Sámúẹ́lì Kejì 18:1-33
18 Nígbà náà, Dáfídì ka iye àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì yan àwọn kan ṣe olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún.+
2 Dáfídì wá fi ìdá mẹ́ta àwọn èèyàn náà sábẹ́ àṣẹ* Jóábù,+ ó fi ìdá mẹ́ta sábẹ́ àṣẹ Ábíṣáì+ ọmọ Seruáyà,+ ẹ̀gbọ́n Jóábù, ó sì wá fi ìdá mẹ́ta sábẹ́ àṣẹ Ítáì+ ará Gátì. Ọba sọ fún àwọn ọkùnrin náà pé: “Èmi náà á bá yín lọ.”
3 Ṣùgbọ́n wọ́n sọ pé: “O ò lè lọ o,+ nítorí tí a bá sá, ọ̀rọ̀ wa ò lè jọ wọ́n lójú;* kódà tí ìdajì wa bá kú, kò lè jẹ́ nǹkan kan lójú wọn, nítorí ìwọ nìkan tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) gbogbo wa.+ Torí náà, ó máa dára kí o máa ràn wá lọ́wọ́ látinú ìlú.”
4 Ọba sọ fún wọn pé: “Ohun tí ẹ bá rí pé ó dára jù ni màá ṣe.” Torí náà, ọba dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnubodè ìlú, gbogbo àwọn èèyàn náà sì jáde lọ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún àti ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún.
5 Ọba wá pàṣẹ fún Jóábù àti Ábíṣáì àti Ítáì pé: “Ẹ ṣe ọ̀dọ́kùnrin náà Ábúsálómù jẹ́jẹ́ nítorí mi.”+ Gbogbo àwọn ọkùnrin náà gbọ́ nígbà tí ọba pàṣẹ fún gbogbo àwọn olórí nítorí Ábúsálómù.
6 Àwọn ọkùnrin náà lọ sí pápá láti pàdé Ísírẹ́lì, ìjà náà sì wáyé ní igbó Éfúrémù.+
7 Ibẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì+ ti ṣẹ́gun àwọn èèyàn Ísírẹ́lì,+ ọ̀pọ̀ èèyàn sì kú lọ́jọ́ yẹn, ọ̀kẹ́ kan (20,000) èèyàn ló kú.
8 Ogun náà dé gbogbo agbègbè náà. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tí igbó kìjikìji pa lọ́jọ́ yẹn pọ̀ ju àwọn tí idà pa lọ.
9 Níkẹyìn, Ábúsálómù ṣàdédé pàdé àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* ni Ábúsálómù gùn, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* náà sì gba abẹ́ àwọn ẹ̀ka tó díjú lára igi ńlá kan, orí Ábúsálómù há sínú igi ńlá náà, ó rọ̀ dirodiro lókè,* kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* tí ó gùn sì kọjá lọ.
10 Ọkùnrin kan bá rí i, ó sì sọ fún Jóábù+ pé: “Wò ó! Mo rí Ábúsálómù tó so rọ̀ sórí igi ńlá kan.”
11 Jóábù sọ fún ọkùnrin tó wá sọ̀rọ̀ fún un pé: “Ìgbà tí o rí i, kí ló dé tí o ò ṣá a balẹ̀ níbẹ̀? Tayọ̀tayọ̀ ni mi ò bá fi fún ọ ní ẹyọ fàdákà mẹ́wàá àti àmùrè kan.”
