Kíróníkà Kejì 3:1-17
3 Nígbà náà, Sólómọ́nì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ilé Jèhófà+ sí Jerúsálẹ́mù lórí Òkè Moráyà,+ níbi tí Jèhófà ti fara han Dáfídì bàbá rẹ̀,+ ibẹ̀ ni Dáfídì ṣètò sílẹ̀ ní ibi ìpakà Ọ́nánì+ ará Jébúsì.
2 Ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ilé náà ní ọjọ́ kejì, oṣù kejì, ní ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀.
3 Ìpìlẹ̀ ilé Ọlọ́run tòótọ́ tí Sólómọ́nì fi lélẹ̀ jẹ́ ọgọ́ta (60) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́,+ gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ti tẹ́lẹ̀.*
4 Ibi àbáwọlé* tó wà níwájú jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ó bá fífẹ̀ ilé náà mu,* gíga rẹ̀ sì jẹ́ ọgọ́fà (120); * ó wá fi ògidì wúrà bò ó nínú.+
5 Ó fi igi júnípà bo ilé ńlá náà, lẹ́yìn náà, ó fi wúrà tó dára bò ó,+ ó wá ya àwòrán igi ọ̀pẹ+ àti ẹ̀wọ̀n+ sára rẹ̀.
6 Yàtọ̀ síyẹn, ó fi òkúta iyebíye tó rẹwà+ bo ilé náà; wúrà+ tó lò sì jẹ́ wúrà láti Páfáímù.
7 Ó fi wúrà bo ilé náà àti àwọn igi ìrólé rẹ̀, ó tún fi bo àwọn ibi àbáwọlé rẹ̀,+ àwọn ògiri rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀kùn rẹ̀; ó sì fín àwọn kérúbù sára àwọn ògiri náà.+
8 Ó ṣe apá* Ibi Mímọ́ Jù Lọ,+ gígùn rẹ̀ bá fífẹ̀ ilé náà mu, ó jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́. Ó fi ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) tálẹ́ńtì* wúrà tó dára bò ó.+
9 Ìwọ̀n wúrà fún ìṣó jẹ́ àádọ́ta (50) ṣékélì;* ó sì fi wúrà bo àwọn yàrá orí òrùlé.
10 Lẹ́yìn náà, ó ṣe ère kérúbù méjì sínú apá* Ibi Mímọ́ Jù Lọ, ó sì fi wúrà bò wọ́n.+
11 Gígùn ìyẹ́ apá àwọn kérúbù+ náà lápapọ̀ jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́; ìyẹ́ apá kan kérúbù àkọ́kọ́ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì kan ògiri ilé náà, ìyẹ́ apá rẹ̀ kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì kan ìyẹ́ apá kérúbù kejì.
12 Ìyẹ́ apá kan kérúbù kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì kan ògiri kejì ilé náà, ìyẹ́ apá rẹ̀ kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì kan ọ̀kan lára ìyẹ́ apá kérúbù àkọ́kọ́.
13 Ìyẹ́ apá àwọn kérúbù yìí nà jáde ní ogún (20) ìgbọ̀nwọ́; wọ́n sì dúró lórí ẹsẹ̀ wọn, wọ́n kọjú sí inú.*
14 Bákan náà, ó fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú rírẹ̀dòdò àti aṣọ àtàtà ṣe aṣọ ìdábùú,+ ó sì ṣe iṣẹ́ ọnà kérúbù sí i lára.+
15 Lẹ́yìn náà, ó ṣe òpó méjì+ síwájú ilé náà, gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùndínlógójì (35), ọpọ́n tó wà lórí òpó kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún.+
16 Ó ṣe àwọn ẹ̀wọ̀n tó dà bí ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn, ó sì fi wọ́n sórí àwọn òpó náà, ó ṣe ọgọ́rùn-ún (100) pómégíránétì, ó sì fi wọ́n sára àwọn ẹ̀wọ̀n náà.
17 Ó ṣe àwọn òpó náà síwájú tẹ́ńpìlì, ọ̀kan sápá ọ̀tún,* èkejì sápá òsì;* ó pe èyí tó wà lápá ọ̀tún ní Jákínì* àti èyí tó wà lápá òsì ní Bóásì.*
Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
^ Ìgbọ̀nwọ́ tí wọ́n máa ń lò jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5), àmọ́ àwọn kan sọ pé “ìwọ̀n tí wọ́n ń lò tẹ́lẹ̀” tọ́ka sí ìgbọ̀nwọ́ gígùn tó jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 51.8 (ínǹṣì 20.4). Wo Àfikún B14.
^ Tàbí “Gọ̀bì.”
^ Tàbí “ó jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́ lára fífẹ̀ ilé náà.”
^ Ìwọ̀n yìí ò dáni lójú.
^ Ní Héb., “ilé.”
^ Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.
^ Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14
^ Ní Héb., “ilé.”
^ Ìyẹn, sápá Ibi Mímọ́.
^ Tàbí “gúúsù.”
^ Tàbí “àríwá.”
^ Ó túmọ̀ sí “Kí Ó [ìyẹn, Jèhófà] Fìdí Rẹ̀ Múlẹ̀ Gbọn-in.”
^ Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Nínú Okun.”