Kíróníkà Kejì 34:1-33
34 Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni Jòsáyà+ nígbà tó jọba, ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n (31) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+
2 Ó ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà, ó rìn ní àwọn ọ̀nà Dáfídì baba ńlá rẹ̀, kò sì yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì.
3 Ní ọdún kẹjọ ìjọba rẹ̀, nígbà tó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́kùnrin, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá Ọlọ́run Dáfídì baba ńlá rẹ̀;+ ní ọdún kejìlá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í mú àwọn ibi gíga+ àti àwọn òpó òrìṣà* àti àwọn ère gbígbẹ́+ pẹ̀lú àwọn ère onírin* kúrò ní Júdà àti Jerúsálẹ́mù.+
4 Láfikún sí i, wọ́n wó pẹpẹ àwọn Báálì lulẹ̀ níṣojú rẹ̀, ó sì gé àwọn pẹpẹ tùràrí tó wà lókè orí wọn lulẹ̀. Ó tún fọ́ àwọn òpó òrìṣà* àti àwọn ère gbígbẹ́ pẹ̀lú àwọn ère onírin* sí wẹ́wẹ́, ó lọ̀ wọ́n lẹ́búlẹ́bú, ó sì wọ́n ekuru wọn sórí sàréè àwọn tó ń rúbọ sí wọn tẹ́lẹ̀.+
5 Ó sun egungun àwọn àlùfáà lórí àwọn pẹpẹ wọn.+ Bí ó ṣe fọ Júdà àti Jerúsálẹ́mù mọ́ nìyẹn.
6 Ní àwọn ìlú Mánásè, Éfúrémù,+ Síméónì àti títí dé Náfútálì, ní àwọn ibi tó ti di àwókù tó yí wọn ká,
7 ó wó àwọn pẹpẹ, ó fọ́ àwọn òpó òrìṣà* àti àwọn ère gbígbẹ́ túútúú,+ ó sì lọ̀ wọ́n lẹ́búlẹ́bú; ó gé gbogbo àwọn pẹpẹ tùràrí lulẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì,+ lẹ́yìn náà, ó pa dà sí Jerúsálẹ́mù.
8 Ní ọdún kejìdínlógún ìjọba rẹ̀, nígbà tó ti fọ ilẹ̀ náà àti tẹ́ńpìlì* náà mọ́, ó rán Ṣáfánì + ọmọ Asaláyà àti Maaseáyà olórí ìlú náà àti Jóà ọmọ Jóáhásì akọ̀wé ìrántí láti lọ tún ilé Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ ṣe.+
9 Wọ́n wá sọ́dọ̀ Hilikáyà àlùfáà àgbà, wọ́n sì fún un ní owó tí àwọn èèyàn mú wá sí ilé Ọlọ́run, èyí tí àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ aṣọ́nà ti gbà lọ́wọ́ Mánásè àti Éfúrémù àti lọ́wọ́ gbogbo ìyókù Ísírẹ́lì,+ títí kan Júdà, Bẹ́ńjámínì àti àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù.
10 Lẹ́yìn náà, wọ́n kó o fún àwọn tí wọ́n yàn láti máa bójú tó iṣẹ́ ilé Jèhófà. Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ilé Jèhófà sì lò ó láti mú ilé náà bọ̀ sípò àti láti tún un ṣe.
11 Wọ́n kó o fún àwọn oníṣẹ́ ọnà àti àwọn kọ́lékọ́lé láti fi ra òkúta gbígbẹ́ àti àwọn ẹ̀là gẹdú láti fi ṣe àwọn agbóhunró àti àwọn ìtì igi tí wọ́n á fi kọ́ àwọn ilé tí àwọn ọba Júdà ti jẹ́ kó di àwókù.+
12 Àwọn ọkùnrin náà fi òótọ́ inú ṣe iṣẹ́ náà.+ Àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n yàn láti jẹ́ alábòójútó wọn ni Jáhátì àti Ọbadáyà látinú àwọn ọmọ Mérárì+ àti Sekaráyà pẹ̀lú Méṣúlámù látinú àwọn ọmọ Kóhátì.+ Àwọn ọmọ Léfì, tí gbogbo wọn jẹ́ olórin tó mọṣẹ́ orin,+
13 ló ń mójú tó àwọn lébìrà,* àwọn sì tún ni alábòójútó gbogbo àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ náà ní onírúurú ẹ̀ka; àwọn kan lára àwọn ọmọ Léfì sì jẹ́ akọ̀wé, aláṣẹ àti aṣọ́bodè.+
14 Nígbà tí wọ́n ń kó owó táwọn èèyàn mú wá sí ilé Jèhófà jáde,+ àlùfáà Hilikáyà rí ìwé Òfin+ tí Jèhófà fún wọn nípasẹ̀* Mósè.+
15 Torí náà, Hilikáyà sọ fún Ṣáfánì akọ̀wé pé: “Mo ti rí ìwé Òfin ní ilé Jèhófà.” Ni Hilikáyà bá fún Ṣáfánì ní ìwé náà.
16 Ṣáfánì mú ìwé náà wá sọ́dọ̀ ọba, ó sì sọ fún un pé: “Àwọn ìránṣẹ́ rẹ ń ṣe gbogbo ohun tí a yàn fún wọn.
17 Wọ́n ti kó owó tí wọ́n rí ní ilé Jèhófà, wọ́n sì ti kó o fún àwọn ọkùnrin tí a yàn àti àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ náà.”