12 Àmọ́ ọkùnrin náà sọ fún Jóábù pé: “Kódà, ká ní ẹgbẹ̀rún (1,000) ẹyọ fàdákà ni o fún mi,* mi ò ní gbé ọwọ́ mi sókè sí ọmọ ọba; nítorí a gbọ́ tí ọba pàṣẹ fún ìwọ àti Ábíṣáì pẹ̀lú Ítáì pé, ‘Ẹni yòówù tí ì báà jẹ́, ẹ ṣọ́ra kí ewu kankan má wu ọ̀dọ́kùnrin náà, Ábúsálómù.’+
13 Ká ní mo ti ṣàìgbọràn ni, tí mo sì gba ẹ̀mí rẹ̀,* ọba kò ní ṣàìmọ̀ nípa rẹ̀, ìwọ náà ò sì ní dáàbò bò mí.”
14 Jóábù bá sọ pé: “Mi ò ní fi àkókò mi ṣòfò lọ́dọ̀ rẹ mọ́!” Torí náà, ó mú aṣóró* mẹ́ta, ó sì fi wọ́n gún ọkàn Ábúsálómù ní àgúnyọ nígbà tí ó ṣì wà láàyè ní àárín igi ńlá náà.
15 Nígbà náà, àwọn ìránṣẹ́ mẹ́wàá tó ń gbé àwọn ohun ìjà Jóábù wá, wọ́n sì kọ lu Ábúsálómù títí ó fi kú.+
16 Jóábù wá fun ìwo, àwọn ọkùnrin náà sì pa dà lẹ́yìn Ísírẹ́lì tí wọ́n ń lépa; Jóábù ní kí wọ́n dáwọ́ dúró.
17 Wọ́n gbé Ábúsálómù, wọ́n sọ ọ́ sínú kòtò ńlá kan nínú igbó, wọ́n sì kó òkúta lé e lórí pelemọ.+ Gbogbo Ísírẹ́lì sì sá lọ sí ilé wọn.
18 Nígbà tí Ábúsálómù ṣì wà láàyè, ó ṣe òpó kan, ó sì gbé e nàró fún ara rẹ̀ ní Àfonífojì* Ọba,+ torí ó sọ pé: “Mi ò ní ọmọkùnrin tí á máa jẹ́ orúkọ mi lọ.”+ Nítorí náà, ó fi orúkọ ara rẹ̀ pe òpó náà, Ohun Ìrántí Ábúsálómù ni wọ́n sì ń pè é títí di òní yìí.
19 Áhímáásì+ ọmọ Sádókù sọ pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n sáré lọ ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ fún ọba, nítorí pé Jèhófà ti bá a dá ẹjọ́ rẹ̀ lọ́nà tó tọ́ bí ó ṣe gbà á lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.”+
20 Àmọ́ Jóábù sọ fún un pé: “Kì í ṣe ìwọ ló máa lọ ròyìn lónìí, o lè lọ ròyìn lọ́jọ́ míì, àmọ́ lónìí, o ò ní lọ ròyìn, nítorí pé ọmọ ọba ló kú.”+
21 Nígbà náà, Jóábù sọ fún ọmọ Kúṣì+ kan pé: “Lọ sọ ohun tí o rí fún ọba.” Ni ọmọ Kúṣì náà bá tẹrí ba fún Jóábù, ó sì sáré lọ.
22 Áhímáásì ọmọ Sádókù tún sọ fún Jóábù pé: “Ohunkóhun tí ì báà ṣẹlẹ̀, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n sá tẹ̀ lé ọmọ Kúṣì náà.” Àmọ́, Jóábù sọ pé: “Ọmọ mi, kí nìdí tí o fi fẹ́ sá tẹ̀ lé e, nígbà tí kò sí nǹkan tí o máa ròyìn?”
23 Síbẹ̀, ó ní: “Ohunkóhun tí ì báà ṣẹlẹ̀, jẹ́ kí n sá tẹ̀ lé e.” Nítorí náà, Jóábù sọ fún un pé: “Sá tẹ̀ lé e!” Áhímáásì sì sáré gba agbègbè Jọ́dánì,* níkẹyìn, ó kọjá ọmọ Kúṣì náà.
24 Ní àkókò yìí, Dáfídì jókòó sí àárín ẹnubodè+ méjèèjì tó wà ní ìlú náà, olùṣọ́+ sì lọ sí orí òrùlé ẹnubodè tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri. Ó gbójú sókè, ó sì rí ọkùnrin kan tí òun nìkan ń sáré bọ̀.
