Sámúẹ́lì Kejì 22:1-51
22 Dáfídì kọ ọ̀rọ̀ yìí lórin+ sí Jèhófà ní ọjọ́ tí Jèhófà gbà á lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀+ àti lọ́wọ́ Sọ́ọ̀lù.+
2 Ó sọ pé:
“Jèhófà ni àpáta gàǹgà mi àti odi ààbò+ mi àti Ẹni tó ń gbà mí sílẹ̀.+
3 Ọlọ́run mi ni àpáta+ mi, ẹni tí mo fi ṣe ibi ààbò,Apata+ mi àti ìwo* ìgbàlà mi,* ibi ààbò+ mi,*Àti ibi tí mo lè sá sí,+ olùgbàlà+ mi; ìwọ tí o gbà mí lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá.
4 Mo ké pe Jèhófà, ẹni tí ìyìn yẹ,Yóò sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.
5 Ikú yí mi ká bí ìgbì òkun;+Àwọn ọkùnrin tí kò ní láárí ya lù mí bí omi.+
6 Àwọn okùn Isà Òkú* yí mi ká;+Ikú dẹ pańpẹ́ síwájú mi.+
7 Mo ké pe Jèhófà nínú wàhálà mi,+Mo sì ń pe Ọlọ́run mi.
Nígbà náà, ó gbọ́ ohùn mi láti tẹ́ńpìlì rẹ̀,Igbe mi fún ìrànlọ́wọ́ sì dé etí rẹ̀.+
8 Ayé bẹ̀rẹ̀ sí í mì síwá-sẹ́yìn, ó sì ń mì jìgìjìgì;+Àwọn ìpìlẹ̀ ọ̀run mì tìtì+Wọ́n sì ń mì síwá-sẹ́yìn nítorí a ti mú un bínú.+
9 Èéfín jáde láti ihò imú rẹ̀,Iná tó ń jóni run jáde láti ẹnu rẹ̀,+Ẹyin iná sì ń jó láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.
10 Ó tẹ ọ̀run wálẹ̀ bí ó ṣe ń sọ̀ kalẹ̀,+Ìṣúdùdù tó kàmàmà sì wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.+
11 Ó gun kérúbù,+ ó sì ń fò bọ̀.
A rí i lórí ìyẹ́ apá áńgẹ́lì kan.*+
12 Ó wá fi òkùnkùn bò ó bí àgọ́,+Nínú ojú ọ̀run tó ṣú dẹ̀dẹ̀.
13 Láti inú ìmọ́lẹ̀ tó wà níwájú rẹ̀ ni ẹyin iná ti ń jó.
14 Nígbà náà, Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í sán ààrá láti ọ̀run;+Ẹni Gíga Jù Lọ mú kí a gbọ́ ohùn rẹ̀.+
15 Ó ta àwọn ọfà+ rẹ̀, ó sì tú wọn ká;Mànàmáná kọ, ó sì kó wọn sínú ìdàrúdàpọ̀.+
16 Ìsàlẹ̀ òkun hàn síta;+Àwọn ìpìlẹ̀ ayé hàn síta nítorí ìbáwí Jèhófà,Nípa èémí tó tú jáde ní ihò imú rẹ̀.+
17 Ó na ọwọ́ rẹ̀ láti òkè;Ó mú mi, ó sì fà mí jáde látinú omi jíjìn.+
18 Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára,+Lọ́wọ́ àwọn tó kórìíra mi, tí wọ́n sì lágbára jù mí lọ.