18 Ṣáfánì akọ̀wé tún sọ fún ọba pé: “Ìwé kan wà tí àlùfáà Hilikáyà fún mi.”+ Ṣáfánì sì bẹ̀rẹ̀ sí í kà á níwájú ọba.+
19 Gbàrà tí ọba gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ inú Òfin náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya.+
20 Ọba wá pa àṣẹ yìí fún Hilikáyà, Áhíkámù+ ọmọ Ṣáfánì, Ábídónì ọmọ Míkà, Ṣáfánì akọ̀wé àti Ásáyà ìránṣẹ́ ọba pé:
21 “Ẹ lọ bá èmi àti àwọn tó ṣẹ́ kù ní Ísírẹ́lì àti ní Júdà wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà nípa àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé tí a rí yìí; nítorí ìbínú Jèhófà tó máa tú jáde sórí wa pọ̀ gan-an torí àwọn baba ńlá wa kò pa ọ̀rọ̀ Jèhófà mọ́, wọn ò ṣe gbogbo ohun tó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé yìí.”+
22 Torí náà, Hilikáyà àti àwọn tí ọba rán, lọ sọ́dọ̀ wòlíì obìnrin+ tó ń jẹ́ Húlídà. Òun ni ìyàwó Ṣálúmù ọmọ Tíkífà ọmọ Háhásì, ẹni tó ń bójú tó ibi tí wọ́n ń kó aṣọ sí. Ó ń gbé ní Apá Kejì Jerúsálẹ́mù; wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀ níbẹ̀.+
23 Ó sọ fún wọn pé: “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Ẹ sọ fún ọkùnrin tó rán yín wá sọ́dọ̀ mi pé:
24 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Màá mú àjálù bá ibí yìí àti àwọn tó ń gbé ibẹ̀,+ ìyẹn gbogbo ègún tó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé+ tí wọ́n kà níwájú ọba Júdà.
25 Nítorí pé wọ́n ti fi mí sílẹ̀,+ wọ́n sì ń mú ẹbọ rú èéfín sí àwọn ọlọ́run míì láti fi gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ wọn mú mi bínú,+ ìbínú mi máa tú jáde bí iná sórí ibí yìí, kò sì ní ṣeé pa.’”+
26 Àmọ́, ní ti ọba Júdà tó rán yín pé kí ẹ lọ wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, ẹ sọ fún un pé, “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Ní ti àwọn ọ̀rọ̀ tí o gbọ́,+
27 nítorí pé ọlọ́kàn tútù ni ọ́,* tí o rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run bí o ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ tó sọ nípa ibí yìí àti àwọn tó ń gbé ibẹ̀, tí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú mi, tí o fa aṣọ rẹ ya, tí o sì sunkún níwájú mi, èmi náà ti gbọ́ ohun tí o sọ,+ ni Jèhófà wí.
28 Ìdí nìyẹn tí màá fi kó ọ jọ sọ́dọ̀ àwọn baba ńlá rẹ,* a ó tẹ́ ọ sínú sàréè rẹ ní àlàáfíà, ojú rẹ ò ní rí gbogbo àjálù tí màá mú bá ibí yìí àti àwọn tó ń gbé ibẹ̀.’”’”+
Lẹ́yìn náà, wọ́n mú èsì náà wá fún ọba.
29 Nígbà náà, ọba ránṣẹ́, ó sì pe gbogbo àwọn àgbààgbà Júdà àti Jerúsálẹ́mù jọ.+
30 Lẹ́yìn náà, ọba lọ sí ilé Jèhófà pẹ̀lú gbogbo èèyàn Júdà, àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù, àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, ìyẹn gbogbo àwọn èèyàn náà, ẹni kékeré àti ẹni ńlá. Ó ka gbogbo ọ̀rọ̀ inú ìwé májẹ̀mú tí wọ́n rí ní ilé Jèhófà sí wọn létí.+
31 Ọba dúró sí àyè rẹ̀, ó sì dá májẹ̀mú*+ níwájú Jèhófà pé gbogbo ọkàn àti gbogbo ara* ni òun á máa fi tẹ̀ lé Jèhófà,+ òun á sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ àti àwọn ìránnilétí rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlànà rẹ̀, láti máa ṣe ohun tí májẹ̀mú tí a kọ sínú ìwé yìí sọ.+
32 Yàtọ̀ síyẹn, ó mú kí gbogbo àwọn tó wà ní Jerúsálẹ́mù àti Bẹ́ńjámínì fara mọ́ ọn. Àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù sì ṣe ohun tí májẹ̀mú Ọlọ́run sọ, ìyẹn Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn.+
33 Lẹ́yìn ìyẹn, Jòsáyà mú gbogbo àwọn ohun ìríra* kúrò ní gbogbo ilẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ ó sì mú kí gbogbo àwọn tó wà ní Ísírẹ́lì máa sin Jèhófà Ọlọ́run wọn. Ní gbogbo ọjọ́ ayé* rẹ̀, wọn ò pa dà lẹ́yìn Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn.
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “àwọn ère dídà.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “àwọn ère dídà.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Ní Héb., “ilé.”
^ Tàbí “àwọn tó ń ru ẹrù.”
^ Ní Héb., “láti ọwọ́.”
^ Ní Héb., “ọkàn rẹ rọ̀.”
^ Àkànlò èdè yìí ni wọ́n fi ń sọ pé èèyàn kú.
^ Tàbí “tún májẹ̀mú dá.”
^ Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
^ Tàbí “àwọn òrìṣà.”
^ Ní Héb., “Ní gbogbo ọjọ́.”