló sábà máa ń lọ, àmọ́ Jékọ́bù jẹ́ aláìlẹ́bi, inú àgọ́+ ló máa ń wà. 28  Ísákì nífẹ̀ẹ́ Ísọ̀ torí ó máa ń fún un ní ẹran ìgbẹ́ jẹ, àmọ́ Rèbékà nífẹ̀ẹ́ Jékọ́bù.+ 29  Lọ́jọ́ kan, Jékọ́bù ń se ọbẹ̀ nígbà tí Ísọ̀ dé láti oko ọdẹ, ó sì ti rẹ̀ ẹ́ gan-an. 30  Torí náà Ísọ̀ sọ fún Jékọ́bù pé: “Jọ̀ọ́, sáré fún mi lára* ọbẹ̀ pupa tí ò ń sè yẹn,* torí ó ti rẹ̀ mí!”* Ìdí nìyẹn tí orúkọ rẹ̀ fi ń jẹ́ Édómù.*+ 31  Jékọ́bù wá fèsì pé: “Kọ́kọ́ ta ogún ìbí rẹ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí+ fún mi!” 32  Ísọ̀ dá a lóhùn pé: “Èmi tí mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú! Kí ni ogún ìbí fẹ́ dà fún mi?” 33  Jékọ́bù sọ pé: “Kọ́kọ́ búra fún mi!” Ló bá búra fún un, ó sì ta ogún ìbí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí fún Jékọ́bù.+ 34  Jékọ́bù wá fún Ísọ̀ ní búrẹ́dì àti ọbẹ̀ ẹ̀wà lẹ́ńtìlì, ó jẹ, ó sì mu. Ó dìde, ó sì ń lọ. Bí Ísọ̀ ṣe fi hàn pé òun ò mọyì ogún ìbí rẹ̀ nìyẹn.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”
Àkànlò èdè yìí ni wọ́n fi ń sọ pé èèyàn kú.
Tàbí “àgọ́ olódi.”
Àkànlò èdè yìí ni wọ́n fi ń sọ pé èèyàn kú.
Tàbí kó jẹ́, “Kò sí àlàáfíà láàárín àwọn àtàwọn arákùnrin wọn.”
Ó túmọ̀ sí “Onírun Lára.”
Ó túmọ̀ sí “Ẹni Tó Ń Di Gìgísẹ̀ Mú; Ẹni Tó Gba Ipò Onípò.”
Tàbí “fún mi ní díẹ̀ nínú.”
Ní Héb., “pupa yìí, pupa yìí gangan.”
Tàbí “ebi ń pa mí gan-an.”
Ó túmọ̀ sí “Pupa.”