25 Nítorí náà, olùṣọ́ ké sí ọba, ó sì sọ fún un. Ọba sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ òun nìkan ló ń bọ̀, á jẹ́ pé ìròyìn ló mú wá.” Bí ó ṣe ń sún mọ́ tòsí,
26 olùṣọ́ rí ọkùnrin míì tó ń sáré bọ̀. Olùṣọ́ bá pe aṣọ́bodè, ó ní: “Wò ó! Ọkùnrin míì ń dá sáré bọ̀!” Ọba sọ pé: “Ìròyìn ni ẹni yìí náà ń mú bọ̀.”
27 Olùṣọ́ sọ pé: “Mo rí i pé ẹni àkọ́kọ́ ń sáré bí Áhímáásì+ ọmọ Sádókù,” torí náà ọba sọ pé: “Èèyàn rere ni, ìròyìn ayọ̀ ló máa ń mú wá.”
28 Áhímáásì ké sí ọba pé: “Àlàáfíà ni!” Ó tẹrí ba fún ọba, ó sì dojú bolẹ̀. Ó sọ pé: “Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó fi àwọn ọkùnrin tí ó dìtẹ̀* sí olúwa mi ọba lé e lọ́wọ́!”+
29 Àmọ́, ọba sọ pé: “Ṣé àlàáfíà ni ọ̀dọ́kùnrin náà Ábúsálómù wà?” Áhímáásì fèsì pé: “Nígbà tí Jóábù rán ìránṣẹ́ ọba àti ìránṣẹ́ rẹ, mo rí i tí ariwo sọ láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn, àmọ́ mi ò mọ ohun tó ṣẹlẹ̀.”+
30 Nítorí náà, ọba sọ pé: “Bọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, dúró síbẹ̀.” Ó bọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́, ó sì dúró síbẹ̀.
31 Lẹ́yìn náà, ọmọ Kúṣì dé,+ ó sì sọ pé: “Kí olúwa mi ọba gbọ́ ìròyìn yìí: Jèhófà ti dá ẹjọ́ rẹ lọ́nà tó tọ́ lónìí bí ó ṣe gbà ọ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.”+
32 Ṣùgbọ́n ọba sọ fún ọmọ Kúṣì pé: “Ṣé àlàáfíà ni ọ̀dọ́kùnrin náà Ábúsálómù wà?” Ọmọ Kúṣì fèsì pé: “Kí gbogbo àwọn ọ̀tá olúwa mi ọba àti gbogbo àwọn tó ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọ dà bí ọ̀dọ́kùnrin náà!”+
33 Ọ̀rọ̀ yìí kó ìdààmú bá ọba, ó lọ sí yàrá tó wà lórí ẹnubodè, ó sì bú sẹ́kún, bí ó ṣe ń rìn lọ, ó ń sọ pé: “Ọmọ mi Ábúsálómù, ọmọ mi, ọmọ mi Ábúsálómù! Ì bá dáa ká ní èmi ni mo kú dípò rẹ, Ábúsálómù ọmọ mi, ọmọ mi!”+
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ní Héb., “sí ìkáwọ́.”
^ Ní Héb., “wọn ò lè fọkàn sí wa.”
^ Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù ń tọ́ka sí ìbaaka
^ Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù ń tọ́ka sí ìbaaka
^ Ní Héb., “láàárín ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.”
^ Ọ̀rọ̀ yìí ní Hébérù ń tọ́ka sí ìbaaka
^ Ní Héb., “Ká ní mo tiẹ̀ ń wọn ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà ní àtẹ́wọ́ mi.”
^ Tàbí “Ká ní mo ti ṣe àdàkàdekè sí ọkàn rẹ̀ ni.”
^ Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ “ọ̀kọ̀.” Ní Héb., “ọ̀pá.”
^ Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”
^ Ní Héb., “agbègbè náà.”
^ Ní Héb., “gbé ọwọ́ wọn sókè.”