Sí Àwọn Hébérù 8:1-13

  • Àgọ́ ìjọsìn tó jẹ mọ́ nǹkan ti ọ̀run (1-6)

  • Ìyàtọ̀ tó wà láàárín májẹ̀mú ti tẹ́lẹ̀ àti májẹ̀mú tuntun (7-13)

8  Kókó ọ̀rọ̀ tí à ń sọ nìyí: A ní irú àlùfáà àgbà yìí,+ ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọba Ọlọ́lá ní ọ̀run,+  òjíṣẹ́* ibi mímọ́+ àti àgọ́ tòótọ́, tí Jèhófà* gbé kalẹ̀, kì í ṣe èèyàn.  Torí gbogbo àlùfáà àgbà la yàn láti máa fi àwọn ọrẹ àti ẹbọ rúbọ; torí náà, ó pọn dandan fún ẹni yìí náà pé kó ní ohun kan láti fi rúbọ.+  Tó bá jẹ́ pé ayé ló wà, kò ní jẹ́ àlùfáà,+ torí àwọn èèyàn tó ń fi ọrẹ rúbọ bí Òfin ṣe sọ ti wà.  Àwọn èèyàn yìí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ bí àpẹẹrẹ àti òjìji+ àwọn nǹkan ti ọ̀run;+ bí a ṣe pàṣẹ fún Mósè láti ọ̀run, nígbà tó fẹ́ kọ́ àgọ́ náà pé: Torí Ó sọ pé: “Rí i pé o ṣe gbogbo nǹkan bí ohun tí mo fi hàn ọ́ lórí òkè.”+  Àmọ́ ní báyìí, Jésù ti gba iṣẹ́ òjíṣẹ́* tó lọ́lá jùyẹn lọ torí òun tún ni alárinà+ májẹ̀mú tó dáa jù,+ tó sì bá a mu rẹ́gí, èyí tí a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà òfin lórí àwọn ìlérí tó dáa jù.+  Ká sọ pé májẹ̀mú àkọ́kọ́ yẹn ò ní àléébù ni, a ò ní nílò ìkejì.+  Torí ó ń rí àléébù lára àwọn èèyàn nígbà tó sọ pé: “‘Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,’ ni Jèhófà* wí, ‘tí màá bá ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà dá májẹ̀mú tuntun.  Kò ní dà bíi májẹ̀mú tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá ní ọjọ́ tí mo dì wọ́n lọ́wọ́ mú láti mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ torí pé wọn ò pa májẹ̀mú mi mọ́, ìdí nìyẹn tí mi ò fi bójú tó wọn mọ́,’ ni Jèhófà* wí. 10  “‘Nítorí májẹ̀mú tí màá bá ilé Ísírẹ́lì dá lẹ́yìn ìgbà yẹn nìyí,’ ni Jèhófà* wí. ‘Màá fi àwọn òfin mi sínú èrò wọn, inú ọkàn wọn sì ni màá kọ ọ́ sí.+ Màá di Ọlọ́run wọn, wọ́n á sì di èèyàn mi.+ 11  “‘Kálukú wọn kò tún ní máa kọ́ ọmọ ìbílẹ̀ rẹ̀ àti arákùnrin rẹ̀ mọ́ pé: “Ẹ mọ Jèhófà!”* Nítorí gbogbo wọn á mọ̀ mí, látorí ẹni tó kéré jù lọ dórí ẹni tó tóbi jù lọ láàárín wọn. 12  Torí màá ṣàánú wọn lórí ọ̀rọ̀ ìwà àìṣòdodo wọn, mi ò sì ní rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.’”+ 13  Bó ṣe pè é ní “májẹ̀mú tuntun,” ó ti sọ èyí tó wà tẹ́lẹ̀ di èyí tí kò wúlò mọ́.+ Ní báyìí, èyí tí kò wúlò mọ́, tó sì ti ń gbó lọ máa tó pa rẹ́ pátápátá.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ìránṣẹ́ gbogbo èèyàn.”
Tàbí “iṣẹ́ ìsìn gbogbo èèyàn.”