Sí Àwọn Ará Fílípì 3:1-21

  • Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé ẹran ara (1-11)

    • Ohun gbogbo jẹ́ àdánù nítorí Kristi (7-9)

  • Mò ń nàgà láti gba èrè náà (12-21)

    • Ìlú ìbílẹ̀ wa wà ní ọ̀run (20)

3  Lákòótán, ẹ̀yin ará mi, ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa.+ Kò ni mí lára láti kọ̀wé nípa àwọn ohun kan náà sí yín, torí ààbò yín sì ni.  Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn ajá; ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn oníṣẹ́ ibi; ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn tó ń kọ ara nílà.+  Nítorí àwa ni a dádọ̀dọ́* lóòótọ́,+ àwa tí à ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí Ọlọ́run, tí à ń fi Kristi Jésù yangàn,+ tí a ò sì gbẹ́kẹ̀ lé ẹran ara,  torí náà, tí a bá rí ẹnikẹ́ni tó ní ìdí láti gbẹ́kẹ̀ lé ẹran ara, èmi gan-an ní. Tí ẹlòmíì bá sì rò pé òun ní ìdí láti gbẹ́kẹ̀ lé ẹran ara, tèmi jù bẹ́ẹ̀:  mo dádọ̀dọ́* ní ọjọ́ kẹjọ,+ mo jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, mo wá láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, Hébérù tó jẹ́ ọmọ bíbí àwọn Hébérù;+ ní ti òfin, mo jẹ́ Farisí;+  ní ti ìtara, mo ṣe inúnibíni sí ìjọ;+ ní ti jíjẹ́ olódodo nínú pípa òfin mọ́, mo jẹ́ aláìlẹ́bi.  Síbẹ̀, àwọn ohun tó jẹ́ èrè fún mi ni mo ti kà sí àdánù* nítorí Kristi.+  Yàtọ̀ síyẹn, mo ti ka ohun gbogbo sí àdánù nítorí ìmọ̀ nípa Kristi Jésù Olúwa mi ṣeyebíye ju ohun gbogbo lọ. Nítorí rẹ̀, mo ti gbé ohun gbogbo sọ nù, mo sì kà wọ́n sí ọ̀pọ̀ pàǹtírí,* kí n lè jèrè Kristi,  kí ó sì hàn pé mo wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, kì í ṣe nítorí òdodo tèmi nínú pípa Òfin mọ́, àmọ́ ó jẹ́ nítorí òdodo tó wá nípasẹ̀ ìgbàgbọ́  + nínú Kristi,+ òdodo tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tó sì dá lórí ìgbàgbọ́.+ 10  Mo fẹ́ mọ Kristi àti agbára àjíǹde rẹ̀,+ kí n jẹ irú ìyà tó jẹ,+ kí n sì kú irú ikú tó kú,+ 11  kí n lè rí i bóyá lọ́nàkọnà, ọwọ́ mi á tẹ àjíǹde àkọ́kọ́ kúrò nínú ikú.+ 12  Kì í ṣe pé mo ti rí i gbà tàbí pé a ti sọ mí di pípé, àmọ́ mò ń sapá+ bóyá ọwọ́ mi á lè tẹ ohun tí Kristi Jésù torí rẹ̀ yàn mí.*+ 13  Ẹ̀yin ará, mi ò ka ara mi sí ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ̀ ẹ́; àmọ́ ohun kan tó dájú ni pé: Bí mo ṣe ń gbàgbé àwọn ohun tí mo fi sílẹ̀ sẹ́yìn,+ tí mo sì ń nàgà sí àwọn ohun tó wà níwájú,+ 14  mò ń sapá kí ọwọ́ mi lè tẹ èrè+ ìpè+ Ọlọ́run sí òkè nípasẹ̀ Kristi Jésù. 15  Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí àwa tí a ti dàgbà+ ní èrò yìí, tí èrò yín bá sì yàtọ̀ lọ́nà èyíkéyìí, Ọlọ́run á jẹ́ kí ẹ ní èrò tí mo sọ yìí. 16  Àmọ́ ṣá, níbi tí a tẹ̀ síwájú dé, ẹ jẹ́ kí a máa rìn létòlétò ní ọ̀nà kan náà. 17  Ẹ̀yin ará, kí gbogbo yín máa fara wé mi,+ kí ẹ sì tẹ ojú yín mọ́ àwọn tó ń rìn lọ́nà tó bá àpẹẹrẹ tí a fi lélẹ̀ fún yín mu. 18  Nítorí ọ̀pọ̀ èèyàn ló wà, mo sábà máa ń mẹ́nu kàn wọ́n tẹ́lẹ̀, ní báyìí tẹkúntẹkún ni mò ń mẹ́nu kàn wọ́n, àwọn tí wọ́n ń hùwà bí ọ̀tá òpó igi oró* Kristi. 19  Ìparun ni ìgbẹ̀yìn wọn, ikùn wọn ni ọlọ́run wọn, ohun ìtìjú ni wọ́n fi ń ṣògo, àwọn nǹkan ti ayé ni wọ́n sì ń rò.+ 20  Àmọ́, ìlú ìbílẹ̀ wa*+ wà ní ọ̀run,+ a sì ń dúró de olùgbàlà láti ibẹ̀ lójú méjèèjì, ìyẹn Jésù Kristi Olúwa,+ 21  ẹni tó máa fi agbára ńlá rẹ̀ yí ara rírẹlẹ̀ wa pa dà kí ó lè dà bí* ara ológo tirẹ̀,+ èyí tó mú kó lè fi ohun gbogbo sábẹ́ ara rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “kọlà.”
Tàbí “kọlà.”
Tàbí kó jẹ́, “fi sílẹ̀ tinútinú.”
Tàbí “ìdọ̀tí.”
Ní Grk., “gbé ọwọ́ lé mi.”
Ní Grk., “ẹ̀tọ́ wa láti jẹ́ aráàlú.”
Ní Grk., “bára mu pẹ̀lú.”