19 Wọ́n kò mí lójú ní ọjọ́ àjálù mi,+Ṣùgbọ́n Jèhófà ni alátìlẹyìn mi.
20 Ó mú mi jáde wá sí ibi ààbò;*+Ó gbà mí sílẹ̀ nítorí pé inú rẹ̀ dùn sí mi.+
21 Jèhófà san èrè fún mi nítorí òdodo mi;+Ó san èrè fún mi nítorí pé ọwọ́ mi mọ́.*+
22 Nítorí mo ti pa àwọn ọ̀nà Jèhófà mọ́,Mi ò hùwà burúkú, kí n wá fi Ọlọ́run mi sílẹ̀.
23 Gbogbo ìdájọ́ rẹ̀+ wà ní iwájú mi;Mi ò ní yà kúrò nínú àwọn òfin rẹ̀.+
24 Màá jẹ́ aláìlẹ́bi+ níwájú rẹ̀,Màá sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.+
25 Kí Jèhófà san èrè fún mi nítorí òdodo mi +Àti nítorí mo jẹ́ aláìṣẹ̀ ní iwájú rẹ̀.+
26 Ìwọ jẹ́ adúróṣinṣin sí ẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin;+Ìwọ ń hùwà àìlẹ́bi sí akíkanjú ọkùnrin aláìlẹ́bi;+
27 Ìwọ jẹ́ mímọ́ sí ẹni tí ó mọ́,+Àmọ́ ìwọ ń jẹ́ kí àwọn oníbékebèke mọ̀ pé òmùgọ̀ ni wọ́n.*+
28 Ò ń gba àwọn ẹni rírẹlẹ̀ là,+Ṣùgbọ́n o kì í fi ojú rere wo àwọn agbéraga, o sì ń rẹ̀ wọ́n wálẹ̀.+
29 Jèhófà, ìwọ ni fìtílà mi,+Jèhófà ló sì ń tan ìmọ́lẹ̀ sí òkùnkùn mi.+
30 Ìrànlọ́wọ́ rẹ ni mo fi lè gbéjà ko àwọn jàǹdùkú;*Agbára Ọlọ́run ni mo fi lè gun ògiri.+
31 Pípé ni ọ̀nà Ọlọ́run tòótọ́;+Ọ̀rọ̀ Jèhófà jẹ́ èyí tí a yọ́ mọ́.+
Apata ló jẹ́ fún gbogbo àwọn tó fi í ṣe ibi ààbò.+
32 Ta ni Ọlọ́run bí kò ṣe Jèhófà?+
Ta sì ni àpáta bí kò ṣe Ọlọ́run wa?+
33 Ọlọ́run tòótọ́ ni odi ààbò mi tó lágbára,+Yóò sì mú kí ọ̀nà mi jẹ́ pípé.+
34 Ó ṣe ẹsẹ̀ mi bíi ti àgbọ̀nrín,Ó sì mú mi dúró ní àwọn ibi gíga.+
35 Ó ń kọ́ ọwọ́ mi ní ogun,Apá mi sì lè tẹ ọrun tí a fi bàbà ṣe.
36 O fún mi ní apata rẹ láti gbà mí là,Ìrẹ̀lẹ̀ rẹ sì sọ mí di ẹni ńlá. +
37 O fẹ ọ̀nà fún ẹsẹ̀ mi;Kí ẹsẹ̀* mi má bàa yọ̀.+
38 Màá lépa àwọn ọ̀tá mi, màá sì pa wọ́n run;Mi ò ní pa dà títí wọ́n á fi pa rẹ́.
39 Màá pa wọ́n run, màá sì fọ́ wọn túútúú, kí wọ́n má bàa gbérí mọ́;+Wọ́n á ṣubú sábẹ́ ẹsẹ̀ mi.
40 Wàá fún mi lókun láti jagun,+Wàá sì mú kí àwọn ọ̀tá mi ṣubú sábẹ́ mi.+
41 Wàá mú kí àwọn ọ̀tá mi pa dà lẹ́yìn mi;*+Màá pa àwọn tó kórìíra mi run.*+
42 Wọ́n kígbe fún ìrànlọ́wọ́, àmọ́ kò sí ẹni tó máa gbà wọ́n;Kódà, wọ́n ké pe Jèhófà, àmọ́ kò dá wọn lóhùn.+
43 Màá gún wọn kúnná bí eruku ilẹ̀;Màá lọ̀ wọ́n, màá sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ ojú ọ̀nà.
44 Wàá gbà mí lọ́wọ́ àwọn èèyàn mi tó ń wá àléébù.+
Wàá ṣọ́ mi kí n lè di olórí àwọn orílẹ̀-èdè;+Àwọn èèyàn tí mi ò mọ̀ yóò sìn mí.+
45 Àwọn àjèjì á wá ba búrúbúrú níwájú mi;+Ohun tí wọ́n bá gbọ́ nípa mi á mú kí wọ́n ṣègbọràn sí mi.*
46 Ọkàn àwọn àjèjì á domi;*Wọ́n á jáde tẹ̀rùtẹ̀rù látinú ibi ààbò wọn.
47 Jèhófà wà láàyè! Ìyìn ni fún Àpáta mi!+
Kí a gbé Ọlọ́run tó jẹ́ àpáta ìgbàlà mi ga.+
48 Ọlọ́run tòótọ́ ń gbẹ̀san fún mi;+Ó ń ṣẹ́gun àwọn èèyàn lábẹ́ mi;+
49 Ó ń gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.
Ìwọ gbé mi lékè+ àwọn tó ń gbéjà kò mí;O gbà mí lọ́wọ́ oníwà ipá.+
50 Ìdí nìyẹn tí màá fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Jèhófà, láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+Màá sì fi orin yin*+ orúkọ rẹ:
51 Ó ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìgbàlà* ńlá fún ọba rẹ̀;+Ó ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí ẹni àmì òróró rẹ̀,Sí Dáfídì àti àtọmọdọ́mọ* rẹ̀ títí láé.”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “olùgbàlà mi tó lágbára.”
^ Tàbí “ibi gíga mi tó láàbò.”
^ Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “ìyẹ́ afẹ́fẹ́.”
^ Tàbí “ibi tó láyè fífẹ̀.”
^ Tàbí “mo jẹ́ aláìmọwọ́mẹsẹ̀.”
^ Tàbí kó jẹ́, “ìwọ ń ṣe bí ẹni tí kò gbọ́n sí àwọn oníbékebèke.”
^ Tàbí “akónilẹ́rù.”
^ Tàbí “ọrùn ẹsẹ̀.”
^ Tàbí “Wàá jẹ́ kí n gbá ẹ̀yìn ọrùn àwọn ọ̀tá mi mú.”
^ Ní Héb., “lẹ́nu mọ́.”
^ Ní Héb., “Tí wọ́n bá gbọ́ ìró mi, wọ́n á ṣègbọràn sí mi.”
^ Tàbí “Àwọn àjèjì á pòórá.”
^ Tàbí “kọ orin sí.”
^ Tàbí “ìṣẹ́gun.”
^ Ní Héb., “èso.”